Sheikh Liadi Orunsolu: Ìmáàmù àgbà ilẹ̀ Egba ti jáde láyé lẹ́ni ọdún méjídínlọ́gọ́rùn ún

Oríṣun àwòrán, @kollysmith
Imaamu agba ti ilẹ Egba, Sheik Liadi Orunsolu ti jade laye.
Iroyin ni imaamu naa jẹ Ọlọrun nipe laarọ ọjọ Iṣẹgun ni ile rẹ to wa ni ilu Abeokuta lẹni ọdun mejidinlọgọrun un.
Ko to jade laye, Sheik Orunsolu ni aarẹ fun gbogbo awọn imaamu ati aafa ni ipinlẹ Ogun.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin mẹ́rin pẹ̀lú orí èèyàn ní ìlú Akure
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola 'I-sho Pepper', ògbóǹtagí òṣèré tíátà tó s'eré Yorùbá yíká Nàìjíríà
- Mọ síi nípa ohun tó ṣẹlẹ ní àwọn ibi tí wọn ti ṣilẹkùn ilé ìwé padà lẹyìn Covid 19
- A óò dá ẹnikẹ́ni tó bá gbé ìwé àti àṣírí ìjọba síta lórí ayélujára lọ́nà àìtọ́ dúró - Ìjọba àpapọ̀
Ologbe ọhun ti n ba awọn aisan kan to ni ṣe pẹlu ọjọ ogbo finra ki awẹ Ramada to bẹrẹ, ko pẹ diẹ si asiko yii lo dagbere faye.
Imaamu naa yoo wọ kaa ilẹ sun gẹgẹ bi ilana ẹsin Musulumi.








