Ammended Terrorism prevention Act: Ẹ̀wọ̀n gbére tàbíì dájọ́ ikú fún ajínigbé títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ ni àbájadé òfin túntun lórí ìjínigbé

ile aṣofin agba NAijiria.

Oríṣun àwòrán, Senate Nigeria

Ilé aṣòfin Nàìjíríà buwọ́lu ẹ̀wọ̀n ọdún 15 fún ẹnikẹ́ni tó bá san owó fún ìtúsílẹ̀ ẹnikẹ́ni láhámọ́ ajínigbé tàbí agbésùnmọ̀mí

Ilé aṣòfin Nàìjíríà buwọ́lù ìyípadà òfin tó dé ijinigbe, kókó pàtàkì rèé nínú rẹ̀Bí o bá san owó fún ìtúsílẹ̀ ẹnikẹ́ni láhámọ́ ajínigbé, ẹ̀wọ̀n ọdún 15 wà níkàlẹ̀ fún ọ

Ijinigbe ti di ọgbẹ ọkan nla fawọn araalu ni Naijiria sugbọn sisan owo lati doola awọn ti wọn ji gbe ti wa tun dakun isoro araalu.

Fawọn alaburu ajinigbe pawo yi, ọna kan gbogi leleyi jẹ lati ri owo lọna aitọ.

Eleyi jẹ nkan to kan awọn asofin lominu ti wọn si kede atunse ofin to dena iwa igbesunmọmi taa mọ si Terrorism (Prevention) Act, 2013.

Eyi to jẹ iyipada tuntun ninu ofin yi ni fifofin de ki eeyan san owo fawọn ajinigbe.

Ijinigbe

Oríṣun àwòrán, others

Ki ni ohun to wa ninu iyipada ofin yi?

Igbimọ ile asofin agba to n ri si ọrọ ẹka idajọ ẹtọmọniyan ati ọrọ to ni se pelu ofin lo daba iyipada lori ofin to wa lori ijinigbe tẹlẹ.

Sẹnẹtọ Opeyemi Bamidele si lo lewaju igbimọ yi to si ni:

"Idi ta fi mu iyipada ba ofin yi ni lati dẹkun ọwọja ijinigbe ati sisan owo fawọn ajinigbe ni Naijiria''.

Lẹyin ti igbimọ se agbekalẹ iwadii wọn niwaju ile asofin agba,ile buwọlu atunto ofin yi lọjọru.

Àkọlé fídíò, Basorun Akinade Ayoola Yusuf: Ìsìnkú Aláàfin Oyo àti Ooni Ile Ife yàtọ̀ nílẹ̀ Oodua

Awọn koko pataki to wa ninu iyipada ofin yi:

•ẹwọn gbere fun ajinigbe ti ile ẹjọ ba da lẹbi

•bi ẹni ti wọn jigbe ba ku, idajọ iku ni fun ajinigbe

•ofin yi gbe aba ẹwọn ọdun mẹẹdogun silẹ fun ẹnikẹni to ba san owo idoola fun ajinigbe

Ninu gbogbo iyipada si ofin yi taa ka silẹ eleyi to mu iriwisi wa ni ti ẹwọn ọdun mẹẹdogun fun ẹni to san owo lati fi doola mọlẹbi tabi ọrẹ lọwọ ajinigbe.

Àkọlé fídíò, Elebuibon: Àwọn àṣà àtọ̀húnrìnwá ló fa títa ẹ̀jẹ̀ nítorí ògùn owo

Eleyi n waye pẹlu bawọn eeyan kan se n sọ pe sisọ sisan owo idoola di ẹsẹ labẹ ofin yoo tunbọ mu inira ba awọn ti eeyan wọn ba wa lahamọ ajinigbe.

Ibagbọ ọpọ ni pe ijọba ko se ohun to yẹ lati jẹ ki ijinigbe ma tiẹ waye rara depo pe mọlẹbi yoo ni lati san owo idoola.

Lọpọ igba awọn eeyan a maa woju ijọba ati awọn ragbofinro lati doola wọn lọwọ ajinigbe sugbọn wọn kii ri iranlọwọ kankan.

Ijinigbe ni Naijiria,ọjọ ti pẹ

Naijiria ko sẹsẹ maa koju ipenija ijinigbe ki bayi .

Lara ohun to n dẹru ba ọpọ bayi ni ki eeyan wọn ko si ọwọ ajinigbe ki wọn si nilo lati san owo idoola.

