Alaafin of Oyo: Ààrẹ Buhari, Ooni Ile Ife, Obasanjo àtàwọn èèkàn míràn kẹ́dùn Alaafin Oyo tó wàjà

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III
Ni owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹrin ọdun 2023 ni gbogbo ọmọ Ooduwa ji si iroyin ipapoda Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Ọlayiwọla Lamidi Adeyẹmi Kẹta.
Gẹgẹbi iroyin ṣe sọ, alẹ ọjọ Ẹti ni Ọba Adeyẹmi waja.
Ni bayii, Ọkọn o jọkan awọn eekan ilẹ Yoruba atorilẹede Naijiria lapapọ ni wọn ti n kẹdun lori iku rẹ.
- 'Abọ́bakú wà fún Alaafin Lamidi Adeyemi III tó wàjà'
- Wo bí àwọn Alfa ṣe kírun sí Aláàfin lára àti ètò tó kàn láti gbé e wọ káà ilẹ̀
- Aláàfin àti Ọba ilẹ̀ Yorùbá márùn-ún mìí tó wàjà láàrin oṣù márùn-ùn péré
- Ìdí tí Osinbajo fi ṣèbẹ̀wò sí Olubadan àti ohun tí wọ́n sọ rèé
- Wo àwọn ǹkan tí o kò mọ̀ nípa Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò tó wàjà
- Kéte ti Baba dákẹ́ ni àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ti bẹ̀rẹ̀ l'Áàfin - Ẹ wo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Aafin Oyo
Alaafin ko fi ọrọ idagbasoke ọmọniyan, paapaajulọ orilẹede Naijiria ṣere rara -Muhammadu Buhari, Aarẹ orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, PresidencyNigeria
Alaafin Lamidi Adeyẹmi to waja jẹ ọlọpọlọ pipe to kopa rẹ ninu eto idagbasoke orilẹede NAijiria
Aarẹ Muhammadu Buhari tọka si eyi ninu ọrọ ikẹdun rẹ lori ipapoda iku baba yeye
O ni idagbasoke ọmọniyan jẹ ohun kan ti Ọba Adeyẹmi ko fi ṣere rara
Ninu atẹjade kan ti Amugbalẹgbẹ fun aaarẹ orilẹede Naijiria lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Fẹmi Adesina fi sita, Aarẹ Muhammadu Buhari ni gbogbo ọna ni ọdun mejilelaadọta ti Alaafin Adeyẹmi kẹta fi wa lori itẹ fi yatọ nitori ilepa alaafia ti Ọbalaye naa dimu.

Oríṣun àwòrán, Alaafin Adeyemi III
"Ọbalaye to lọwọ pupọ ni Alaafin gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria ṣe sọ ti ikopa rẹ ninu awọn ipade apapọ lori ọjọ ọla orilẹede Naijiria maa n mu ọpọ ọrọ ọgbọn dani ti kii sii ṣẹ ẹnu ku lati ṣalaye ọrọ lori iṣọkan ati iṣejọba to mu igbayegbadun araalu dani.
Aarẹ Buhari ki igbimọ lọbalọba ipinlẹ Ọyọ, ẹbi Ọba Lamidi, awọn ọrẹ ati ojulumọ rẹ ku ara fẹraku,paapaajulọ ẹka ti ere idaraya nibi to ni ipa rẹ ko ti lee parun laelae.
Igi nla lo lọ nigbo ilẹ Oodua - Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Ọọni Ile Ifẹ Aṣiwaju ọba Iran Yoruba
Ninu ọrọ to fi sita lati kẹdun Alaafin ilu Ọyọ, Ọọni ile ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja Keji ni gbogbo ilẹ Oodua lo padanu eeyan nla pẹlu ipapoda Alaafin Adeyẹmi kẹta.

