Olubadan of Ibadan coronation: Olúbàdàn tuntun, Ọba Lekan Balogun Ali Okùmádé kejì ṣèlérí lẹ́yìn tó gbọ̀pá àṣẹ

Oríṣun àwòrán, Aso rock villa
Wọn ti gbe ade ati ọpa aṣẹ fun Olubadan tuntun, Sẹnetọ Lekan Balogun nilu Ibadan lọjọ Ẹti.
Gbagede gbọngan nla Mapo ni Ọjaaba ni ayẹyẹ igbọpa aṣẹ Ọba Lekan Balogun Okumadade Keji ti waye gẹgẹ bii Olubadan ikẹejilelogoji.
Aṣọ oke ti wọn koṣe to duro si lara ni Kabiyesi Olubadan tuntun wọpẹlu ade funfun tẹwa gba ọpa aṣẹ rẹ lọwọ gomina ipinlẹ yọ, Seyi Makinde lọsan ọjọ Ẹti niwaju awọn eekan, ladelade, loyeloye atwaọn olori lẹkajẹ̀ka gbogbo lawujọ.
- Dókítà ní ọdún márùn-ún ló kù fún mi láyé, mo sì ti lò lára rẹ̀ - Òṣèré Kemi Afolabi
- Àwọn gómìnà 'yahooyahoo' ní APC ló ń ti Buni láti da ojú ètò ìdìbò adarí ẹgbẹ́ bolẹ̀ - Gómìnà Rotimi Akeredolu
- Lẹ́yìn tí wọ́n gba ipò alága NURTW lọ́wọ́ rẹ̀, MC Oluomo yapá kúró ní NURTW
- Ìrírí tí Ilana Omo Oodua àti Sunday Igboho rí lósù mẹ́fà yìí tí kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ síi- Ojogbon Banji Akintoye
Lara awọn eekan to wa nibi ayẹyẹ naa ni awọn ọbalaye bii:
-Ọọni ile Ifẹ, Oba Adeyẹye Ogunwusi,
-Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi;
-Sultan ti ilu Sokoto, Alhaji Saád Abubakar kẹta, pẹlu
-Emir ti ilu Kano, Alhaji Ado Bayero atawọn miran.
Bakannaa ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo to ṣoju fun Aarẹ Muhammadu Buhari, ati igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar pẹlu wa nibi ayẹyẹ naa.

Oríṣun àwòrán, oyo state government
Ilana iṣẹmbaye oye jije ilẹ Ibadan lo bori - Gomina Seyi Makinde
Lẹyin to gbe ọpa aṣẹ le Olubadan tuntun naa lọwọ tan, Gomina Seyi Makinde kan sara si awọn Oloye ilẹ Ibadan ati gbogbo ọmọ bibi ilẹ Ibadan fun Igbade Ọba Lekan Balogun Ali Okumade keji.
Gomina Makinde ni lẹyin o rẹyin ilana iṣẹmbaye oye jije ilẹ Ibadan lo bori eleyi to ni o fun iṣejọba iṣẹmbaye lẹnu ọrọ.
- Wọ́n ti gbé dẹ́rẹ́bà ọ̀kọ̀ BRT tí Bamise wọ̀ lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kirikiri
- Ìlù ti yí, orin ti séńjì! Ẹni tí yóò jẹ Olubadan yóò ní àmúyẹ tuntun - Ìgbìmọ̀ Olubadan
- Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ ilú Ìbàdàn buwọ́lu Lékan Balógun gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn tuntun ṣùgbọ́n....
- Olubadan tuntun yóò di mímọ̀ lọ́jọ́ Ajé - Gómìnà Makinde
- Arẹ́májà kò sí, Olubadan fi tìlù-tìfọn kí àwọn ìjòyè káàbọ̀ lẹ́yìn ọdún méjì
O wa rọ Ọba tuntun naa lati rii daju pe ko yẹ kuro ni ilana oye jijẹ ilẹ Ibadan to ba nilẹ ki o si rii daju pe awọn oloṣelu ko toju bọ ọrọ oye jijẹ mọ nilu Ibadan.
"Mo fẹ lo anfani yii lati rọ kabiyesi atawọn igbimọ oloye ilẹ Ibadan lati rii pe wọn ṣiṣẹ tọ bibọwọ fun ofin oye jijẹ ilẹ Ibadan.
"Bi wọn ba si wo o pe o yẹ fun atunṣe, irufẹ atunṣe bẹẹ gbọdọ waye laarin igbimọ wọn."
"Igbimọ Oloye Ibadan lo yẹ ko maa ṣe akoso ati atunto ara rẹ laisi ọwọ atọrunrinwa tabi ajeeji kankan latọdọ awọn oloṣelu."

