Ogun Chieftancy Law: Àwọn Oníṣẹ̀ṣe fọnmú pé Ìlànà oyè ọba jíjẹ tíjọba gbé kalẹ̀ kò dún mọ́ àwọn nínú

Oríṣun àwòrán, Ikorodu Traditionalist
Awọn oniṣẹṣe ni ipinlẹ Ogun ti fariga bayii o, wọn si ti paroko ikilọ ranṣẹ si gbogbo awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi.
Bakan naa ni wọn fi ewe ọmọ mọ awọn oriade kan ti wọn pe ni "aletilapa" ọba leti, lati jinna si eto ọba jijẹ ati isinku ọba nipinlẹ naa lati asiko yii lọ.
Bi ẹ ko ba ni gbagbe, ofin oye jijẹ tuntun nipinlẹ Ogun ti wọn gbe kalẹ laipẹ yii, fofin de asa fifi agidi mu awọn ọmọ oye to ba fẹ jẹ ọba lati ṣe etutu lasiko ti wọn ba fẹ jẹ Oba tabi nigba ti wọn ba fẹ sin wọn.
- Wo ewu tó rọ̀ ma kí wọn sin ọba tó ṣètùtù nílànà ẹ̀sìn Krìsítẹ́nì àti Islam
- Ìpínlẹ̀ Ogun fẹ́ fi òfin wọ́gilé ìsìnkú ọba lọ́nà ìṣẹ̀mbáyé
- Egúngún bá òṣèrébìnrin lòpọ̀ nínú eré, àwọn Eléégún yarí
- Ènìyàn lásán ní ọba ilẹ̀ Yoruba tí kò bá ṣe ètùtù, ẹ má tẹ ìṣẹ̀ṣe mọ́lẹ̀ - Elebuibon
- Ẹ wo àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọmọ Yorùbá tó jẹ́ ayaba ní ààfin ilẹ̀ Káàárọ̀ oòjíire
- Wo ìdí tí Ìje ṣe ṣe pàtàkì nílùú Ijare lẹ́yìn tí ọba bá wàjà
- Wo ìlú tí wọ́n ti ń gbé òkú ọba wọn pọ̀n lórí ẹṣin lọ fún ìsìnkú nínú igbó
- Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀
- Oluwo gbóríyìn fún Awujale, Akarigbo fún àyípadà òfin lórí àṣà àtijọ́ fún yíyàn Ọba, ṣíṣe ìsìnkú Ọba
- Ọba tó wàjà àmọ́ tí òkú rẹ̀ gbúdọ̀ jókòó sórí ìtẹ́ ṣáájú ìsìnkú
- Ìyàwó Ẹlẹ́ṣìn ìlú Wukari yarí pé láyé òun ò lè gbà kí ọkọ́ òun wọ igbó mọ́ fún ìsìnkú Ọba
Atunse ilana ofin oye jijẹ naa si lo ti n fa awuyewuye lati bi ọjọ melo kan nipinlẹ Ogun, paapaa lọdọ awọn onisẹse ti ofin naa kan julọ.
Ki lawọn oniṣẹṣe sọ nipa ofin oye jijẹ nipinlẹ Ogun?
Amoṣa, ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe nipinlẹ Ogun ni inu awọn ko dun si ilana oye jijẹ tuntun naa.
Wọn ni awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi n ṣi ofin oye jijẹ ni ipinlẹ naa tumọ si bo ṣe wu wọn.
Nigba ti wọn n ba awọn akọroyin sọrọ nilu Ṣagamu, awọn oniṣẹṣe labẹ aṣia ẹgbẹ Oniṣẹṣe Parapọ lorilẹede Naijiria woye pe, ofin oye jijẹ naa, ninu ẹsẹ kini de ikarun un abala karundinlọgọta faaye silẹ lati sin ọba to ba waja ni ilana iṣẹṣe.
Agba Oye Ifaṣọla Ọpẹodu, to sọrọ lorukọ ẹgbẹ awọn oniṣẹṣe naa woye pe, abala ofin ti a n sọrọ rẹ yii to fun awọn mọlẹbi ọba to ba waja laaye lati wa nibi isinku rẹ, yoo da awuyewuye silẹ laarin awọn mọlẹbi naa atawọn ti iṣẹṣe faye gba lati ṣeto ikẹyin fun ọba to ba waja.
Ki ni ofin oye jijẹ ipinlẹ ogun sọ?
Ni ọdun 2021 lawọn aṣofin ipinlẹ Ogun gbe ofin yii kalẹ lati bomi pa ọpọlọpọ aawọ to n waye lori ifinijoye ati isinku awọn Oba nipinlẹ naa.
Ni paapaajulọ, aawọ to maa n waye laarin awọn afọbajẹ, awọn ẹlẹṣin miran atawọn mọlẹbi ọba.
Ohun ti ofin naa si gbe lori julọ naa ni Ilana oye jíjẹ ati isinku ọba ni ipinlẹ naa.
Abala kẹjọ ofin naa laa kalẹ pe ko si ẹnikẹni to gbọdọ fi tipa mu ọba tabi oloye kankan wọ ẹgbẹ imulẹ tabi ẹgbẹkẹgbẹ yoo wu ti ko ba fẹ.
Ofin naa laa kalẹ pe, ẹnikẹni to ba tapa si eyi yoo fi ẹwọn ọdun meji gbara laisi anfani owo itanran.
Bakan naa ni ofin yii tun laa kalẹ pe "ẹnikẹni ko gbọdọ di awọn ẹbi ọba to ba waja lọwọ sinsin oku wọn lọna to ba wu wọn."
Ẹwọn oṣu mejila ṣangiliti ni ẹni to ba tapa si ofin yii yoo fi gbara.

