Sunday Igboho: Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka ní kí Benin Republic ó fi Sunday Igboho sílẹ̀ kó máa bá ìrìnàjò rẹ̀ lọ

Wole Soyinka

Oríṣun àwòrán, other

Ogbontagi onkọwe, Ọjọgbọn Wọle Soyinka ti ke si awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Benini Republic pe ki wọn tu eekan aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho silẹ.

Ọjọgbọn Soyinka ṣalaye nibi ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin ni ọjọ Ẹti.

Soyinka ni ẹṣẹ kan ti ijọba Naijiria lee ri ka si Sunday Igboho lẹsẹ ni pe o n ja fun awọn eeyan rẹ lati dojukọ wahala awọn darandaran fulani kan to ti sọ ara wọn di ariigbọdọ wi ikun imu baale lori awọn eeyan rẹ ni ipinlẹ Ọyọ.

Ọjọgbọn Soyinka ni oun ko gbagbọ pe Igboho ṣẹ ẹṣẹ kankan ju wi pe o sọrọsoke lori iwa aitọ tawọn kan n hu si awọn eeyan rẹ. Ọjọgbọn naa ṣalaye pe ni toun o, ọna alaafia ni Igboho gba pe ipe rẹ ti ẹnikẹni ko si lee tọka si pe o jẹ iwa ọdaran rara.

Àkọlé fídíò, Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

Oluwole ọmọ Soyinka ni: "Nigba ti ijọba atawọn ileeṣẹ alaabo kọlu ile Igboho lọganjọ oru, ti wọn pa eeyan rẹ meji ti wọn si tun n pariwo laisi iwe aṣẹ ayẹwo lori ile rẹ pe awọn ba ohun ija oloro nibẹ...ta ni yoo gba itan ijapa ati ọbọ bẹẹ gbọ?"

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Bakan naa lo tun bi awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Benin Republic leere idi ti wọn fi n fi Igboho si atimọle dipo ki wọn fi silẹ ko maa ba irinajo rẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Baba Iyetade ni ko si ohun to tako iwe ofin orilẹede Naijiria ninu ki eeyan pe fun idasilẹ orilẹede niwọn igba to jẹ pe ọna alaafia lo gba n ṣe e labẹ ofin.

Àkọlé fídíò, Test your Yoruba language skill: Wá ká jọ sọ Yorùbá...