#RevolutionNow: Ọlọ́pàá ní ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ gbàjọba ni ìfẹ̀hónú ọ̀hún

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force
Agbẹdọ! Tẹ ba danwo pẹrẹ, a o fimu yin danrin. Eyi ni ikilọ ọga ọlọpaa orilẹede Nàìjíríà, Mohammed Adamu fawọn to n gbero lati fi ẹhonu wọn han fun ijọba Naijiria lọjọ Aje lori aifararọ ilu.
Ninu ọrọ kan ti ọga ọlọpaa fi sita loju opo Twitter ile iṣẹ ọlọpaa lọjọ Abamẹta, o sọ pe ẹsun iditẹ gbajọba ati igbesunmọmi lawọn yoo fi kan ẹnikẹni to ba kopa ninu ifẹhonu han gbogbogbo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ile iṣẹ ọlọpaa sọ ninu atẹjade naa pe ohun ko ni gba ki ẹnikẹni ko tapa sofin Naijiria bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ Naijiria lẹtọọ labẹ ofin lati fẹhonu han ṣugbọn kii ṣe afipa sẹ bi iru eyi tawọn kan n gbero.
- Ó tó gẹ́ẹ́! Àsìkò tó láti fi ìwọ́de gba ara wa sílẹ̀ lọ́wọ́ ebi àti oko ẹrú - Sowore
- Ọ̀gá àgbá ọlọ́pàá pàṣẹ pé kí wọn ṣàwárí àwọn pásítọ̀ tí wọn jí gbé
- Èmi kò gbé pọ̀ pẹ̀lú Kollington Ayinla àmọ́ ọjà t'ọ́mọ ti wọ̀ lọ̀rọ̀ àwa méjééjì - Salawa Abẹni
- Òṣèré tíátà, Kemi Afolabi fi ohùn ìdúpẹ́ ránṣẹ́ láti Meccah fún àdúrà ọmọ Nàíjíríà
- Pásítọ̀ ọmọ Nàìjíríà, Omotoso, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kàn pàdánù ìwé ìgbélùú ní South Africa
Ile iṣẹ ọlọpaa ni gẹgẹ bi orilẹede olominira, eto idibo lọna kan gbogi tawọn ọmọ Naijiria le lo lati yi ijọba pada.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omoyele Sowore
Ọga ọlọpaa ni Naijiria lo anfani naa lati maa jẹ ki ẹgbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ 'Global Coalition for Security and Democracy in Nigeria' ti wọn lọ sibi ifẹhonu han lọjọ Aje, bibẹẹ kọ, ọwọ ofin lawọn agbofinro yoo fi mu wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
#FreeSowore: Àwọn ọmọ Nàìjíríà fi gbe ta lórí Sowore tí DSS mú
Ori ẹrọ ayelujare Twitter n gbona jainjain lẹyin ti iroyin sọ pe awọn olopaa ọtẹlẹmuyẹ(DSS) lorilẹede Naijiria ti ṣigun bo ile ọkan lara awọn oludije si ipo aarẹ lọdun 2019, Omoyele Sowore ni oru moju mọ Ọjọ Satide.
Iroyin naa sọ wi pe awọn ọlọpaa mu u lọ si agọ wọn pẹlu panpẹ lọwọ.
Ọpọlọpọ awọn to fesi lori ẹrọ ayelujara bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba saaju ifẹhọnu awọn ọmọ Naijiria, eleyii ti Sowore jẹ asaaju fun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4
Pẹlu #FreeSowore ni awọn eniyan fi n kesi ijọba lati tarasasa fi arakunrin naa silẹ nitori ẹtọ awọn ọmọ Naijiria ni lati fẹhọnu han, ti ijọba ba n se ohun ti ko tẹ wọn lọrun.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 5
Awọn miran se apẹrẹ orilẹẹde okeere ti o fun awọn eniyan laaye lati se ifẹhọnu, lai si ọlọpaa ti yoo kan ilẹkun wọn ni ọganjọ oru.

Oríṣun àwòrán, Others
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Ẹwẹ, nigba ti BBC kan si alukoro ile iṣẹ ọlọpaa, Frank Mba lati fi aridaju ọrọ yii lelẹ, ọgbẹni Frank ni iroyin naa ko tẹ oun leti di akoko ti a n sọrọ.
Ni aago kan kọja ni oru ni Sowore fi si oju opo Twitter rẹ pe awọn ọlọpaa ti de si ile oun, ti wọn si gba ẹrọ ilewo rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
Iroyin ọhun fi kun un wi pe o ṣeeṣe ki panpẹ ti wọn fi mu u nii se pẹlu ifẹhọnu han ti ọgọọrọ ọmọ Naijiria ti yoo waye ni Ọjọ Aje, ifẹhọnu han naa n ke si awọn ọdọ lati dide ja fun ẹtọ wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 8