Rape: Akínkanjú obìnrin tó ń ṣe àyà gbàngbà kojú àwọn tó ń fipá báni lòpọ̀ nílùú rẹ̀
Arabinrin Fanny fi itan aye rẹ hande nipa bi wan ṣe fipa ba oun funra rẹ lopọ ti wọn tun fiya jẹ ẹ.
O ni inira gidi ni ilu ara rẹ to bẹẹ́ to fi yi orukọ ara rẹ ati awọn ọmọkunrin rẹ meji pada ti wọn si pada pa wọn.
Ohun to sun un de idi ipinu lati maa daabo bo ati lati maa ja fun ẹtọ awọn obinrin mii ti wọn ba fẹ tabi ti wọn fipa ba lopọ.
Iṣẹ to yan lati maa ṣe yii ko rọrun rara paapaa fun obinrin, o lewu gidi.
Ni orilẹede Colombia, ko si irọrun kankan fun awọn adari. Lọdun 2020 nikan o to adari to le ni igba ti wọn ṣekupa.
Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe n gbiyanju lati daabo bo ilu lọwọ ogun amọ awọn janduku ko jẹ.
Fanny Escobar gbe igbesẹ akin, o dariji awọn to sọ aye rẹ di radarada o si fi ara rẹ jin fun riran awọn obinrin ilu rẹ lọwọ.

