Gbenga Adeboye: Òní ló pé ọdún 19 tó kú, kí lẹ rántí nípa rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, City People
Òní ọjọ́ Ẹtì ló pé ọdún méjìdínlógún tí gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́ nnì, tó tún jẹ́ adẹ́ẹ̀rínpòṣónú, Gbenga Adébóyè, t'áwọn olólùfẹ́ rẹ̀ tún mọ̀ sí Funwọ́ntán, jáde láyé.
Ọ̀gbẹ́ni Adeboye, tó jẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, adẹ́ẹ̀rínpòṣúnú, àti akọrin ṣaaju ikú rẹ̀, jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ká lẹ́ka àwọ̀n amúlùdún, tọ́pọ̀lọpọ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ sí fi ṣe àwòkọ́ṣe.
Elijah Oluwagbemiga Abefe Adeboye ni orukọ abisọ rẹ, amọ Alhaji, Pastor, Olúwo, Jengbetiele, Itu baba ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ míràn tó pani lẹ́rìn lo n jẹ lẹnu isẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wòlíì Olubọla ni wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó jí ọkọ̀ ọmọ ijọ̀ lọ ní Abeokuta
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn tẹ ara wọ́n pa, ariwo ẹkún sọ
- Afurasí Oníṣòwò ǹkan ìjà olóró méje kó sí pańpẹ́ Ọlọ́pàá ní Jos àti Taraba
- Saidi Balogun figbe ta pé wọn ń ba òun lórúkọ jẹ́ lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha
- Mo bẹ̀rẹ̀ sí ń wọ ìjáàbù nítorí àwọn okùnrin máa ń wo bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí mi tí mo bá ń wàásù - Sister Kate
- A kọ̀ láti yí ọkàn wà padà lórí ìpinnu Yorùbá Nation- Ilana Omo Oodua
Kò sí àníàní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò lé gbàgbé ádẹ́rìnposónu sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà nítori àwọn iṣẹ́ to ti gbése kí ó to gbà fún ikú lọgbọ̀n ọjọ oṣù kẹrin, ọdún 2003.
Láti túbọ̀ ṣe ìràntí Gbẹnga Adeboye, A ṣe àkójọ àwọn nǹkan mánigbàgbé mẹ́wàá tó ti ṣe nile aye.
Àwọn nǹkan málègbàgbé nípa Gbenga Adeboye.
Gbenga Adeboye lo sọ awada di itẹwọgba kaakiri:
Gbenga Adeboye ti gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Funwọntan, ni ó wà lára àwọn ẹni àkọ́kọ́ tó sọ àwàda kẹrikẹri dí iẹwọgba gbogbo ènìyàn, kí àwọn ènìyàn mii tó lájú síbẹ̀.
Títí di àsìkò yìí, kò tíì ṣí ẹni tí o le ti ẹsẹ̀ bọ bata Gbenga Adeboye láti àsìkò yii titi di igba tó lọ sinmi láyà Oluwa.
Lẹ́yin àìsàn tó niṣe pẹ̀lú kídìrín ní Gbega Adeboye gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra.

Oríṣun àwòrán, Achieve
Gbenga Adeboye lo ni orukọ inagijẹ to tii pọju lẹnu isẹ:
Nígbà tí a bí Gbenga Adeboye, Elijah Oluwagbemiga Adeboye ni wọn sọ ọ́, sùgbọ́n nígbà tí yóò fi kú, o níra láti le sọ iye orúkọ tó n jẹ́ lẹnu isẹ.
Ìdí ni pé nínú orín àti àwàdà tí o má n ṣe, ló ti jẹ́ oníruurú orúkọ bii Funwontan, Alhaji Pastor Oluwo, Jengbetiele, Itu baba Ita, Alaye mi Gbengulo àti àwọn orúkọ mííràn.
- Yekeen Ajileye, ọ̀gá mi nínú iṣẹ́ tíátà ṣẹ̀ mí, ó ṣẹ ẹlẹ́dàá mi - Abija
- A kọ̀ láti yí ọkàn wà padà lórí ìpinnu Yorùbá Nation- Ilana Omo Oodua
- Ẹẹmejì ni mo ti wú òkú fún ètùtù ọlà tí kò jẹ́, kí ọwọ́ tó tẹ̀ mí
- Mi o rí òṣèrékùnrin tí kìí yan àlè lẹ́yìn ìyàwó wọn- Iyabo Ojo
- Òní ni ọjọ́ mẹ́jọ ìpapòdà Oba Lamidi Adeyemi ni ìlú Oyo
- Bíbéli mi ló sọ pé kí n fẹ́ ìyàwó omidan mẹ́rin, kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀- Pásítọ̀
- A ti yọwọ́ olùdíje méji kúrò láwo lẹ̀yìn àyẹ̀wò, wọn kò lè díje lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ PDP- David Mark
Gbenga Adeboye ni ẹbun pupọ ti ko se ka:
Gbenga Adeboye jẹ ọkan ninu àwọn to ni ẹbun púpọ, ti o sì ni ìmọ̀ tó pọ̀ nínú iṣẹ̀ tọ yàn láàyò.
