2023 Presidency: Wo ohun tí ìgbákejì ààrẹ àti Olubadan sọ lásìkò ìbẹ̀wò rẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Igbakeji aarẹ Ọjọgbọn Yemi Osinbajo to tun jẹ ọ̀kan lara awọn oludije fun ipo aarẹ ti lọ ṣe ibẹwo si Olubadan ti ilu Ibadan, Sẹnetọ Lekan Balogun lati fi too leti nipa erongba rẹ ati dupo aarẹ.
Ọba alade naa si ti gbadura fun igbakeji aarẹ pẹlu bo ṣe ni "mo kasẹ ọrọ mi nilẹ nipa gbigbe ọle Allah lọwọ lati da abo bo ẹ".
Bakan naa ni igbakeji aarẹ ṣepade pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ti ipinlẹ Oyo.
Lasiko ti wọn jọ n sọrọ, o ni oun ni igboya pe ni gbogbo ọdun meje sẹyin gẹgẹ bi igbakeji aarẹ, o ti ṣe igbaradi fun oun fun ipo giga.
Nigba to n gbe iwe aato oṣelu siwaju awọn aṣoju ẹgbẹ naa, igbakeji aarẹ ni oun ti lo iye ọdun bii melo yii sẹyin ni oun ti fi kọ ẹkọ ati igbaradi.
Fun idi eyi lo ṣe gbagbọ pe oun ni iriri to koju osuwọn lati kan lu agbami adari lati dije du ipo aarẹ ti yoo gba eku ida lọwọ Buhari.
"Pẹlu gbogbo irẹlẹ lonii ni mo fi n kede erongba mi lati du ipo aarẹ orilẹede Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu nla wa"APC, o sọ eyi ninu fidio kan ti ileeṣẹ Channels fihan.
Ikede rẹ yii lo mu opin wa si ọpọlọpọ ireti ati ero awọn eniyan Naijiria lati mọ boya yoo dije eyi to si tun ti ṣi aaye silẹ fun ọpọ eeyan lati darapọ mọ awọn to n kede ati dije.
















