BBC Pidgin Essay Competition 2019: Njẹ́ ìwọ le kọ àròkọ̀ ní èdè Pidgin?

Ẹni to bori lọdun 2018

BBC News Pidgin ṣe ifilọlẹ eto kikọ arokọ ni ede Pidgin to maa n ṣe lọdọọdun fun igba keji.

Idije naa ṣi silẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga ni Afirika.

Ẹnikẹni ti yoo ba kopa ninu idije naa gbọdọ kọ arokọ ti ko le ni ẹgbẹrin ọrọ (800 words) lori koko to da le, "Is Africa ready for female political leadership?"

Àkọlé fídíò, Imperial Majesty ni Olubadadan, Royal Majesty làwa, òfin sì tẹ̀lé e - Ọtun Olubadan

Awọn ọmọ igbimọ ti yoo mu ẹni to ba jawe olubori si ti wa; awọn ọmọ igbimọ naa wa lati awọn orilẹede to wa ni Iwọ oorun Afrika, ikọọkan wọn si jẹ yala olukọ, onkọwe, ati akọroyin ni ede Pidgin.

Gbogbo arokọ gbọdọ tẹle ofin ati ilana ede Pidgin, o si gbọdọ pa ofin girama naa mọ.

Wọn yoo kede ẹni to jawe olubori nibi eto kan ti yoo waye nilu Eko ni ogunjọ, oṣu Kẹsan, ọdun 2019.

Bakan naa ni olubori yoo gba ẹbun ẹẹdẹgbẹta Dọla (five hundred Dollars) lati fi ra iwe lori eto ẹkọ t'oun kọ.

Anfaani lati fi arokọ ranṣẹ ti ṣi silẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, yoo si wa si opin ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2019.

Ẹ fi arokọ ranṣẹ si [email protected]

Ninu ọrọ rẹ, Ọga agba fun BBC News Pidgin, Adejuwon Soyinka, sọ pe "eto arokọ kikọ ileeṣẹ iroyin BBC News Pidgin ti n di itage fun igbelarugẹ awọn ọdọ to jẹ onkọwe ati alarojinlẹ ni ede Pidgin to jẹ ede to gbajumọ laarin awọn ọdọ ilẹ Afrika.

Fun ẹkunrẹrẹ alaye lori bi o ṣe le kopa, to fi mọ ofin ati ilana, lọ si oju opo BBC Pidgin everi year essay Competition Terms and Conditions

Àkọlé fídíò, Àwọn òṣìṣẹ́ BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ìdùnnú lórí ayẹyẹ ọdún kan iléeṣẹ́ náà