Àwọn afurasí tí ọlọ́pàá ká orí èèyàn mọ́ lọ́wọ́ ní ìlú Akure ti fojú balé ẹjọ́

Akure
    • Author, Olumide Owaduge
    • Role, BBC Yoruba, Lagos

Oni ni igbẹjọ awọn afurasi ti ileeṣẹ ọlọpaa ka ori eeyan mọ lọwọ ní agbègbè Imafon ni Ipinle Ondo.

Ọwọ tẹ awọn ọkunrin mẹrin naa ti wọn jẹ agbẹboji ni ile isinku to jẹ ti ijọba ibilẹ Guusu Akure ni ọsu karun un ọdun 2020.

Awọn merin naa ti rojọ niwaju adajọ Magistrate to wa ni ilu Akure.

Akure

Femi Adeoye to jẹ agbẹjọrọ fun awọn afunrasi ọhun pe funh sinsun ẹjọ naa siwaju lẹyin to ni ileeṣẹ ọlọpaa ko lẹtọ láti pè fún ẹjọ́ naa.

Ṣaaju ni agbefọba ninu ile ẹjọ naa, Udom Ulo, ti ṣalaye pe awọn ajọ to n ja fẹtọ ọmọniyan tí pé fún gbigba ẹjọ́ náà lọ́wọ́ òun láti gbé fún àjọ miran to dantọ.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro mejeji, ile ẹjọ sun igbejo naa si ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa ọdun 2020.

Àkọlé fídíò, Ibadan Murder: Oyún oṣù méje ló ń bẹ nínú Azeezat, kí wọ́n tó f'òkúta fọ́ ọ lórí

Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin mẹ́rin pẹ̀lú orí èèyàn ní ìlú Akure

Ọga ọlọpaa Naijria

Oríṣun àwòrán, "PoliceNG/Twitter

Ọwọ ṣikun awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn mẹrin kan ti wọn ka ori eeyan mọ lọwọ nilu Akure.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Tee-Leo Ikoro lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC.

Awọn afurasi ọhun to jẹ agbẹboji ni ilẹ isinku to jẹ ti ijọba ibilẹ Guusu Akure ni ọwọ palaba wọn segi nibi ti wọn ti n gbiyanju lati ge ori oku kan ti wọn ṣẹṣẹ sin.

Ẹni ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ pe awọn mọlẹbi ologbe ọhun pada wa si ilẹ isinku naa lati mọ biriki le iboji rẹ, ni wọn ba ka awọn ọkunrin naa mọ ibi ti wọn ti n gbiyanju lati ge ori oku ti wọn sin ni wakati diẹ sẹyin.

"Lẹyin ti ọwọ tẹ wọn tan, ni a fi lilu bi i bara da wọn lọla nigba ti a ka ori obinrin kan ati awọn ori eeyan miran mọ wọn lọwọ."

Ẹwẹ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa sọ fun BBC pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ na.

O ni "Ni kete ti wọn ke si wa, ni awọn oṣiṣẹ wa lọ si ibẹ, ti a si gba awọn ọdaran naa mu lọrun ọwọ pẹlu ori eeyan ati awọn ẹya ara eeyan miran.

"Ni bayii, a ti bẹrẹ iwadii ni kikun lati mọ boya awọn kan lo ran awọn ọdaran naa niṣẹ tabi iṣẹ ara wọn ni wọn n jẹ."

Akure

Oríṣun àwòrán, others

Agbẹnusọ ọlọpaa naa pari ọrọ rẹ pe awọn afurasi naa yoo foju ba ile ẹjọ lẹyin iwadii.