Ohun tó bá kàn ìlú Ibadan, kàn mí - Gómìnà Ganduje

Oríṣun àwòrán, insideoyo.com
Awọn eekan ilu lorisirisi lo ti n kan si Olubadan ilu Ibadan, Oba Lekan Balogun, Okunmade Keji.
Ninu wọn ni Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje ati Emir Ilu Kano, Aminu Ado Bayero, ti wọn wa se abẹwo si aafin Olubadan lọjọ Abamẹta.
Lọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanla osu Kẹta ọdun yii ni ayẹyẹ ifilọlẹ Olubadan waye, nibi ti Gomina Seyi Makinde ti gbe ọpa asẹ le ori ade naa lọwọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo ṣèlérí pé n kò ní já Ibadan àti Nàìjíríà kulẹ̀- Olúbàdàn tuntun, Ọba Lekan Balogun Ali Okùmádé kejì
- Tẹ̀gbọ́n tàbúrò jí ọmọ ará àdúgbò gbé láti gbowó, àmọ́ wọn fún ní òògùn eku jẹ
- Wo àwọn nǹkan tó le fa lupus - àìsàn tó ń bá Kemi Afolabi fínra
- "Èèdì àti ogun ayé ni awọn èèyàn n rò pé ó mú mi bí ìbejì ní ìgbà mẹ́fà"
- Ọjọ́ Ajé la bẹ̀rẹ̀ ìpè fún ìdásílẹ̀ Yoruba Nation padà - Akintoye
- Malami pahùndà lórí ọ̀rọ̀ Kyari, ó ní kò jẹbi ẹ̀sùn kíkówó pamọ́
- Ìjàmbá ọkọ̀ tún gbẹ̀mí ènìyàn mẹ́tàlá ní òpópónà márosẹ̀ Ilorin sí Ogbomoso
Lasiko abẹwo naa, Gomina Abdullahi Ganduje sọ fun Olubadan pe Ilu Ibadan jẹ bi ile keji fawọn eeyan ilu Kano, ti Kano naa si jẹ bi ile keji fun awọn ọmọ Ibadan to ba wa nibẹ.
Gomina Ganduje, ti ọmọ rẹ obinrin fẹ ọmọ Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri, Abiola Ajimobi, fi ifarajin rẹ han lati jẹ ki ibasepọ laarin Kano ati Ibadan tunbọ gun rege si.
Gẹgẹ bo se wi, ''nnkan to ba de ba Ibadan, deba emi naa ni.''
Olubadan to gba Gomina ati Emir lalejo woye ibasepọ toun ni pẹlu Kano.
O ni gbogbo igba ti wọn ba darukọ Kano, nise lọkan oun maa n balẹ.
Gomina Ganduje tẹsiwaju pe ati awọn lọbalọba Kano ati ijọba ipinlẹ naa ni inu wọn dun si bi Oba Balogun se gun ori oye awọn baba rẹ.
Olubadan, jẹ ki ibasepọ Ibadan si Kano gun rege si - Emir Kano
Ninu ọrọ tirẹ, Emir Kano, Alhaji Aminu Ado Bayero sọ fun Olubadan pe ki o jẹ ki ibasepọ laarin awọn gbajumọ ilu mejeeji yii tunbọ gun rege si.
O ni ''nipa inawọ si ara ẹni laarin awa mejeeji ni a se le fẹsẹ Naijiria, ti irẹpọ yoo wa fun gbogbo wa lelẹ.
Naijira ti yoo jẹ ile fun gbogbo wa nibikibi taa ba ti ba ara wa''
Awọn to tẹle awọn alejo yii wa si aafin Olubadan ni akọwe agba ijọba ipinlẹ Kwara tẹlẹ ri, Alhaji Olalekan Alli.
Bakan naa ni olubadamọran pataki tẹlẹ feto iroyin lasiko isejọba Gomina Ajimobi, Bolaji Tunji ati Idris Ajimobi, to jẹ ana si Gomina Ganduje.

