Wo ìdí tí Ìje ṣe ṣe pàtàkì nílùú Ijare lẹ́yìn tí ọba bá wàjà

Sapetu ilu Ijarẹ, nipinlẹ Ondo, Oloye Wemimo Olaniran, ti só pe oun ni igbagbọ pe ilu naa yoo yan ẹni to tọ lati rọpo Ọba Adegbamigbe Oluwagbemigun to waja lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, odun 2021.
Nibi eto isinku Ọba Oluwagbemigun ti a mọ si èje, Wemimo sọ fun BBC Yoruba pe oun ni aridaju pe ilu Ijarẹ yoo yan ẹni to tọ loye, amọ oun ko nii sọ akoko ti yoo jẹ.
Wemimo to jẹ igbakeji ọba ilu ijarẹ juwe Ìje gẹgẹ bi ọkan lara awọn aṣa to di dandan ki wọn ṣe lati dagbere fun Ọba to ba papoda, ti awọn araalu si lee yọju si.
Ije n tumọ si ọjọ keje lẹyin ti ori ade naa dagbere faye, to si jẹ pe dandan ni ki wọn o ṣe e fun ọba to ba waja.
Bakannaa ni Ọdunwo ilu Ijare, Oloye Idowu Adebumiiti rawọ ẹbẹ si awọn olugbe ilu naa lati kun fun adura, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọn ti n dari ilu naa lakoko yii.
Ẹwẹ, Èje ọun to waye laafin Olujarẹ ni tọmọde, tagba ati awọn isọri ọjọ-ori loriṣiriṣi bawọn peju si.
Awọn aworo naa ko gbẹyin nibi wọn ṣe ṣe oniruuru etutu, to fimọ ijo latọdọ awọn onijo ibilẹ, awọn ọdẹ, ati lilu oniruuru ilu bii alupororo, àgbá, ilu ode, ilu awo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lati le sami si ọjọ naa daadaa, karakata ni wọn fofinde lawọn aaye itaja, ibusọ ati awọn ọja kaari ilu.
Ọba Oluwagbemigun to jẹ ọba kọkandilogun nilu Ijare lo lọ darapọ mawọn baba nla rẹ lẹyin ọdun mẹẹdọgbọn lori aleefa ni ọmọ ọdun mẹtalelọgọrin.0
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
Ayẹyẹ ìjáde lẹ́yìn ìsìnkú Olujare ti ilú Ijare ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu l'Ondo
Ilu, ijo ati orin ni awọn araalu Ijarẹ, nipinlẹ Ondo fi n ṣe ayẹyẹ isinku ọba wọn, Ọba Adebamigbe Oluwagbemigun, Kokotiri kẹta to waja lọsẹ to kọja.
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 yii, ni Kabiesi naa waja, lẹni ọdun mẹtalelọgọrin.
Ọdun mẹẹdọgbọn si ni o lo lori itẹ awọn baba rẹ gẹgẹ bi ọba.
Ayẹyẹ to si n waye lonii ni wọn n pe ni Ìje, to n tumọ si ọjọ keje lẹyin ti ori ade naa dagbere faye, to si jẹ pe dandan ni ki wọn o ṣe e fun ọba to ba waja.

Lara awọn ohun ti wọn la kalẹ fun ayẹyẹ isinku naa ni oniruru ijo ibilẹ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ.
Bẹẹ naa ni awọn ọde ilu yoo maa yẹ ori ade naa si ni bi wọn yoo ṣe maa lu awọn ilu kan bii alupoporo, àgbá, ìlù ode, ìlù awo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lati sami si ayẹyẹ isinku naa, ko ni si karakata niluu Ijare, gbogbo awọn ṣọọbu ati ile itaja yoo si wa ni titi pa.
Lara awọn to ti wa ni aafin Olujare bayii ni ogunlọgọ ọmọ ilu naa nile loko, to fi mọ awọn ẹbi ati ọrẹ oloogbe ọhun.
- Mọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́wàá tí ò lè fi kó sí páńpẹ́ LASTMA ní Eko àti ìjìyà tó tẹ̀lẹ̀ e
- Buhari, rọra yá owó kí Nàìjíríà má ba á kú sóko gbèsè o- Atiku Abubakar
- Ìtàn Ìjàpá àti ọbọ ni ìjọba àpapọ̀, àwọn agbófinró ń sọ nípa Igboho - Wole Soyinka
- Àwọn olùgbé Akinyele fí ẹ̀sùn ilẹ̀ gbígbà kan ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo, ìjọba Makinde ti fèsì padà
- Wo iye ìgbà tí wọ́n ti jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Nàìjíiríà













