School Kidnap in Nigeria: Wo iye ìgbà tí wọ́n ti jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Nàìjíiríà

ijinigbe

Oríṣun àwòrán, Others

Iye igba ti wọ́n ti ji awọ́n ọmọ gbe nile ẹ̀kọ́ Naijiria Osu kejila 2020 si isinyi

Kayan-Maradun, Zamfara

Image copyright by Getty Images

Awọn agbebọn to wa lori ọkada ati ọkọ akẹru Pick-up ti ji o kere tan, aadọrin akẹkọọ ile ẹkọ Government Day Secondary School, Kayan-Maradun nipinlẹ́ Zamfara gbe lọ.

Akẹkọọbinrin marun lo bọ kuro lọwọ awọn ajinigbe lọjọ keji osu Kẹsan-an, ti wọn si ti da wọn pada sọdọ awọn obi wọn bi o tilẹ jẹ pe ọlọpaa ni wọ̀n gba wọn la ni.

Ni ojo ketala, osu kesan an ni won tu awon akekoo to ku sile

Kaduna, Kaduna

Image copyright by Getty Images

Àwọn agbébọn kọlu ilé-ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ àwọn ọmoogun ni ìhà aríwá-ìwọ̀òòrun ìlú Kaduna, wọ́n pa àwọn ọmọogun méjì ti wọ́n sì jí òmíràn gbé

Faskari, Katsina

Image copyright by BBC

Wọ́n jí àkẹ́kọ̀ọ́ mẹ́jọ àti olùkọ́ kan gbé ní ilé kẹ́wú kan ní abúlé Sakkai tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Faskari, ìpínlẹ̀ Katsina.

Àwọn aláṣe abúlé ọ̀hún sọ pé nǹkan bíi ago mẹ́sàn án alẹ́ ni àwọn agbébọn kọlu ilé kéwú náà.

Bakura, Zamfara

Image copyright by Facebook/College of Agriculture and Animal Health

Àwọn agbébọn kọlu ilé ìwé gíga ẹ̀kọ́ ètò ọ̀gbìn kan ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakura tí wọ́n sì jí akẹ́kọ̀ àti òṣìṣẹ́ mọ́kàndínlógún lọ.

Wọ́n jí akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, òṣìṣẹ́ kan, ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ méjì. Wọ́n pa olùṣọ́ mẹ́rin àti ọlapàá kan.

Olórí ilé ẹ̀kọ́ náà, Habibu Mainasara sọ pé àwọn ajínigbé náà bèrè àádọ́jọ (150) mílíọ́nù náírà gẹ́gẹ́ bíi owó ìtúsílẹ̀.

Ni ọjọ kẹ́tadinlọgbọn oṣu kẹjọ, awọn Ọlọpaa sọ pe mejidinlogun ninu awọn ti wọn jigbe lo ti gba itusilẹ “lai san nkankan”. Bakan naa ko ye ẹnikẹni ohun to ṣẹlẹ si awọn to ku nigbekun.

Zaria, Kaduna

Image copyright by BBC

Wọ́n jí akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlélọ́gọ́fà (121) gbé láti ilé ẹ̀kọ́ girama Bethel Baptist Secondary School, ní Kaduna.

Lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù keje, ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà, Reverend John Hayab sọ fún BBC pé wọ́n ti dá akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn ìdúnadúrà láàrin àwọn ajínigbé àti àwọn òbí àwọn tón jí gbé. Kò sọ ní pàtó nípa bọ́yá wọ́n san owó ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó sọ pé “ó ṣeéṣe.”

Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹjọ, ọmọ ile ẹkọ mejilelọgbọn ni wọn tu silẹ kuro ni'gbekun. Obi ọkan lara wọn sọ fun BBC pe lẹyin ti wọn san owo itusilẹ ni wọn to da wọn silẹ.

Yauri, Kebbi

Image copyright by FGC YAURI

Àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ kan gbé láti ilé ẹ̀kọ̀ọ́ girama ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Yauri. A kò mọ iye èèyàn tí wọ́n jí gbé, ṣùgbọ́n àwọn alakóso sọ ọgbọ̀n akẹ́kọ̀ọ́ ló móríbọ́.

Tegina, Niger

Image copyright by BBC

Àwọn agbébọn ti jí àwọn ọmọ ilée kéwú mẹ́rìndílógóje (136) gbé ní ìlú Tegina. Ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ló ń lọ sí ilée kéwú náà tí wan jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fàá (6) sí méjìdínlógún (18) .

Lọ́jọ́ kọ̀ọ́kànlélọ́gbọ̀n oṣù kaàrùn ún, àwọn aláṣẹ ìpínlẹ̀ náà sọ pé wọ́n tú àwọn ọmọ mọ́kànlá sílẹ̀ nítorí pé wan kéré púpọ̀ láti lè rìn.