Ṣé o ti gbọ́ nípa àwọn ojú ọnà tí wọ̀n fẹ ti pa nítorí ayẹyẹ iwuye Olubadan ni ola?
Ọba Lekan Balogun ni ọba ikejilelogoji ti yoo jẹ nilẹ Ibadan.

Oríṣun àwòrán, @Olubadan
Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede awọn oju ọna kan ti yoo wa ni titi pa lasiko ayẹyẹ iwuye Olubadan ilu Ibadan, Oloye Lekan Balogun ti yoo gori apere awon baba nla rẹ̀.
Lọjọ Eti lawọn oju ọna naa yoo wa ni titipa gẹgẹ bi wọn se sọ ninu atẹjade kan.
Ileesẹ to n risi eto lilọ bibọ ọkọ loju popo lo si buwọlu atẹjade taa n wi yi.
- 'Gbogbo ẹ̀yà ara Bamise Ayanwole ló pé nígbà tí mo rí òkú rẹ̀'
- A ti rí ilé ti à ń lọ lọ́ọ̀kán báyìí díẹ̀ ló kù - Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye lásíkò àjọyọ̀ ìtúsílẹ̀ Sunday Igboho
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
- Timothy Adegoke: Ìyàwó Timothy Adegoke jẹ́rìí nípa ọkọ rẹ̀ nílé ẹjọ́, gbọ́ nípa ìjà tó jà fún ọkọ̀ rẹ̀
- Ademola Adeleke ní igun kíni PDP ní Osogbo fà kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ oyè láti díje dupò gómìnà Osun
- Ọkùnrin àkọ́kọ́ tó ṣàṣeyọrí lílo ọkàn ẹlẹ́dẹ̀ láti mi ti padà kú o!
Awon adugbo wo ni ọ̀rọ̀ kan?
Gẹgẹ bi wọn se sọ, wọn yoo dari ọkọ si ibomiran lawọn aaye kọọkan ti awọn eeyan le gba de Oke Mapo nibi ti iwuye Oba Lekan Balogun yoo ti waye.
Bẹrẹ lati aago mejila oru oni tii se ọjọ Kẹwaa, ni wọn yoo bẹrẹ si ni ti awọn oju ọna wọnyi ti wọn yoo si si wọn pada ni ọjọ Kejila, osu Kẹ́ta, ọdun ti a wa yii.
Ninu awọn ọna ti wọn yoo ti pa lati ri:
1. Ikorita Beere lọ si Gbongan Mapo Hall
2 Ikorita Born Photo lọ si ọna Oja Oba
3.Ikorita Idi-Arere lọ si Oja Oba
4. Ikorita Oritamerin lọ si Gbongan Mapo Hall.
Igbese mii wo lo wa nilẹ̀?
Amọ sa, awọn alasẹ ileesẹ to n risi ọrọ oju ọna sọ pe awọn ti pese oju ọna miran tawọn eeyan le gba dipo eyi ti wọn yoo ti pa.
Eleyi yoo mu irọrun ba awọn awakọ to ba fẹ gba oju ọna taa n wi yi.
Akọkọ ni:Ọna miran ti wọn le gba dipo eyi ti wọn gbegi di ni : Beere Junction to jẹ ọna Oranyan , Beere-Oke, Dada ati Agbeni-Ogunpa
Elẹẹkeji ni Oju ọna Gẹgẹ to lọ si Oke Ado ati ọna Idi-Arere to ja si Moleto dipo ọna Born-Photos ti wọn gbegi di.
Ikẹta ni ọna Agbongbon-Kobomoje-Eleta-Oranyan ti wọn la kalẹ dipo ọna ti Idi-Arere ti wọn ti pa.
Lakotan, wọn tun sọ pe na Beere-Oje,Agbeni-Okunpa yoo jẹ ọna abayọ si ti Itamẹrin ti wọn yoo ti pa.
























