Alleged incest: Ọkùnrin kan dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn fífi ipá bá ọmọ bíbí inú rẹ̀ méjì lájọṣepọ̀ ní ìlú Akure

Oríṣun àwòrán, Sola Ilesanmi
Ọkunrin kan, Femi onifade, ti dero atimọle ajọ abo araẹni labo ilu, NSCDC lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o fipa ba awọn ọmọ rẹ obinrin meji lopọ.
Iṣẹlẹ naa waye nile ẹni ọdun mejidinlaadọta ọhun lagbegbe Oluwatuyi nilu Akure.
Iroyin ni afurasi naa ma n rọ awọn ọmọde ọhun, to jẹ ẹni ọdun mẹfa ati mẹsan an ni ogun ko to gunle iwa buburu naa.
- Àsìkò wo ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò wọlé padà? Àwọn ǹkan ti a mọ̀ nìyìí.
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola 'I-sho Pepper', ògbóǹtagí òṣèré tíátà tó s'eré Yorùbá yíká Nàìjíríà
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin mẹ́rin pẹ̀lú orí èèyàn ní ìlú Akure
- Mọ síi nípa ohun tó ṣẹlẹ ní àwọn ibi tí wọn ti ṣilẹkùn ilé ìwé padà lẹyìn Covid 19
Awọn ara adugbo lo figbe ta nigba ti wọn n gbo igbe ọkan lara awọn ọmọ ọhun loru ọganjọ nigba to n ba laṣẹpọ.
Lẹyin ti aṣiri rẹ tu tan lo fẹsẹ lọ si afin ọba ilu Akure ki wọn to faa le ajọ NSCDC lọwọ.
Iya awọn ọmọ naa sọ fun awọn oniroyin pe awọn ọmọ mejeji sọ fun oun pe ootọ ni baba wọn ma n bawọn lopọ.
- Ìmáàmù àgbà ilẹ̀ Egba Sheik Liadi Orunsolu ti jáde láyé lẹ́ni ọdún 98
- A óò dá ẹnikẹ́ni tó bá gbé ìwé àti àṣírí ìjọba síta lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́ dúró - Ìjọba àpapọ̀
- Ènìyàn 229 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní ààrùn Covid-19 ní Nàìjíríà
- Èrò ọmọ Nàìjíríà sọ̀tọ̀tọ̀ lórí fàákájáa láàrin Abike Dabiri-Erewa àti mínísítà ètò ìbárẹ̀nisọrọ̀,

Oríṣun àwòrán, @allafrica
Agbẹnusọ ajọ NSCDC ipinlẹ Ondo, Femi Omole ni "Ọkunrin naa sẹ pe oun ko mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ayẹwo awọn dokita ni ile iwosan ijọba apapọ, FMC fi han pe wọn ti ba awọn ọmọ ọhun lopọ.
Omole ni afurasi ọhun yoo foju bale ẹjọ ni kete ti wọn ba ti pari iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Ni bayii, awọn ọmọ naa ti wa ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo to n ri si ọrọ awọn obinrin, kọmiṣọna ileeṣẹ naa, Titilayo Adeyemi si ti ṣeleri pe oun yoo tu iṣu de isalẹ ikoko iṣelẹ ọhun.
Ológun mú àwọn sọ́jà tó kọ́wọ̀ọ́ fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ fásitì AAUA lò pọ̀
Ile iṣẹ olgun Naijiria ni ilu Akure, ipinlẹ Ondo ni awọn ti mu àwọn sọja kan ti wọn fi ẹsun kan pe wọn pawọ pọ fipa ba akẹkọ onipele ikẹta ni fasiti Adekunle Ajasin, Akungba Akoko.
Wọn ti kọkọ ni irọ ni iroyin naa ti wọn si gba mọ awọn oniroyin ṣugbọn wọn pada rẹ ara wọn silẹ nigba ti fasiti naa tun funa mọ ọ̀rọ̀ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iroyin sọ pe ni Ọjọru ni awọn sja fipa ba akẹkọ ẹka imọ nipa ẹsin ati ẹkọ ilẹ Afirika ni fasiti naa lo pọ ni ibudo ayẹwo awọn ologun to wa ni opopona Ikare Akoko.
- 'Ibi àríyá ni àbúrò mi d'ágbére kí ọlọ́pàá tó fi ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ akọ-sí-akọ kàn án'
- Wo bí o ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ lẹ́kọ̀ọ́ ìbálòpọ̀
- Iléẹjọ́ fi Ọ̀jọ̀gbọ́n tó bèérè fún ìbálòpọ̀ ní fásitì OAU pamọ́ sọ́gbà ẹ̀wọ̀n
- Pásítọ̀ ọmọ Nàìjíríà, Omotoso, tí wọ́n fi ẹ̀sùn ìfipábánilòpọ̀ kàn pàdánù ìwé ìgbélùú ní South Africa
A gbọ pe ṣe ni sọja kan, Lance Corporal mu akẹkọbinrin ọhun ni dandan lati bọ silẹ ninu ọkọ ero kan ti o si paṣẹ pe ki awọn to ku ninu ọkọ maa lọ.
Ni wọn ba mu u lọ sinu koto awọn ologun lẹyin ibi ti wn ti n yẹ ọkọ wo wọn si ṣe e yana yana ni ti ibalopọ gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ.
Lọna rẹ pada sile pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ lati ile iwe ni awn sọja yii ti fipa mu u.
Ọjọ ẹti ni Ọgagun, Brigade Commander, Zakari Abubakar fi aridaju kan pe wọn ti fi ọwọ ofin mu awọn sja to ṣiṣẹ laabi ọhun wọn si ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun naa.
Awọn alaṣẹ fasiti AAUA naa ti fesi si eyi pe lootọ iwadii ti n lọ lọwọ lori ẹsun naa. Ẹwẹ wọn ọlọrọ gan ko tii wa fi ẹjọ ọ̀rọ̀ yii sun awọn lọna to tọ lati le gbe igbesẹ.
Adari ẹka iroyin ni fasiti AAUA, Victor Akinpelu tẹnu mọ pe ile iwe ti gbe igbesẹ lori iṣẹlẹ na bi o tilẹ jẹ pe "ọmọbinrin naa ko tii wa fi ẹjọ sun awọn alaṣẹ ile iwe lọna to tọ".
"Fasiti ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii iṣẹlẹ ọdun wọn yoo si gbe esi wọn jade laarin ọjọ perete".
Victor ni"mo gbagbọ pe lasiko iwadii ti igbimọ ba n ṣe wọn yoo pe ọmọbinrin naa fun ifọrọwanilẹnuwo leyii ti ọpọlọpọ kan mọ gbọyii sọyii lasan nipa iṣẹlẹ naa".
Nitori naa, Victor ni abọ iwadii igbimọ ni yoo ṣi aṣọ loju ohun gbogbo to ṣẹlẹ.














