Prince Charles and Camilla royal visit: BBC gbàlejò orí adé ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ka bí wọn ṣé kàn sáárá sí àwọn akọroyin

Alejo ile Oba si BBC

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ọmọ Ọba Charles kàn sí BBC lórí àjọdun àádọ̀rún ọdún ileèsẹ náà,ka ohun tí Oriade so

Arẹmọ ọmọ ọbabinrin ilẹ Gẹẹsi ti gbosuba kare fawọn akọroyin to n sisẹ takuntakun pe ki araalu maa gbọ iroyin ti ko lẹja bakan ninu lati awọn ibi ti ikọlu ti n waye.

Alejo ile Oba si BBC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oriade yi fi ọrọ yi lede lasiko to n kan si BBC World Service ni iranti ayẹyẹ aadọrun ọdun ileesẹ ọhun.

Arẹmọ Charles ati iyawo rẹ Duchess ti Cornwall Camilla sabẹwo si olu ileesẹ naa ni London lọjọbọ tii se ọjọ Kejidinlọgbọn osu Kẹrin 2022.

Alejo ile Oba si BBC

Oríṣun àwòrán, Jeff Overs/BBC

Lasiko abẹwo yi, wọn ba awọn akọroyin to n sisẹ takuntakun lati mu iroyin wa lati agbegbe ti ikọlu ti n waye bi Afghanistan Ukraine ati Russia sọrọ.

Bẹẹ, wọn fi to wọn leti bawọn ikọ akọroyin se n se isẹ wọn jakejado agbaye toun ti ipenija ti wọn koju.

Àkọlé fídíò, BBC ṣe'filọlẹ Yoruba, Igbo ati Pidgin

Bakan naa tọkọtaya oriade yi kan sara si awọn osisẹ BBC lori isẹ wọn paapa nipa gbigbe iroyin jade lori ogun Ukraine ati Afghanistan lasiko abẹwo taa n wi yi.

Alejo ile Oba si BBC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọba Charles sọ fun akọroyi wa Lyse Doucet ati Clive Myrie pe "akikanju ni wọn n se tori ko rọrun lati se isẹ ti wọn n se''.

Àkọlé fídíò, Nkan ti awọn eeyan nsọ lori BBC Yoruba

Bi awọn osisẹ ti se rọyika rẹ, o tun sọ pe:

"Mo mọ riri wahala tawọn to n gbe iroyin jade lasiko yi n se ati iru ayika ti wọn ti n sisẹ bayi ti nkan ko rọgbọ''.

Àkọlé fídíò, Ìpàdé ìtagbangba BBC Yorùbá ti ìpínlẹ̀ Ọyọ

''Ni paapa iru nkan ti wọn se ki araalu ba fi le gbọ iroyin ododo ti ko segbe lẹyin ẹnikankan ni paapa lawọn ibi ti ogun ti n waye''

''Nitori naa mo gbosuba fun yin lori isẹ ti ẹ n se ati awọn akẹgbẹ yin to wa loju ina to fi mọ awọn to sa kuro lati awọn ilẹ ,eyi to n waye leralera lasiko taa wa yi lawọn ibi wahala-Mo dupẹ fun gbogbo igbiyanju yin''.

Àkọlé fídíò, Ìpínlẹ̀ Oyo gbàlejò ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Ileesẹ BBC ti n ri iyipada to lamilaaka lẹnu ọdun meloo kan sẹyin lati ọdun 1940:

Ni bayi, BBC ti n gbe iro iroyin jade lede orisi to fi mọ Pidgin,Korean ti wọn si tun si ọfisi tuntun ni Cairo to fi de Seoul Belgrade ati Bangkok.

Àkọlé fídíò, Iko BBC Yoruba tuntun

Ileesẹ iroyin to tobi julọ ti BBC da silẹ nilẹ miran yatọ si ti ilẹ Gẹẹsi ni eleyi to wa ni Delhi ati Nairobi.

Ileesẹ iroyin BBC World Service a maa gbe iroyin jade lede Gẹẹsi ati ede mọkanlelogoji lori redio,ẹrọ amounmaworan,lori ayelujara ti o kere tan eeyan miliọnu 364 kaakiri agbaye a si maa wo wọn.

Liliane Landor, ọga agba BBC News International to tun jẹ oludari BBC World Service sọ pe:

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ìdùnnú lórí ayẹyẹ ọdún kan iléeṣẹ́ náà

"Ohun ayọ ni fun wa pe a gba alejo awọn oriade wa lati fi se iranti ayẹyẹ aadọrin ọdun wa ti wọn si tun lanfaani lati pade awọn ikọ wa kaakiri ẹka ede.''

''Bi wọn se n fi ọkan ba isẹ wa bọ eyi tawọn eeyan wa n gbe jade fawọn ololufẹ wa nile loko ati lẹyin odi ni Afghanistan, Ukraine ati ibomiran n jẹri si isẹ ribiribi taa n se''

Àkọlé fídíò, BBC gbalejo ọmọ Ibadan