Plateau Killing: Ẹgbẹ̀ CAN àti NSCIA ké gbàjarè bi wàhálà se n rúgbó

Plateau Killing

Oríṣun àwòrán, Ngong Ignatius

Akẹkọọbinrin fasiti Jos, UNIJOS, ni awọn janduku tun pa lasiko to n lọ si ile ijọsin lọjọ Aiku lẹyin ti ijọba ṣe ofin konileogbele ni ijoba ibilẹ Jos North, Jos South ati Bassa.

Iroyin sọ pe wọn tun pa awọn miiran, ti ọpọ si tun farapa ni awọn orisirisi, to fi mọ Farin-Gada, ni opopona Bauchi ati agbegbe Terminus.

Lẹyin eyi ni gbogbo agbegbe ọja Terminus da paroparo lọsan ọjọ Aiku naa.

Iroyin sọ pe ọmọ akẹkọọ UNIJOS ti wọn paa naa n lọ si ile ijọsin laaro ọjọ Aiku nigba ti awọn janduku paa ni agbegbe Ring Road, niluu Jos.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Saaju ni Gomina Simon Lalong ti kọkọ pe fun konileogbele ni ijọba ibilẹ mẹta lọjọ Satide nitori wahala to waye ni opopona Rukuba ni ijọba ibilẹ Jos North.

Ẹwẹ, aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Jos, Joshua Danladi fidi rẹ mulẹ pe wọn pa ọkan ninu awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa lọjọ Aiku.

Bakan naa ni atẹjade kan lati ọwọ alaga agbarijọpọ awon akẹkọọ to jẹ Kristẹni ni ipinlẹ Plateau, Jeremiah Dalong naa tun fi idi ọrọ naa mulẹ pe awọn padanu ọkan lara awọn, ti awọn miiran si farapa.

O ni awon n kepe ijọba ipinlẹ naa lati gbe igbesẹ to yẹ lati ri pe awọn akẹkọọ ni Plateau ko fara kaasa ninu iṣẹlẹ yii ki wọn si ri aabo to yẹ, ati itọju to peye fun awon to wa nile iwosan lọwọ.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Ọ̀gá agba ọlọpaa ni Naijiria ni Usman Baba ti ran awon ikọ iwadii lọ si ipinlẹ ọhun lati ṣe iwadii to peye lori iku awon eniyan to le ni ogun ti wọn funrasi pe awọn ọdọ Irigwe lo ṣiṣẹ ibi ọhun.

Oniruuru ẹka ọlọpaa ni awọn ikọ ti wọn ran lọ yii ti n ṣiṣẹ lati ri daju pe iwadii to ye kooro jade.

Eyi jẹyọ ninu atejade ti agbẹnusọ ọlọpaa ni Naijiria, Frank Mba fọwọsi to si nibi to ti sọ pe awọn ti mu awọn afurasi ogun, ti wọn si doola awọn eniyan mẹtalelọgbọn.

Ninu atẹjade ile iṣẹ ọmọ ogun ti ikọ Operation Safe Haven, Ishaku Takwa fi sita lọjọ Aiku bakan naa, o ni pe awọn soja ti yi igboro Jos ka lati mu ki gbogbo nnkan bọ sipo.

Ẹgbẹ to n ri si ọrọ awọn Musulumi ni Naijiria, NSCIA, ti pe fun alafia.

Aarẹ gbogboogbo fun ẹgbẹ naa, Sultan ti Sokoto, Alhaji Muhammad Sa'ad Abubakar bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa, to si pe ni ipakupa awọn Musulumi to n bọ jẹjẹ wọn lati bi ipade kan ni Bauch ti wọn si n lọ si ipinlẹ Ondo.

Ẹwẹ, ẹgbẹ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN, eka ti Plateau pẹlu naa ti ke gbajare pe awon ko faramọ ipaniyan to waye ni Jos.

Ninu atejade ti CAN fi sita lọjọ Aiku ti alaga egbe naa, Polycarp Lubo fi ọwọ si, ẹgbẹ naa ke si ile isẹ ọlọpaa ati awọn eleto abo to ku lati se awari ojulowo awon to ṣe iṣẹ ibi naa.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Femi Falani ní ẹjọ́ Igboho ní Cotonou ń kọ́ àwọn amòfin Nàíjíríà ní ẹ̀kọ́