Baba Ijesha: Iyabo Ojo fèsì fún Bukky Black, Ó ní ọ̀rọ̀ rírùn ló sọ, ìtìjú ńlá ló jẹ́ fún ìran obìnrin àti ìyá

Iyabo Ojo/Bukky black

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofepris/buckkyblack28

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọrọ ti ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan gbajumọ oṣere tiata, Baba Ijẹsha yoo da silẹ lawujọ awọn oṣere Yoruba yoo fẹẹ domiru diẹ o.

Nibayii, iyabọ ojo ti fesi si eekan oṣere miran, Bukky Black to sọ pe ko si bi Baba Ijesha ṣe lee ṣe ohun ti wọn pe o ṣe naa nitori ninu ọrọ rẹ ẹṣin inu iwe ni Baba Ijẹsha ti ko lee ta.

Iyabọ Ojo ni iyalẹnu nla lo jẹ fun oun pe Bukky Black to jẹ agbablagba ninu owo ere tiata lee sọ ọrọ naa ati pe itiju nla lo jẹ fun iran obinrin atawọn iya lagbaye.

Iyabọ Ojo ninu fidio kan to fi sita lori ayelujara ṣalaye pe kii ṣe ohun to boju mu pe Bukky Black fẹ ki wọn boo mọle nitori pe o jẹ ọrẹ rẹ.

O ni bi Bukky Black ba n sọ pe oun ko ri Baba Ijẹsha pẹlu obinrin ri, a jẹ pe Bukky Black ko ranti pe Baba Ijesha ti ni iyawo ri to si tun ti bimọ ri.

"Akẹgbẹ wa kan ti ṣe aṣemaṣe o si yẹ ko foju wina ofin lori rẹ ki awọn to ku lee fi kọgbọn."

Skip Instagram post, 1
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 1

Bukky Black sọ òkò ọ̀rọ̀ si Iyabo Ojo lori ọ̀rọ̀ Baba Ijesha

Bukky Black ati Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, buckkyblack28/Instagram

Awuyewuye miran tun ti bẹ silẹ lori ẹsun asemase pẹlu ọmọ ọdun mẹrinla ti wsn fi kan Baba Ijesha, tii se agbajumọ oesere tiata.

Lọtẹ yii, obinrin mii to jẹ gbajugbaja osere tiata ti ọpọ eeyan mọ si Bukky Black ti wa dojukọ akẹẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata bakan naa, Iyabo Ojo, lori ipa to n ko lori ọrọ Baba Ijesha.

Bukky Black ninu fidio kan to se sita lajọ Ẹti lo ti n salaye pe oun mọ Baba Ijesha bii ẹni mọ owo nitori ẹyin ile oun lo n gbe ni Ikorodu nilu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Black, ẹni to ni ohun kii saba da si ohun to n sẹlẹ lawujọ ni ohun to sẹlẹ si Baba Ijesha ba oun lọkan jẹ, ti oun ko si le sun.

O ni gẹgẹ bi ohun ti mọ osere tiata naa, o jẹ ẹni ti kii yara mọ obinrin ti ko si kundun lati maa ko obinrin kiri.

Skip Instagram post, 2
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post, 2

"Baba Ijesha ko fi bẹẹ fẹran obinrin ti mo si maa n bi pe se o ni nnkan ọmọkunrin sa, o kan maa n se bii okobo ni.

N ko mọ Ijesha pẹlu ọrẹbinrin kankan, bii ẹni ti ko ni nnkan obinrin lo maa n se."

Bukky Black ni oun ti ohun ri ninu isẹlẹ naa ni pe ki eeyan ye ko isoro rẹ lọ si ọrọ ọrẹ amọ ka maa ke pe Ọlọrun , ẹni to n dahun adura.

Gẹgẹ bo se wi, isẹlẹ baba Ijesha naa dabi pe wọn n se sinima ni, wọn sẹẹti Baba Ijesha ni, bi ere itage lo si jọ loju oun.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

"Fidio ti Iyabo Ojo gbe sita, mo wo ni aimọye igba, to si dabi ẹni pe wsn n sere sinima ni. O dabi ẹni pe awọn ere ti Baba Ijesha ti se tẹlẹ ni wọn n sọrọ le lori.

Abi bawo ni isẹlẹ kan yoo se waye ni ọdun meje sẹyin, ti ẹ ko ri ẹni naa mu, tẹ wa pe sibi kan lati sẹẹti rẹ, ti yoo si ko sọwọ.

Amọ o se mi laanu bi ọpọ eeyan se maa n sọrọ lorisirisi lasiko ti nnkan wa waye lori ayelujara, onikaluku yoo si maa sọrọ saa.

"Bi nnkan ba sẹlẹ si ẹda, atunse lo yẹ ka maa wa, kii se ka maa baa jẹ. Iwọ to wa lori ilẹ alaaye, to ni laari, to n mi, to n se daada, to ni laari, to ro pe o ti debi to n lọ.

To wa ri ẹni ti isoro kan, to mura pe o maa ba tiẹ jẹ ni, Oluwa lo maa ba ti onitọun jẹ nitori ti ẹni to de la ri, a ko mọ ti ẹni to n bọ.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

Gbogbo ẹnikẹni to ba si ni oun yoo maa da isoro ẹlomiran, ẹnikẹni ta bi ninu obinrin, Ọlọrun maa ba ti onitsun jẹ ni."

Bukky Black wa kesi Iyabo Ojo pe ọga rẹ ni Baba Ijesha jẹ ninu ere tiata, ti awọn ara ita ba si n tako baba Ijesha, ko yẹ ko jẹ Iyabo Ojo ni yoo se bẹẹ.

"Iyabo Ojo, jẹ ki n sọ fun ẹ, ko yẹ ko post fidio yẹn, tabi ko ko awọn ọrẹ rẹ lọ sagọ ọlọpaa pe ti wsn ba fi Baba Ijesha silẹ, o maa pa sibi ni.

Ẹ lọ pa, kẹ wa maa gbe orilẹ alaaye, atunse lo yk kẹ maa wa, Ọlọrun ma fi isoro wa bu wa. Amọ to ba jẹ pe o ku ni ,ẹ maa ls sin, ẹ wa maa sunkun kiri.

Ẹ ma jẹ ka maa dakun isoro ara wa, atunse lo yẹ ka maa wa, ẹ ma jẹ ka maa da kun nitori ti kaluku si maa de baa.

Àkọlé fídíò, Olugbon of Igbon: ‘Rubber Stamp’ làwọn aṣòfin àpapọ̀, wọn kò ṣojú aráàlú

Iwa ti ikọọ́kan yin n hu labẹ ile ju bayii lọ, gbogbo wa ni ẹlẹsẹ, ẹni ti ilẹ ba mọ ba ni barawo."

Bakan naa ni Bukky Black n beere pe ki lo de ti wọn sẹẹti Baba Ijesha up lẹyin ọdun meje to ti se nnkan ti wọn lo se saaju.

O ni isoro ti wọn mọ pe Baba Ijesha ni ni wọn sisẹ le lori.