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III
Ọọni Ogunwusi ni Ọbalaye to fẹ alaafia laarin awọn ọmọ Yoruba gbogbo ni Ọba Ọlayiwọla jẹ, gbogbo igba aye rẹ lo si fi jin fun igbeleke aṣa Yoruba.
"Igi nla la padanu, Ọba nla to dari Ọyọ lasiko ọlaju wọ idagbasoke igbalode laui pa aṣa ati iṣẹṣe to rọ mọ itẹ ti Alaafin Ọranmiyan kọkọ joko le lori jẹ"
Ọba Ogunwusi wa rọ awọn Ọyọmesi lati rii daju pe wọn ko jẹ ki ọlaju to bayejẹ bayii ni ohunkohun pada nipa ilana isinku Alaafin to waja ati yiyan Alaafin tuntun nitori pe ipo Alaafin wuwo pupọ ninu aṣa ati iṣẹṣe Yoruba ju eyi ti wọn lee fi ọwọ gbẹfẹ mu.
Ọba Adeyẹmi, ohun kan ṣoṣo to n fọnrere iduroṣinṣin lẹnu iṣakoso ijọba orilẹede - Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Aarẹ tẹlẹ lorilẹede NAijiria

Oríṣun àwòrán, other
Ninu ọrọ ikẹdun to fi sita, Aarẹ Naijiria nigbakan ri, Oluṣẹgun Ọbasanjọ ṣe apejuwe Alaafin Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta gẹgẹ bi olupolongo ibarẹ̀pọ ati igbọraẹniye laarin awọn eeyan ibuba rẹ ati kaakiri Naijiria.
O ni lasiko ba Adeyẹmi ni ilu Ọyọ yipada di ọtun. O ni ilakaka rẹ fun idagbasoke orilẹede Naijiria lo mu ki wọn fi oye Commander of the Federal Republic da a lọla.
"Gẹgẹ bi ọpọ awọn aṣiwaju nla, alaafin jẹ ohun gbogbo fun gbogbo eeyan,"
Adanu nla ni iku Alaafin fun ipinlẹ Ọyọ ati iran Yoruba - Seyi Makinde, Gomina Ipinlẹ Ọyọ lẹkun iwọ oorun gusu Naijiria

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oba Adeyemi III
Gomina Seyi Makinde ṣe akawe Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta gẹgẹ bi aṣiwaju rere, ọbalaye to n ṣe atilẹyin fun mutumuwa ti kii si ye sa ipa gbogbo to yẹ lati rii daju pe ipinlẹ Ọyọ ati Naijiria goke agba.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Taiwo Adisa kọ sita, Gomina Makinde woye pe adanu nla ni ipapoda Alaafin Ọyọ jẹ fun ipinlẹ Ọyọ, iran Yoruba ati orilẹede Naijiria.
O ni awọn ọrọ imọran ati igbaniniyanju ti Alaafin maa n sọ ko lakawe, eyi to ni eyi to gbẹyin ninu awọn igi nla ti n di igbo mu laarin iran awọn ọbalaye ilẹ Yoruba kan ni Alaafin laarin awọn ọbalaye ti wọn pẹ lori itẹ awọn babanla wọn.
Gomina Makinde fi kun un pe bi a ba n sọrọ awọn ọ̀balaye to jẹ ọjọgbọn ninu itan ati ilana ile ọba nilẹ Yoruba, agba ni Alaafin Adeyẹmi jẹ nitori o ti ni iriri to pọ nipa itan Yoruba, oṣelu nilẹ̀ Yoruba pẹlu idagbasoke ilu.
Opin saa kan ni iku Alaafin jẹ - Ọba Abdulrasheed Akanbi, Oluwo ti ilu Iwo
Ninu ọrọ tirẹ, Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Akanbi ti ba awọn ẹbi Alaafin Adeyẹmi kẹdun. Bakan naa lo tun ba awọn Ọyọmesi, ilu Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ ati gbogbo Naijiria lapapọ kẹdun.
Ọba Akanbi ni adanu nla ni iku Alaafin Adeyẹmi jẹ fun oun, paapaajulọ bi o ti jẹ pe lọsẹ to kọja loun ṣi bẹ baba wo pẹlu adehun ati tun fojurinju loṣu karun.
"Ta ni wa lati bi Ọlọrun lẹjọ?"












