Oyo NURTW: APC ni Auxilliary ṣiṣẹ́ fún lásìkò ìdìbò gómìnà 2019 kìí ṣe PDP

Auxilliary

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Oyo NURTW: APC ní Auxilliary ṣiṣẹ́ fún lásìkò ìdìbò gómìnà 2019 kìí ṣe PDP

Ọ̀kan nínú àwọn èèkàn ẹgbẹ́ awakọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo (NURTW) Alhaji Alidu Mustapha tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Weree ti bẹ̀nu atẹ́ lu alága tó rí si ìbáwí àwọn awakọ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo Alhaji Lamidi Mukaila, ó ní aláìmoore ni, nítori ọ̀rọ̀ tó sọ si èèkàn nínú àwọn olóṣèlú nípinlẹ̀ Oyo Alhaji Bisi Olopoeyan.

Mustapha ní Mukaila Lamidi ti gbogbo èèyàn mọ̀ sí Auxilliary kò fì ìgbà kankan ṣiṣẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) lásìkò ìdìbò tó gbé gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde wọ́le lọ́dún 2019.

Olórí NURTW nínú ìbánisọ̀rọ̀ pẹ̀lú akọ̀ròyìn kan nílùú Ibadan sàlàyé pé o bani nínújẹ́ pé Auxillary á ma sọ́rọ́ ìbanijẹ́ sí olóyè àgbà ẹgbẹ́ òṣèlù àti àwọn iṣẹ́ ribiribi tó ti ṣe fún ilọsíwájú ìgbéayé ènìyàn àwọn ènìyàn nípìnlẹ̀ Oyo

''Ọ̀rọ̀ Auxilliary lórí radio lọ́sẹ̀ tókọjá fi hàn pé olóye ẹgbẹ́ òṣèlú náà kò wúlò rárá. kìí ṣe olóṣèlú, kìí ṣe oníròyìn ti gómìnà Makinde bẹ̀ lọ́wẹ̀ láti sọ̀rọ̀ lórúkọ rẹ̀, kìí tún ṣe ọmọ ẹgbẹ́ PDP kí wá nìdí ti yóò fi maa sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀" Mustapha lo sọ èyí.

"Kìí ṣe Bisi Olopoeyan yìí náà ló fi Axilliary mọ Baba Adedibu ní ki o le di igbákejì Salako Eleweomo lọ́dun 2007"

"Bí ó ṣe máa ń sọ pé, òun lọ sẹ́wọ̀n nítori gómìnà Seyi Makinde, irọ́ ni, o lọ́ sẹ́wọ̀n nítori ìwà ọ̀daràn tó wù ni, nígbà tó sì dé lọ́dún 2019, ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti Adelabu lo bá ṣiṣẹ́.

Adelabu, Axilliary ati àwọn ẹgbẹ́ onimotò

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Oyo NURTW: APC ní Auxilliary ṣiṣẹ́ fún lásìkò ìdìbò gómìnà 2019 kìí ṣe PDP

"Ó gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù àti bọ́ọ̀sì Sienna lọ́wọ́ Adebayo Adelabu. Ó ṣiṣẹ́ fún APC lọ́dun 2019 gẹ́gẹ́ bi ọmọọ̀ta ní kìí ṣe bi ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú"

Mustapha fi kún-un pé ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí gómìnà Makinde kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi alága ìgbìmọ̀ ìbáwí fún ẹgbẹ́ awakọ̀ nípìnlẹ̀ Oyo.

Ó ní gómìnà Makinde já aráilú kulẹ̀ nípa yíyàn tẹ̀wọ̀ndé gẹ́gẹ́ bi asojú egbẹ́ awakọ nípìnlẹ̀ Oyo láì tẹtí sí igbe àwọn ará ìlú.

Mustapha ti ke sí gómínà Seyi Makinde láti ṣe satúngbéyẹwò àwọn ètò ìjọba fún ẹgbẹ́ awakọ l'Oyo kí wàhála tó bẹ́ silẹ̀.

Gbogbo ìgbìyànjú BBC News Yoruba láti gbọ́ tẹnú Mukaila Lamidi tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Auxilliary nípa ẹsùn náà jásí pàbó bí ó ṣe ni kí a pè òun padà, sùgbọ́n tí ko gbéaaggo rẹ̀ mọ́ nígbà tí a pèé padà.