BBC: Iroyin yoruba yoo bẹrẹ ni pẹrẹwu

Oríṣun àwòrán, Channels TV
Ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ ti ijọba ilẹ Gẹẹsi (BBC) ti ṣetan lati ṣe ifilọlẹ awọn ẹka iṣẹ iroyin meji tuntun lorilẹede Naijiria lọjọ aje.
BBC Yoruba ati BBC Igbo yoo bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu lẹyin ifilọlẹ wọn ni ọsẹ to n bọ nipinlẹ Eko.
Oludari ati aṣaaju awọn ẹka iroyin mejeeji yi ni ileeṣe BBC, Peter Okwoche sọ eyi di mimọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ile iṣẹ amohunmaworan Channels ni ọjọ abamẹta pe awọn ẹka iṣẹ iroyin yii yoo pese iroyin ni ede abinibi Yoruba ati Igbo fun awọn ọmọ orilẹede yii.
Nisisiyi, BBC n ṣiṣẹ ni ede Gẹẹsi, Hausa ati pidgin ni orilẹede Naijiria.

Irisi BBC Yoruba ni ṣoki

- Iroyin ni ede Yoruba, fun awọn ọmọ kaarọ o jiire
- BBC Yoruba yoo maa jade lori ikanni agbaye bbc.com/yoruba
- Ẹka akanṣe iroyin ni ede Yoruba yoo wa ni ori opo ayelujara Facebook ati instagram pẹlu idanimọ @bbcnewsyoruba
- Eto iṣẹ yi yoo maa jade lati ileeṣ BBC nipinlẹ Eko
- Awọn ọmọ Yoruba ti wa ni pẹsẹ lati ṣe eto ipese iroyin yii lojoojumọ pẹlu ẹrọ igbalode.