Kò sí ìgbà tó bá ń ṣe ohunkóhun ki àwọn ènìyàn má rín ẹ̀rin àrìn tàkìtì, sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ni, oludari ayẹyẹ lóde àríyá ni pẹlu, bakan naa lo tu maa n kọrin.
Oloju aanu ati Onididun ọlọrẹ ni Gbenga Adeboye:
Nígbà ayé rẹ̀ àti lásìkò tó kú tan, gbogbo ènìyàn ló n jẹ̀rí si pé Gbenga Adeboye jẹ́ onínu dídùn ọlọ́rẹ ati ẹni ti kò máyé le rara.
Ọ̀kàn nínú ọ̀mọ̀ Funwọntan lo fi idi ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fún BBC lásíkò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
"O yá bábá mi kí a mú gàrí ju kí ará ìta má ri ounjẹ jẹ lọ."
Amunimọna ni Gbenga Adeboye, paapaa awọn to sẹsẹ n didelẹ:
Ọ̀pọ̀ ló má a n pè Gbenga Adeboye ni olùtọ́nisọ́nà fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dìde ni Alayé mi Gbengulo, bi ọ̀pọ̀ ṣe má a n pè é.
Ìròyìn fi ye ni pé, Gbenga Adeboye lo jẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ gbájúgbàjà òṣèré Fathia Balogun bii isana ẹlẹẹta nítorí pé ó ṣe àfihàn rẹ̀ nínú ijó orin rẹ̀ kan.
Àwọn ènìyàn bí Baba Gboin, Ereke ni Sọobu àti àwọn mííràn ló ti ara Adeboye dide pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Elijah Adeboye
Ọjọru jẹ ọjọ ọ̀wọ̀ fun Gbenga Adeboye, kii fi sere rara:
Gbenga Adeboye jẹ́ ẹni ti kìí fi Ọjọ́rú ṣere nígbà ayé rẹ̀, abúrò rẹ̀ kan lo fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ nínú àwo orin kan tó gbé jáde.
Ninu awo orin naa lo ti sọ ìtàn ayé Gbenga Adeboye kí ó tó di ìlúmọ̀ọ̀ká lásìkò náà, Ọmọ Majẹmu lo pe àkọle orin náà.
Ọjọ́rú jẹ́ ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ fún Gbenga Adeboye, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ, ọgbọ̀n ọjọ́, oṣù kẹsan ọdun 1959 ni wọ́n bíi
Ọjọ́rú ló bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé, Ọjọ́rú bákan náà ló rin ìrìnàjò àkọ́kọ́ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Amẹrika, Ọjọ́rú náà lo ṣe ètò Radio rẹ̀ àkọ́kọ́.
Ọjọ́rú, ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù kẹrin ọdún 2003 lo kú, wọ́n sì sí ni Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹrinlà, oṣù karun ọdún 2003.
Gbenga Adeboye ri ọrun, ko to ku:
Wọ́n máá n ri Gbenga Adeboye gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti rí ọ̀run, kí ó tó kú.
idi ni pe o ti kọkọ ku nile iwosan, ti okiki si ti gba aye kan, ko to tun wa ji pada, ko si pẹ lẹyin igba naa, to tun jade laye pada.
Asiko perete to lo laye lẹyin iku rẹ akọkọ naa si lo gbe awo orin kan sita, ninu eyi to ti sọ bi ọrun se ri ati iriri ranpẹ to ni lajule ọrun nigba iku rẹ akọkọ.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ nínú àwo orin naa, o ni òun kú, òun si rí Ọlọ́rún, sùgbọ́n ó dá òun pada láti lọ pari iṣẹ́ tó ran òun láti gbé ilé ayé ṣe ni.
Bákan náà lo ni Ọlọrun sọ fún oun pé, tí òun bá kú, wọ́n gbọdọ sin òun pẹ̀lú Bíbelì àti ìwé orin.
Àwo orin rẹ̀ yìí si lo dá onirúrú awuyewuye sílẹ̀ láwujọ lásìkò náà.























