Baba Ijesha: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fi ẹ̀sùn mẹ́rin kan Ijesha, ẹ̀wọ̀n gbére wà nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, babaijesha

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe oun ti gbọ nipa ẹsun ifipa ba ọmọde lopọ ti wọn fi kan gbajumọ oṣere kan, Baba Ijesha, ati pe oun ti ṣetan lati ṣe ẹjọ rẹ.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri si ẹsun ifibanilopọ fi lede, eyii to tẹ BBC Yoruba lọwọ, ni wọn ti kede bẹẹ.

Ikede naa ni "A fẹ fi akoko yii sọ fun gbogbo araalu pe, ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n ri si ẹsun ifibanilopọ ati iwa ipa ninu ile, ti bẹrẹ iṣẹ lori ẹsun ti wọn fi kan Baba Ijesa, a si ti n ba awọn to fẹsun kan an sọrọ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"A fẹ ki ẹyin eeyan ilu mọ pe wọn ti fi ẹda iwe ẹsun rẹ ṣọwọ si ẹka to n ṣe ẹjọ awọn araalu, DPP, fun imọran to tọ labẹ ofin."

Lẹyin naa ni wọn ṣalaye awọn ẹsun naa lẹsẹṣẹ ati ijiya to wa fun awọn ẹsun ọhun labẹ ofin ijọba ipinlẹ Eko.

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, princesscomedian

Ẹṣun ti wọn fi kan Baba Ijesha ati ijiya fun ọkọọkan:

  • Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan baba Ijesha ni fifi ipa ni ibalopọ si ọmọde, eyi to lodi si ofin to rọ mọ iwa ọdaran nipinlẹ Eko ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015, ti ijiya rẹ si jẹ ẹwọn gbere
  • Ẹsun keji ni igbiyanju lati fi ipa ni ibalopọ, ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹrinla gbako
  • Wọn tun fi ẹsun ifipabanilopọ kan Baba Ijesha eyi ti ijiya rẹ jẹ ẹwọn ọdun mẹta pere
  • Ẹsun kẹrin ni biba ọmọde wu iwa to jọ mọ ibalopọ, eyii ti ko tọ, ẹwọn ọdun meje ni ijiya rẹ labẹ ofin ipinlẹ Eko.

Ileeṣẹ naa ni awọn ni igbagbọ to dantọ ninu ẹka eto idajọ ipinlẹ Eko lati ri daju pe gbogbo awọn ti ọrọ naa kan yoo ri idajọ ododo gba.

Àkọlé fídíò, Ikorodu cult crisis:A máa gbé Orò síta lọ́jọ́kọ́jọ́ tí ìjà ẹgbẹ́ òkùnkùn bá tún ṣẹlẹ̀- Àwọ

Lẹyin naa ni wọn sọ pe, ijọba ipinlẹ Eko ko faye gba gbogbo iwa to jọ ifipabanilopọ ati iwa ipa si obinrin tabi ọkunrin ni ipinlẹ naa.

Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko sọ fun BBC ninu atẹjade kan pe, afurasi naa ti wa ni ahamọ.

Igbesẹ naa waye lẹyin ti Damilola Adesanya, ti ọpọ mọ si Princess Comedian fi ẹjọ rẹ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Sabo nilu Eko

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ati awọn akẹgbẹ rẹ nidi iṣẹ tiata ni wọn ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iṣẹlẹ naa.

Amin iyasọtọ kan

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha

Saidi Balogun ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, saidibalogun/Babaijesha Instagram

Ọrọ awuyewuye to n lọ lọwọ lori ẹsun biba ọmọde lopọ ti wọn fi kan gbajumọ osere, Baba Ijesha, tun ti sun kan gbajugbaja osere miran, Saidi Balogun.

Idi ni pe ọpọ awọn eeyan to n tako gbigba beeli Baba Ijesha ni ahamọ ọlọpa, lo ti n pariwo awọn osere tiata lọkunrin kan pe awọn lo wa nidi igbesẹ lati tu Baba Ijesha silẹ.

Lara awọn ọkunrin ti wọn n lọ ọrọ naa mọ lọrun ni Yomi Fabiyi ati Saidi Balogun pẹlu awọn osere tiata lọkunrin miran ti ko tii sọrọ lori awuyewuye naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ nigba to n takun ero awọn eeyan to ni oun n se atilẹyin fun Baba Ijesha, Saidi Balogun ni oun ko fara mọ iwa ifipabanilopọ rara ati rara.

