Alaafin of Oyo: Abọ́bakú wà fún Alaafin Lamidi Adeyemi III tó wàjà, ohun tí yóò sì ṣẹlẹ síi nìyí

Aworan Alaafin Adeyẹmi III

Oríṣun àwòrán, other

Ṣe Abọbaku yoo wa fun Ọba Lamidi Adeyẹmi kẹta, Alaafin ti ilu Ọyọ to waja?

'Abọ́bakú wà fún Alaafin Lamidi Adeyemi III tó wàjà'

Ibeere yii lawọn eeyan kaakiri agbaye n beere lẹyin ti ọbalaye nii darapọ mọ awọn babanla rẹ lọjọ Abamẹta.

Ko si si idi meji ti ibeere yii fi gbilẹ bi ko ṣe nitori ipo ti ọrọ aṣa ati iṣẹṣe dimu ninu eto oye jijẹ ni ilu Ọyọ, ati paapaa bi Kabiyesi Alaafin tilu Ọyọ to waja ṣe kundun gbogbo ohun to ba ti niiṣe pẹlu aṣa.

Ta ni Abọbaku?

Itumọ abọbaku ni ẹni ti yoo ba ọba ku nigba ti ọba ba waja.

Ilu Ọyọ ni aṣa yii ti kọkọ gbilẹ gẹgẹ bi ọpọ itan ṣe sọ.

Àkọlé fídíò, Oru tí olóríibú máa ń di olóríire ni "Laylatul Qadr", tóo bá bẹ Ọlọ́hun, orú agbára gidi ni - Akeugbagold

Ilu Ọyọ aye ọjọun si ni a gbọ pe o ti bẹrẹ.

Abọbaku si ni ẹni ti wọn maa n fi ẹmi rẹ de ẹmi Kabiyesi nitori awọn to ba fẹ wa iṣubu kabiyesi nigba naa.

Niwọn igba ti abọbaku si ti mọ pe bi Kabiyesi ba ti lọ ni oun pẹlu nlọ, Abọbaku maa n fi gbogbo ẹmi rẹ lepa alaafia ati igbayegbadun Alaafin nigba naa ni.

Àkọlé fídíò, Jimi Solanke: Bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ eré òṣùpá láyé àtijọ́ táa mú ìtàn Yorùbá sísọ dé America padà

Ṣe Abọbaku wa fun Alaafin Adeyẹmi kẹta?

Gẹgẹbi iwadi BBC News Yoruba, Abọbaku wa fun Alaafin Lamidi Adeyẹmi.

Ọkan lara awọn ọmọ aafin nilu Ọyọ ti a ba sọrọ laafin Ọyọ lọjọ Abamẹta ṣalaye pe lootọ ni Abọbaku wa fun Alaafin Adeyẹmi Kẹta ṣugbọn wọn ti yi orukọ rẹ pada si 'Oloko ehin'.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

O fi kun un pe gẹgẹ bi aṣa ati iṣẹṣe nigba iwasẹ, o yẹ ki Oloko Ẹhin ba alaafin Adeyẹmi ku ni ṣugbọn aṣa ti yi pada, oro ni wọn yoo ṣe dipo rẹ.

Ninu alaye rẹ, O ni oro kan wa ti awọn yoo ṣe fun awọn abobaku naa lati dena titẹle Ọba naa waja.

Àkọlé fídíò, Nigeria movie industry: Àgbà òṣèré, Lere Paimo ní àìgbọràn ló ń da ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn