Fatemi Elebuibon: Àkókò Alaafin, Soun àti Olubadan ti tó ló jẹ kí wọ́n papòdà

Oríṣun àwòrán, @Fayemi Elebuibon
Kìí ṣe nǹkan abàmì bí Alaafin, Soun àti Olubadan ṣe papòdà lèralèra - Elebuibon
Araba awo ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibon ti sọ pe ko si ohun abami kankan ninu ipapoda Alaafin ilu Oyo, Oba Lamidi Adeyemi; Soun ti ilu Ogbomosho, Oba Jimoh Oyewumi, ati Olubadan ti ilu Ibadan, Oba Saliu Adetunji to waye lerelera laarin oṣu marun un sira wọn.
Elebuibon ni asiko awọn ori ade naa lo to, ti wọn fi lọ ree darapọ awọn babanla wọn, kii ṣe pe ejo lọwọ ninu.
- Nínú àwòràn, wo ìgbà ayé Aláafin Oyo, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta tó lọ bá àwọn Baba Ńlá rẹ̀
- Ta ni Yorùbá ń pè ní Abọ́bakú?
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà
- Mọ̀ síi nípa Olorì Abibat Nihinlola Adeyemi tó ti lo ọdún 60 gẹ́gẹ́ bíi olorì láàfin Alaafin Oyo
- Èèyàn bí méjì kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò tí àwọn afurasí ọmọ Auxiliary àti Isota kọlu ara wọn ní Ibadan
- Ìyàwó Olúbàdàn, Olorì Joyce ti darapọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Islam
- Wọ́n ti ṣe ìsìnkú àpapọ̀ fún èèyàn 50 lára àwọn tó jóná níbúdò ìfọpo tó gbiná ní Imo
Bawo ni awon Oba Alade yii se pa ipo da?
Soun waja ni ọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2021 nigba ti Olubadan waja lọjọ Keji, oṣu Kinni, ti Alaafin si papoda ni ọjọ Ẹti, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022.
Nigba to n sọrọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle Punch, Elebuibon ni "Ko si ohun abami to wa nidi ipapoda wọn, akoko wọn lo de, awọn baba nla wọn pe wọn, wọn si jẹ wọn nipe."
Nigba to n sọrọ lori alafo ti ipapoda awọn ori naa yoo fi silẹ ni ipinlẹ wọn, Elebuibon sọ pe aye wọn yoo yọ silẹ laarin ilu nitori awọn ojuṣe wọn, to fi mọ awọn ipo ti wọn di mu lawujọ.
Ni ti oyin to le awọn eeyan kan lere nibi eto isinku Alaafin, Araba awo ilu Osogbo ni kii ṣe nnkan babara, o kan waye bẹẹ ni.
O ni "Ẹnikan lo ṣkunfa rẹ, ẹni naa lọ sibi ti awọn oyin ọhun wa o si le wọn kuro nibẹ, boya o fẹ ṣẹru ba awọn eeyan ni, a ko le sọ."
"Ohunkohun tii ba wu ko jẹ, kii ṣe ọwọ awọn alalẹ."
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ogun ti ba awọn eeyan ilu ̣Oyo kẹdun ipapoda Alaafin to tẹri gbaṣọ.
Ẹni ọdun mẹtalelọgọrin ni Iku Babayeye ko to lọ darapọ mọ awọn babanla rẹ.
