Ọkẹ aimọye eeyan lawọn ajinigbe ti gbe ti wọn a si maa beere owo idoola lọpọ igba.

Àkọlé fídíò, LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé

Pẹlu bi nkan se ri ni Naijiria bayi, isẹ ajinigbe ti wa pawo taara bayi ti ko si yọ awọn agbegbe kankan silẹ.

Ọrọ naa ti wa n dabi ẹni pe ipa awọn agbofinro ijọba ko ka nkan to wa nilẹ yi.

Lati Guusu titi to fi de Ariwa Naijiria ipenija nla ni ijinigbe jẹ.

Ko si ẹni ti ko le ko sọwọ ajinigbe .Ati akẹkọọ ni kilasi tabi ni ile igbe wọn, ọmọ kekere ni ile, agbalagba, arinrinajo ati bẹẹbẹẹ lo wa ninu ewu ijinigbe.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Bi a ko ba gbagbe, laipẹ yi ni awọn ajinigbe gbe arinrnajo reluwee gbe losu Kẹrin ni Kaduna.

Eeyan mejidinlaadọsan la gbọ pe o wa ninu reluwee.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Koda, awọn ajinigbe yi tun fi aworan awọn to wa ni ahamọ wọn sita lai bikita boya awọn agbofinro yoo mu awọn.

Ileesẹ reluwee fidi ọrọ yi mulẹ ti wọn si ni eeyan mejileniọgọta lo wa ni ahamọ ajinigbe.

Titi di asiko yi,ijọba lawọn n gbiyanju lati tu awọn eeyan yi silẹ ni.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

Bí o bá san owó fún ìtúsílẹ̀ ẹnikẹ́ni láhámọ́ ajínigbé, ẹ̀wọ̀n ọdún 15 wà níkàlẹ̀ fún ọ

Ileegbimọ aṣofin agba ni Naijiria ti buwọlu atunṣe abadofin igbesunmọmi ni Naijiria Terrorism (Prevention) Act, 2013 eleyi to sọ sisanwo itusilẹ fun awọn ajinigbe di ẹṣẹ si ofin lorilẹede Naijiria.

Ileegbimọ aṣofin agba fọwọsi abadofin naa lẹyin ti igbimọ kokari lori ọrọ eto idajọ, ẹtọ ọmọniyan ati ọrọ gbogbo to nii ṣe pẹlu ofin gbe e yẹwo ti wọn si gbe wa siwaju ile.

Abadofin naa, gẹgẹ bi ohun ti alaga igbimọ naa, Ọpẹyẹmi Bamidele, ṣe lalaye niwaju ile lọjọru, yoo sọ sisanwo itusilẹ fun awọn ajinigbe lati tu ẹnikẹni ti wọn ba ji gbe silẹ di ẹṣẹ si ofin lorilẹede Naijiria.

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, pataki ofin yii ni lati dẹkun ọwọja ijinigbe eleyi to ti n fẹju tantan gẹgẹ bii owo nla lorilẹede Naijiria.

O ni gbigbe awọn ofin ti yoo koju ija si sisanwo fawọn agbesunmọmi yoo dẹkun gulegule owo ijinigbe lorilẹede Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ ile aṣofin agba lorilẹede Naijiria, Ahmad Lawan ni abadofin naa yoo kun ijọba apapọ lọwọ ninu ilakaka rẹ lati gbogun ti eto abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria bi aarẹ Buhari ba le buwọlu abadofin naa.

Àkọlé fídíò, Wọ́n jí pè mi láàrọ̀ pé ọmọ mi bímọ, ó dákú àmọ́ bí mo ṣe débẹ̀, àt'òkú ọmọ mi, àt'òkú

Bi aarẹ Buhari ba lee buwọlu abadofin yii, yoo jẹ wi pe, ẹwọn ọdun marundinlogun ni ẹnikẹnu to ba lufin abadofin yii yoo fi gbara.

Abala ikẹrinla ofin naa sọ wi pe "Ẹnikẹni to ba fi owo ranṣẹ, tabi san owo fun ajinigbe tabi agbesunmọmi kankan lati gba itusilẹ ẹnikẹni ti wọn gbe pamọ lọna aitọ, tabi jigbe jẹbi iwa ọdaran labẹ ofin yii bi ile ẹjọ ba si da a lẹbi yoo fi ẹwọn ti ko din ni ọdun marundinlogun gbara."