Oríṣun àwòrán, Aso rock villa
Ọba Ọlalekan Balogun Ali Okumade Keji ti gbaradi fun ipo yii lati ọjọ pipẹ - Aarẹ Buhari
Aarẹ Muhammadu Buhari wa nilu London nibi to ti n gba itọju ṣugbọn o ran Igbakeji rẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo lọ sibi ayẹyẹ naa to si ki Olubadan tuntun ku oriire.
Nigba to n jiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari, Igbakeji Aarẹ Oṣibajọ tọka si pataki ilẹ Ibadan ninu idagbasoke Naijiria.
O ni pe o bẹrẹ lati asiko ijọba amunisin, to si gbadura fun alaafia ati idagbasoke ilẹ Ibadan lasiko Olubadan kejilelogoji to jẹ.
"Kabiyesi Alayeluwa, Olubadan ti ilẹ Ibadan, mo gbadura fun yin pe ẹ o pẹ lori apere, pẹlu alaafia ati ọgbọn lati ọdọ Eleduwa.
"Mo si tun gbadura pe ilẹIbadan yoo mọ alaafia pupọ ati idagbasoke lasiko yin. Bẹẹni ilu idunnu ko ni dẹkun ko ni dẹkun lasiko yin."
Mo ṣeleri pe n ko ni ja awọn ọmọ Ibadan kulẹ - Olubadan Ọba Lekan Balogun Ali Okumade keji.
Kini Oba Ibadan tuntun tun so?
Ọba Lekan Balogun Ali fi idunu rẹ han si ojuṣe tuntun ti ilẹ Ibadan gbe le e lori. O ni oun ko si ni ja wọn kulẹ rara.
" Mo dupẹ lwọ gbogbo yin o. Mi o ni ja Ibadan kulẹ. Mi o si ni ja Naijiria kulẹ pẹlu."

Bawo ni irinajo Olubadan tuntun ṣe ri de ori itẹ?
Ọba lalekan Balogun Ali ni Olubadan keji ti yoo wa lati ile Aliiwo nilu Ibadan.
Ipele oye mẹtalelogun lo si la kọja laarin nnkan bii ọgbọn ọdun o le diẹ ko to de ori itẹ gẹgẹbi a ṣe mọ pe mọkanmọkan loye Ilẹ Ibadan.
Ọba Ọlalekan Balogun Ali gori oye lẹyin ti Olubadan kọkanlelogoji Ọba Saliu Adetunji waja nileewosan nla UCH lọjọ keji oṣu kini ọdun 2022 lẹni ọdun mẹtalelaadọrun.
ọdun mẹfa ni olubadan ana lo lori itẹ lyin ti wọn gbpa aṣẹ lee lọwọ ni ọjọ kẹrin oṣu kẹta ọdun 2016.
Lẹyin iku rẹ ni Ọba Lekan Balogun Ali Okumade keji gori oye, amọṣa ọpọ awuyewuye lo waye lori tani yoo joye Olubadan tuntun ki o to de ipo.
- Arẹ́májà kò sí, Olubadan fi tìlù-tìfọn kí àwọn ìjòyè káàbọ̀ lẹ́yìn ọdún méjì
- Wọ́n ti gbé Olubadan wọ káà ilẹ̀, bí ìsìnkú Ọba Adetunji ṣe lọ nìyí
- Makinde buwọ́lu Sẹ́nẹ́tọ̀ Lekan Balogun gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun
- Iléewòsàn UCH kò lè bá Aafin Ibadan parọ́, ẹ dẹ́kún gbígbé ìròyìn òfegè nípa Oba Adetunji tó wàjà- Adeola Oloko
Kini awuyewuye naa?
Awuyewuye naa ko ṣẹyin bi awọn oloye Ibadan kan, ninu eyi ti Ọba Lekan Balogun, to jẹ Ọtun Olubadan nigba naa wa, ṣe gba lati maa de ade yin ti gomina ipinlẹ Ọyọ lasiko naa, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ṣe atunto eto iṣejọba nilu Ibadan.
Amọ, gbogbo awuyewuye yii lo jẹ rodo lọ mumi lẹyin ti Gomina Seyi Makinde, da si ọrọ naa to si ke si gbogbo awọn ti ọrọ kan lati jẹ ki alaafia jba.
Lẹyin eyi ni gomina ipinlẹ Ọyọ kede orukọ Sẹnetọ Lekan Balogun gẹgẹbi Olubadan tuntun loṣu keji ọdun 2022.

