PDP Screening 2022: Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò olùdíje mẹ́tàdínlógún tó fẹ́ díje dùpo aáré lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ PDP

Logo PDP

Oríṣun àwòrán, @PDP

Egbé òṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti bẹrẹ eto ayewo awọn Oludije sipo aarẹ.

Nibi ayẹwo yii ni wọn yoo ti fun awọn to kunju osuwọn ni maaki o pegede lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party (PDP).

Lẹyin ti ayẹwo yii bẹrẹ ni igbimọ tẹẹkoto ẹlẹni mẹsan an naa kede pe awọn ti yọwọ oludije meji kuro lawo oludije.

Bawo ni ọrọ ṣe jẹ?

Oloye David Mark to jẹ olori igbimọ tẹẹkoto naa lo sọ eyi di mimọ fun awọn akọroyin.

Sugbon David Mark kọ lati darukọ awọn mejeeji ti wọn ti yọ orukọ wọn kuro lara oludije naa.

Àkọlé fídíò, Oyo PDP Crisis: Olopoeyan ní Makinde yá PDP láti dìbò ni, àwọn kò ní gbà kó ba ẹgbẹ jẹ

Kini o ti kọkọ ṣẹlẹ?

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò olùdíje mẹ́tàdínlógún tó fẹ́ díje dùpo aáré lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ PDP

Egbẹ́ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti bẹrẹ ayẹwo gbogbo awọn to fẹ jade dije dupo labẹ asia ẹgbẹ naa.

awon Oludije

Oríṣun àwòrán, others

Oni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2022 yii ni eto naa bẹrẹ fun awọn to fẹ dije dupo aarẹ.

Alaga igbimọ tẹẹkoto naa ni aarẹ awọn Asofin agba nigba kan ri, Oloye David Mark.

Igbimọ tẹẹkoto yii jẹ ti ẹlẹnu mẹsan an.

Awọn wo ni wọn maa ṣe ayẹwo fun?

Awọn ti igbimọ naa fẹ ṣe ayẹwo fun ni: Igbakeji Aarẹ Atiku Abubakar, Aare ile igbimo asofin tele Bukala Saraki, Peter Obi ati Aminu Tambuwal.

Àkọlé fídíò, PDP Crisis: Mo fẹ kí èmi àti Auxillary kojú ara wa lọ́dọ̀ ọlọ́pàá ní Abuja lórí ìkọlù náà

Awọn mii ni akowe ijoba apapo tẹlẹ Pius Anyim; gomina Bauchi Bala Mohammed; Gomina Rivers Nyesom Wike, ati ti Akwa Ibom Udom Emmanuel.

Àkọlé fídíò, PDP Convention: Àrà ọ̀tọ̀ ní ìdìbò 'convention' tọ̀tẹ̀ yí, òru mọ́jú la ti yanjú

Awon mii tun ni Mazi Sam Ohuabunwa; ati Mohammed Hayatu-Deen; pelu onisegun oyinbo lati ile America Nwachukwu Anakwenze, ati Alase ileese Ovation Dele Momodu.

Awọn to ku ni gomina ekiti tẹlẹ. Ayo Fayosi; Cosmos Ndukwe, Charles Ugwu, Chikwendu Kalu ati Tariele Oliver.

Àkọlé fídíò, Kola Ologbodiyan: Jẹgudu jẹra ni ijọba APC