Pension: Ohun tí o ní láti ṣe kí owó ìfẹ̀yìntì rẹ̀ má wọgbọ́

Àwòrán ìwọ́de NLC, TUC, ULC.
Àkọlé àwòrán, Àwọn òṣìṣẹ́

Ẹgbẹ awọn to ń ṣeto ifowopamọ owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ni awọn ati ri owo gba yoo nira fun awọn to n dawo sọdọ wọn bi wọn ba kọ lati ṣe iforukọsilẹ ori ẹrọ ayelujara.

Ọrọ yii jẹ jade ni ilu eko nibi ipade oniroyin pẹlu awọn adari meji lati awọn ile iṣẹ to wa ninu ẹgbẹ naa iyẹn PENOP ati ARM Pension nibi ti wọn ti fi hande pe aṣ taara latọdọ ajọ to n risi ọrọ owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ ni Naijiria (PENCOM).

Àkọlé fídíò, Onídájọ́ Fọlahanmi Oloyede léwájú ìwọ́de òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì fún ọjọ́ mẹ́ta l'Ọ́ṣun

"Lọwọlọwọ, miliọnu mẹsan awọn to n dawo la ni ṣugbọn a ni iṣẹlẹ awọn eeyan to ni nọmba aṣiri to pe oriṣiriṣi".

Nitori naa, wọn ṣalaye pe idi fun iforukọsilẹ ori ayelujara yii ni lati le foju to awọn ile iṣẹ wọnyẹ ki idanimọ fun ọlọ́dani le daju to bẹẹ ti eeyan ba san owo, wọn mọ pe ni to yẹ ni wọn n san an fun.

Lati ṣe eyi wọn ni nọmba idanimọ gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria ni awọn yoo lo eyi ti yoo jẹ nkan ara ọtọ lati da ẹni kọọkan mọ.

Àkọlé fídíò, Imperial Majesty ni Olubadadan, Royal Majesty làwa, òfin sì tẹ̀lé e - Ọtun Olubadan

Wọn tun ti lọ nọmba idanimọ orilẹede yii, NIN pọ mọ nọmba apapọ ile ifowopamọ BVN nitori naa ko ni si nkan to jọ pe ẹni ọtọ ni wọn n sanwo fun.

"Akanṣe eto ni ti o si pọn dandan fun gbogbo eniyan lati ṣẹṣẹ lọ tun fi orukọ wọn silẹ. O gba wa ni akoko gan lati ṣe bẹẹ fun eeyan miliọnu mẹsan ti a ni bayii nitori naa iṣẹ nla ni lati ṣẹṣẹ maa tun un ṣe".

Wọn ni niwọn igba ti awọn banki ba fi gbedeke ọjọ silẹ lasiko ti wọn n ṣe BVN, o ṣeeṣe ki awn naa ṣe bẹẹ fun eto yii.

"A ni ọpọlọpọ eeyan lati fi orukọ wọn silẹ, nitori naa, fun gbogbo ẹyin ti ẹ n gbọ, o san ki ẹ tete kara bọ ọ ko to pẹ".