Saidi, ẹni to se fidio kan soju opo Instagram rẹ lori ọrọ naa ni, oun korira asa ifipabanilopọ fun obinrin agbalagba, ka to wa sọ hihu iwa yii si ọmọde ti ko mọ ọtun yatọ si osi.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

"Mo korira iwa nina ọwọ ere oke si ọmọge, n ko si se ri. N ko de agọ ọlọpaa Panti ri laye mi, bẹẹ ni n ko tii ba Baba Ijesha sọrọ rara lati igba to ti wa ni ahamọ.

Ki wa lo de ti maa fi sọ fawọn ọlọpaa pe ki wọn fi silẹ, ki lo de ti maa fi se bẹẹ. Ẹ jọọ, se ẹ mọọmọ n ditẹ lati ba orukọ mi jẹ, kẹ fi le mu mi walẹ ni abi bawo?"

Saidi Balogun fikun pe oun ko se atilẹyin rara fun iru iwa bẹẹ, amọ oun dakẹ lai sọrọ nipa isẹlẹ naa nitori pe oun fẹ ki ofun sisẹ rẹ ni lai si idiwọ.

Àkọlé fídíò, Helen Paul sọ idi tó fi gba orúkọ ní kékere

"Se emi nikan ni osere tiata ti ko tii sọrọ lori isẹlẹ yii ni? Ninu ẹgbẹ bii ọgbọn, eeyan kan abi meji pere lo tii sọrọ, ki wa lo de tẹ se n pariwo mi."

Bakan naa ni Saidi ni oun fi gbogbo ara se atilẹyin fun ohun tawọn obinrin n se lori ọrọ yii, oun ki wọn, oun si yin wọn pẹlu.

Amọ o ni ohun n bẹ wọn ni pe ki wọn mase mu orukọ oun bọnu lori ọrọ naa, ki wọn dakun, fi ohun silẹ.

Amin iyasọtọ kan

Ẹ̀yin tẹ tako béèlì Baba Ijesha, ẹ̀ ń palá sẹ́nu ni - Yomi Fabiyi

Aworan Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Instagram/realyomifabiyi

Gbajumọ osere tiata Yoruba, Yọmi Fabiyi ti fesi lori bi awọn eeyan kan se n naka aleebu si pe o n satilẹyin fun Baba Ijesha.

Baba Ijesha ni osere tiata Yoruba ti wọn fi ẹsun kan pe o nawọ ere oge si ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla, tii se ọmọ adẹrinposonu kan, Princess.

Oniruuru ọrọ si ni Yomi Fabiyi ti kọ soju opo Instagram rẹ lati igba ti isẹlẹ naa ti waye, eyi to fi n sekilọ pe ki araye mase tii da baba Ijesha lẹbi, titi ti ileẹjọ yoo fi gbe idajọ kalẹ lori ọrọ naa.

Ọrọ Fabiyi yii lo bọ sapo ibinu awọn ọmọ Naijiria, to fi mọ awọn akẹẹgbẹ rẹ bii Iyabo Ojo ati Mercy Aigbe, ti eruku si n yọ lori ayelujara nipa iha ti Yomi Fabiyi kọ si ọrọ Baba Ijesha naa.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ yii, Fabiyi sọ pe gba-gba-gba loun duro lẹyin Baba Ijẹsha to wa lahamọ ọlọpaa bayii .

Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, realyomifabiyi/Instagram

O ni afurasi naa lẹtọ si igbẹjọ ati idajọ ododo labẹ ẹtọ ọmọniyan, ko si yẹ kawọn eeyan tii maa se idajọ rẹ, titi ti ileẹjọ yoo fi kede idajọ rẹ.

Yọmi Fabiyi salaye pe, oun ko figbakan ti iwa ibajẹ, irufẹ eyi ti wọn n fẹsun rẹ kan Baba Ijesha, lẹyin.