Bawo ni eto naa ṣe bẹrẹ lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2022 ni mapo?
Oriṣiriṣi gbajumọ lo peju si ibi ayẹyẹ iwuye Olubadan tuntun, Oba Lekan Balogun.
Gbọngan Mapo nilu Ibadan ni ayẹyẹ naa ti waye.
Lara awọn to wa nibẹ ni igbakeji aarẹ orilẹede yii , Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, igbakeji aarẹ orilẹede yii tẹleri, Atiku Abubakar, Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, Olugbo ilẹ Ugbo, Oba Frederick Obateru , Oluwo ti ilu Iwo.

Ọba Abdulrasheed Akanbi, gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi, gomina ipinlẹ Ogun, Dapọ Abiọdun, igbakeji gominlẹ Ọṣun, Benedict Alain, igbakeji gomina Ondo, Lucky Aiyedatiwa, Etsu Nupe, Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan, Sẹnetọ Rashidi Ladoja, Aarẹ ọna Kankanfo ilẹ Yoruba, Iba Ọtunba Gani Adams, ati awọn eeyan jankanjankan mii.

Bẹrẹ lati Ọja Orita ni agbegbe New garage ni ilu Ibadan, titi de Mọlete, Ọja Ọba, Bẹẹrẹ, ati awọn Oja mii lo ti wa ni titi pa bayii, tori ayẹyẹ ifinijoye Olubadan tuntun.

Eto naa n waye ni gbagede gbọngan nla Mapo.

Jakejado orilẹede Naijiria si ni wọn ti n reti awon jankan jankan to n bọ wa ba awọn eeyan ilu Ibadan se ajọyọ.


Eruku yoo sọ lala nilu Ibadan loni, ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanla oṣu Kẹta, ọdun 2022.

Eyi ko ṣẹyin bi Olubadan tuntun ti ilu Ibadan , Ọba Lekan Balogun, yoo ṣe gbade.

Nibi ayẹyẹ naa ti yoo waye ni gbọngan iṣẹmbaye Mapo to wa ni adugbo Ọja Ọba ni ireti wa pe Gomina Seyi Makinde yoo ti gbe ade ati ọpa aṣẹ fun Olubadan tuntun.
Iyansipo Lekan Balogun waye lẹyin ti Olubadan tẹlẹ, Saliu Adetunji, waja lopin ọdun 2021.

Lekan Balogun ni yoo jẹ Olubadan kejilelogoji.
Awuyewuye ti kọkọ waye lori ẹni yi yoo jẹ Olubadan tuntun eyi to di rẹpẹt laarin awọn to jọ n fa a.
Bo tilẹ jẹ pe Lekan Balogun ni oye naa tọ si, ọpọ lo gbagbọ pe ko yẹ ki wọn o fi jọba, nitori pe oun ati awọn oloye kan nilu Ibadan ti jẹ ọba lasiko iṣejọba gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Oyo, oloogbe Abiola Ajimobi.
Ẹ tẹti leko ni oju opo yii lati mọ bi ayẹyẹ iwuye naa ba ṣe n waye.





