Ni ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ni wọn fi o le ni ọgọrun un akẹkọo silẹ lẹyin ti Obi san $150,000 owọ dọla fún awọn ajinigbe

Makurdi, Benue

Image copyright by BBC

Wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì ètò ọ̀gbìn ti ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Makurdi gbé lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹrin. Wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ́kàndínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin.

Kasarami, Kaduna

Image copyright by Getty Images

Wọ́n jí ogún akẹ́kọ̀ọ́ gbé àti àwọn òṣìṣẹ́ mẹ́ta gbé ní fásitì Greenfield tó wà ní agbègbè Chikun ní ìpínlẹ̀ Kaduna. Agbẹnusọ ọlọ́pàá sọ pé wọ́n pa òṣìṣẹ́ kan

Wọ́n rí òkú akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta lọ́jọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹrin, wọ́n tún rí òkúu méjì nínú wọn lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹrin, èyí tó sọ iye akẹ́kọ̀ọ́ tó kú di mẹ́fà. Méjìdínlógún ṣì wà ní àhámọ́.

Wọ́n dá èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sílẹ̀ lọ́jọ́ kọọ̀kàndínlógún oṣù káàrù ún.

Birnin Gwari, Kaduna

Image copyright by Getty Images

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́rin, lọ́jọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gún oṣù kẹta, ìjínigbé kejì ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ̀ọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ kan ní abúle Rema tó wà ní agbègbè Birnin Gwarí ní ìpínlẹ̀ kaduna.

Wọ́n kọ́kọ́ rò pé wọ́n jí àwọn ọmọ gbé ni, ṣùgbọ́n àwọn alákósọ padà sọ pé kọ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé lẹ́yìn tí wọ́n ka àwọ̀n akẹ́kọ̀a tan. Ṣùgbọ́n wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀a mẹ́ta gbé, wọn kì sì tíì tú wan silẹ̀.

Afaka, Kaduna

Image copyright by Getty Images

Wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàndínlógójì (39) gbé ní ilé ẹ̀kọ́ gíga iṣẹ́ oko lọ́nà ìgbà ló dé ní ìpínlẹ̀ Kaduna tó wà ní iwọ́-oòrùn àríwá Nàìjíríà.

Àwọn agbésùmọ̀mí ya wọ ilé ẹ̀kọ́ náà tí wọ́n sì gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ọ̀pọ̀ wọn jẹ́ obìnrin lọ. Wọ́n ti tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀, díẹ̀díẹ̀.

Wọ́n dá máàrùn ún sílẹ̀ lọ́jọ́ kaàrún oṣù kẹrin, márùn ún lọ́jọ́ kẹjọ oṣù kẹrin, wọ́n sì dá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n náà sílẹ̀ lọ́jọ́ kaàrùn ún oṣù kaàrùn ún.

Jangebe, Zamfara

Image copyright by Getty Images

Wọ́n jí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mọ́kàndínlọ́gọ́rinlénígba (279) láti ilé ẹ̀kọ̀ọ́ girama ti obìrin ìlú Jangebe ní ìpínlẹ̀ Zamfara. Lẹ́yìn tí wọ́n lo ọjọ́ mẹ́rin ní àhámọ́, wọ́n dá gbogbo mọ́kàndínlọ́gọ́rinlénígba náà sílẹ̀ lajọ́ kejì oṣù kẹta.

Kagara, Niger

Image copyright by Getty Images

Wọ́n jí akẹ́kọ̀ọ́, òṣìṣẹ́ àti àwọn ẹbí wọn méjìlélógójì láti ilé ìwé girama Kagara ní ìpínlẹ̀ Niger. Lẹ́yìn ọjọ́ mọ́kànlá , wọ́n tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sílẹ̀ lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì.

Kò sí àmọ̀dájú pé wọ́n san owó ìtúsílẹ̀ láti tú wọn sílẹ̀.

Kankara, Katsina

Image copyright by Getty Images

Ní nǹkan bíi ago mẹ́sàn án ààbọ̀ alẹ́ wọ́n gbúrò ìbọn nínú ilé ẹ̀kọ̀a girama Kankara, ní ìpínlẹ̀ Katsina. Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn sọ pé àwọn agbébọn ya wọ inú yàrá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méje tí wan sì kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́kùnrin mẹ́rìnlélógójìlélọ́ọ̀ọ́dúnrún (344) lọ.

Wọ́n fi àwọn ọmọ náà sí àhàmọ́ fún ọjọ́ mẹ́fà títí di ìgbà tí wan dá wọn sílẹ̀ lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejìlá ọdún 2020.

Opọ̀ igba ni wọ́n ti ji akekọ́ọ́ gbe ni orilé-ede Naijiria.

Ipaniyan niluu Jos

Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau gbé lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé lọjọ Isegun

Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau ti tún ṣe òfin kóníléógbélé oní láyípo ni ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Jos, ìpínlẹ̀ Plateau.

