NLC Kwara-Iṣẹ́ tí èèyàn kò bá tí ṣé, kò yẹ kó gba owó rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/NLC
Ohun to kọju si ẹni kan,ẹyin lo kọ si ẹlomiran lọri ki ijọba yara san owo oṣu oṣiṣẹ.
Igbesẹ Gomina ipinlẹ Cross River to yara san owo osu fawọn oṣiṣẹ lati fi ṣe moriwu ni asiko ayajọ ọjọ oṣiṣẹ lo mu ọrọ wa.
Bi awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ipinlẹ naa ṣe ni ìgbésẹ̀ naa ko daa to, lawọn to wa ni ipinlẹ miran ti n ni awọn ko lodi si.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC, Alaga ana fẹgbẹ oṣiṣẹ ni ipinlẹ Oyo, Siyanbade Waheed Olojede ni ko si ohun to buru ki wọn tete san owo oṣu fun oṣiṣẹ.
Alaga tẹlẹ ri ọhun ni pẹlu bi owo oṣu ko ti ṣe ma wa deede fawọn oṣiṣẹ kan lawọn ipinlẹ kan,o yẹ ki wọn ''lu eyikeyi Gomina to yara san owo lọgọ ẹnu''
Laarin ọṣẹ si igba ti wọn gba owo oṣu to kọja ni Gomina Ben Ayade paṣẹ ki wọn san owo oṣu eleyi ti awọn oṣiṣẹ ko ti ṣiṣẹ fun.
Siyanbade salaye pe ni ipinlẹ Oyo,''ijọba ipinlẹ ko jẹ ju owo oṣu kẹrin to ṣẹṣẹ pari lọ amọ fawọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ, a ri ibi ti wọn ti jẹ oṣu kan,oṣu meji,ati oṣu mẹta''
''Ko si ohun ti ẹni to n ṣiṣẹ ọba fẹ gba lọwọ ẹni to gba ṣiṣẹ to yatọ si owo oṣu''
Nipinlẹ Kwara, ọmọ ko sọri bakan naa nibi ti alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ọgbẹni Issa Ore ti ni isẹ ti eeyan ko baa ti ṣe ko yẹ ki o gba owo rẹ.
Issa ti wọn ṣẹṣẹ yan si ipo alaga sọ pe lootọ ni o da ki oṣiṣẹ tete gba owo oṣu ''amọ ko tọ ki wọn ti gba owo iṣẹ ti wọn ko ti ṣe rara''

Nipa sisan owo oṣu fawọn oṣiṣẹ ni Kwara o ni ijọba ibilẹ ni wahala wa ti owo oṣu ko lọ deede.
''Wọn ṣi n san owo fawa oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ,ti ibilẹ ni a ti ni ipenija''
Ko si ofin kankan to lodi si ki owo oṣu oṣiṣẹ maa di sisan saaju ki o to ṣiṣẹ tan ni Naijiria amọ ohun ti o wọpọ ni ki awọn Gomina ma j oṣiṣẹ lowo oṣu.













