Baba Ijesha Rape case: Iyabo Ojo ní ìdúnú òun ni kí ọmọdé náà rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo, Baba Ijesha
Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba tun ti ri ẹni kunra ninu ijagbara rẹ fun idajọ lori ẹsun ti wọn fi kan ọkan lara awọn oṣere akẹgbẹ rẹ, Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha.
Iyabo Ojo n sọ ọrọ yii nigba to n fesi si fidio ti awọn eeyan to n da si ọrọ ẹsun ti wọn fi kan Baba ijesha lọ wu jade ti wọn si ni o ti gbe ọrọ naa ti ko kan an sori ju.
Fidio naa to ti pẹ ni Iyabo Ojo ṣalaye pe Baba Ijesha rọjo epe le akẹgbẹ rẹ, Iyabo Ojo lori ninu eyi to tun ti n fi ẹsun kan pe ogun owo lo ṣe.
- Àlàyée Fídíò bí Baba Ijesha ṣe ṣe aṣamaṣe pẹ̀lú ọmọ Princess rèé
- A kò bá ti lé Baba Ijesha àmọ́ kìí ṣe ọmọ ẹgbẹ TAMPAN, a kò sì fọwọ́ sí ìwà tó hù - Mr Latin
- Ìjọ Islam fìwé pe Wòlíì Genesis bíi àlejò pàtàkì sí òru Lailatul Quadir, ariwo sọ
- Ọlọ́run Ọba ti pa ẹ̀gàn mi rẹ́, a bímọ l'Amẹrika - Lizzy Anjorin
"Inu mi dun pe mi o tilẹ ri fidio naa lasiko to gbe e jade, tori ninu ki n kan gboju, o da lorii bi mo ba ṣe ri i si, tabi ki n fesi tori o le ba ibi ti ko daa lara mi".
O ni amọ adẹrinpoṣonu ni Baba Ijesha tori naa, o lee sọrọ si ẹnikẹni bo ṣe wu u. Iyabo ni o tilẹ dara pe oun ko ri i depo fesi eyi to lee mu awọn tun ri sọ.
Iyabo Ojo ni tori awọn to n ro kiri pe kilode ti oun ṣe gbe ọrọ ọlọrọ sori gan loun ṣe tun ṣe fidio jade. O ni ko sewu tori gbogbo eniyan lo lẹtọ ati sọrọ.
"Amọ fun ẹyin tẹẹ lọ n wu oriṣiriṣi fidio sita lati gbiyanju ibanujẹ si mi, mo fẹ sọ fun un yin pe ẹ n fi akoko yin ṣofo ni".
Iyabo Ojo ni ọtọ ni ọrọ to wa nilẹ bayii awọn ko si ni gba ọjẹgẹ.
"Idunu kan ṣoṣo ti mo fẹ gba lara nkan taa n ṣe yii ni pe ki ọmọde yẹn gba ẹtọ rẹ, ki idajọ bori, ko si gba idalaraya."
O ni "ẹ ba wu gbogbo ohun to ṣee wu jade, ko mi mi rara". Torinaa, Iyabo Ojo ni kii ṣe pe oun fi ọrọ Baba Ijesha fa oju awọn eeyan mọra toripe nkan aburu ni.
Iyabo Ojo ni toripe ijọba ti n ṣe ohun to yẹ ki wọ́n ẹ jẹjẹ ni ara oun ṣe balẹ.