Baba Ijesha kii se ọdaran ayafi tile ẹjọ ba sọ bẹẹ

O ni ṣugbọn ohun ti oun n ja fun ni pe ki awọn eeyan to n ṣe idajọ rẹ lori ayelujara o ranti pe labẹ ẹtọ omoniyan lagbaye, afurasi ko tii di ọdaran ayafi igba ti adajọ ba sọ pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Nipa bẹẹ, o ni gbogbo awọn ti n pariwo lori ayejara pe kawọn ọlọpaa mase gba beeli Baba Ijesha kan n pala lẹnu lasan ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Labẹ ofin Baba Ijesha lẹtọ si beeli, bi wọn ba si fun un, ofin lo fun, kii ṣe oun Yọmi Fabiyi.

Ara oun to n fa awujọ sẹyin ni aibọwọ fun ẹtọ ọmọniyan ati pe, idajọ ori ayelujara ti ọpọ awọn to n da si iṣẹlẹ naa n ṣe, ko le ran orilẹede yii lọwọ."

Lori itahunsiraẹni to n waye laarin rẹ ati Iyabọ Ojo lori ikanni ayelujara, Yomi Fabiyi ni oun mọ gbajumo osere naa si eeyan daadaa.

Amọ o ni sibẹ, igbagbọ oun ṣi ni pe agbẹjọ ẹnikan da, agba oṣika ni, oun ko si ni yẹsẹ kuro lori ero oun naa.

Àkọlé fídíò, hhhhhh

Obinrin kan jade lati fi ẹsun ifipanilopọ kan Yomi Fabiyi

Ni kutu hai oorọ Ọjọbọ ni iroyin miran tun jade sori ayelujara nibi ti obinrin kan ti n fi sun kan Yomi Fabiyi pe oun naa fẹ fipa ba oun lopọ nigba kan ri.

Gẹgẹ bi obinrin naa to kede ọrọ yii soju opo Instagram rẹ, actoryohan ti wi, iru ẹyẹ ni ẹyẹ n wọ tọ lẹyin, ni ọrọ Yomi Fabiyi ati Baba Ijesha, ta si ni eesi yoo gbe, bi ko se elegbo.

Obinrin naa, ẹni to koro oju si iha ti Fabiyi kọ si ero Iyabo Ojo, lo tẹsiwaju lati maa salaye ohun to sẹlẹ si lọdun 2016, to si ni diẹ lo ku ki Fabiyi fipa ba oun lopọ.

"Mo fẹ se ere itage, mo si kan si Yomi Fabiyi nipa rẹ, o ni ki n san ẹgbẹrun lọna marundinlogoji naira lati fi gba fọọmu bii ọmọ ẹgbẹ tiata rẹ.

Mo san ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ninu rẹ, to si ni ki n wa pade oun nibi ti wọn ti n se ere. Igba ti mo de ibẹ, lo tun ni ọọfisi ni fọọmu naa wa, to si ni ki n kalọ si ọọfisi oun.

Amọ ile rẹ ni adugbo Ogolonto nilu Ikorodu lo gbe mi lọ, o fun mi ni fọọmu lati kọ nnkan nipa mi sibẹ. Ibi ti mo ti n se bẹẹ lọwọ, lo ti jade ni ihooho wa ba mi, to si n na nnkan ọkunrin rẹ si mi."

Obinrin naa ni oun sa kuro ninu ile naa, ti oun si ni oun ko le sun ti nitori ere, o wa ni ko fi owo oun ransẹ si oun.

Nigba to n sọ ero rẹ lori iroyin naa, Fabiyi ni irọ to jinna sootọ ni ẹsun obinrin naa, ti ọrọ naa ba si da loju, ko lọ fi ẹjọ oun sun ọlọpaa.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹbọ ọkùnrin àti obìnrin tí kò ní ìbálòpọ̀ rí ni wọ́n rú dènà ogun Fulani

Ma ran obinrin to fi ẹsun ifipabanilopọ kan mi ni ẹwọn lai gbẹbẹ

Bakan naa lo tun woye pe awọn obinrin kan kundun ki wọn maa pa irọ mọ ọkunrin, oun si le duro osu kan lai ri obinrin, bi obinrin ko ba si gba fun oun, kii se dandan.

"Ẹ ba sa oogun si mi, titi ti opin aye yoo fi de, n ko le fi ipa ba obinrin lopọ laelae, ti ọrọ naa ba si da obinrin naa loju, ko gba agọ ọlọpaa lọ.

Maa eran obinrin naa ni ẹwọn, ti n ko si ni gbọ ẹbẹ lasiko naa, nitori irọ nla lo pa mọ mi."