Adari ìbánisọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ tó n lọ fún gómìnà ipínlẹ̀ Plateau, Simon Lalong, Makut Macham lo kéde nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta l'Ọjọ́rú.

Òfin kóníléógbélé náà wáyé nítórí ìkólu tó ṣẹlẹ̀ ní Yelwa Zangam, abúlé kan ni ẹkùn Zangam ni ìpínlẹ̀ Plateau.

Gẹ́gẹ́ bí Gómínà ṣe sọ òfin kóníléógbélé náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ òni ọjọ́ karùndinlọ́gbọ̀n, oṣù kẹjọ, ọdún yìí títí di ìgbà tí ẹnikẹ́ni ko tíì mọ̀.

"Igbésẹ̀ oníwàrànṣesà yìí pọndandan nítorí wàhálà tó n dúkoko mọ ìwàláàyè àwọn ara ìlú ni ìjọba ìbílẹ̀, ó sì pọndandan kí a mójútó kí nǹkan to bàjẹ́ jìnà."

" Èyí yóò ràn àwọn agbófinro lọ́wọ́ pẹ̀lú láti ṣe iṣẹ́ wọn bi ó ti tọ́ àti bi ó ti yẹ, àti láti ṣe àwárí àwọn tó ṣe iṣẹ́ aburú náà."

"Gómínà tí wá rọ àwọn ará ìlú pàápàá jùlọ àwọn ará àríwà ni Jos láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba nípa tílèlé òfin kóníléógbélé náà ti yóò bẹ̀rl ni aago mẹ́rin ìrọ̀lé òní."

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Ìjọba ti pọn ni dandan fun awọn agbófinro pe kí wọ́n fi ọwọ́ òfin mú ẹnikẹni tí ó ba ki etí ọ̀gbọ̀in si àṣẹ náà."

Gómìnà Lalong tun fi kun pé, òfin kónílé o gbélé alaago mẹ́fà alẹ́ sí ti ìdájí náà wà ni ìhà Gúúsù Jos náà títí di àsìkò ti wan kò mtí mọ̀.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn tó n ṣe iṣẹ́ bi nọ́ọ̀sì, dókítà, oníròyìn, àwọn panápaná àti awọn eletò ààbò nikan ni ofin fi aaye gbà láti jáde.

Sùgbọ́n kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí rii dájú pé, wọ́n mú ìwé ìdánimọ̀ wọn dání.

" Lẹ́ẹ̀kan si gómìnà bá àwọn to pàdánù ẹbi wọn láti fi ọ̀kan bálaẹ̀ kí wọ́n sì gba ìjọba láàyè láti mójú tó ọ̀rọ̀ náà kí àwọn oníṣẹ́ ibi náà má baa fi ìyà jẹwọ́n gbé."

Jos Crisis: Ìjọba ìpińlẹ̀ Plateau ti ṣofin kóníléógbéléní Àríwá Jos

Oríṣun àwòrán, Lalong

Jos killings: Àwọn jàndùkú agbébọn tún yìnbọn pa èèyàn tó lé ní 30 nílùú Jos

Iroyin yajoyayo to n tẹ wa lọwọ lati ipinlẹ Plateau sọ pe awọn janduku agbebọn tun ti fi ẹmi eeyanto le lọgbọn ṣofo lagbegbe Yelwan Zangam ni ijọba ibilẹ ariwa ilu Jos.

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

Ti ẹ ko ba gbagbe, bi ọsẹ meji sẹyin lawọn agbebọn ṣekupa arinrinajo mẹẹdọgbọn to n lọ si Ondo niluu Jos.

Amọ iroyin sọ pe bi ago mẹsan an ku iṣẹju mẹẹdogun ni alẹ ọjọ Iṣẹgun lawọn janduku yii yabo awujọ Yelwa Zangam nibi ti wọn ṣọṣẹ di oru mọju Ọjọru.

Ọba awọn ẹya Anaguta to wa lagbegbe tawọn agbebọn kọlu yii, Ujah Johnson Jauro fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn akọroyin.

Kọunsilọ wọọdu Ahwol lawujọ naa, Yusuf Ali ṣalaye pe awọn janduku naa dana sun awọn kan laaye.

Aṣofin ni afara to so awujọ naa pọ mọ awọn agbegbe mii lawọn janduku ọhun kọkọ bajẹ ko le nira fawọn ẹṣọ eleto abo lati wa doola awọn eeyan.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Kọunsilọ naa ni bawọn janduku yii ti de awujọ naa ni wọn dabọn bolẹ, bakan naa lo sọ pe wọn tun dana sun ọpọ ile.

O ni ọpọ oku awọn eeyan ni wọn ti ko lọ si ile igboku si nigba ti ọpọ eeyan si fara pa yanayana.

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau ko tii sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun.