Afghan Conflict: Taliban ló n ṣàkóso àwọn ìlú nla àyàfi Kabul

Ikọ Taliban ti n fẹrẹ gba akoso orilẹede Afganistan tan, to si jẹ pe olu ilu ilẹ naa, Kabul nikan ni ilu nla to ku sabẹ akoso ijọba nikan.Lọjọ Aiku, awọn agbebọn naa gba akoso ilu Jalalabad, to wa ni ẹkun ariwa ilẹ naa lai ja fun rara.

Awọn akọroyin wa to wa ni olu ilu naa ni se ni awọn eeyan to fẹ sa kuro ni orilẹede naa, to lọ gbọọrọ si ori ila ni papakọ ofurufu, ti awọn ibudo itaja ati ọọfisi ijọba si da paro paro.

Ikọ Taliban ti wa pasẹ fawọn jagunjagun rẹ lati duro si abawọle olu ilu orilẹede naa, ti wọn si n rọ awọn araalu lati duro si orilẹede wọn.

Ijiroro pẹ́lu awọn lọgalọga ninu ijọba aarẹ Ashraf Ghani lori gbigbe agbara silẹ lọna alaafia si n lọ lọwọ, Atẹjade kan lo sọ bẹẹ.

Ninu awọn isẹlẹ miran:

Ọpọlọpọ ọmọ orilẹ-ede Afganistan to sa kuro nibi ti ija ti n waye ti n ṣe atipo ni Kabul

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọpọlọpọ ọmọ orilẹ-ede Afganistan to sa kuro nibi ti ija ti n waye ti n ṣe atipo ni Kabul

Ilu to kẹyin lẹkun ariwa, Mazar-i-Sharif, naa bọ sọwọ awọn agbebọn lai si ija pupọ.

Ilẹ Amẹrika ti n ko awọn osisẹ rẹ kuro ni ileesẹ asoju rẹ to wa ni Kabul - ta si ri awọn eeyan to n wọ baalu ofurufu ologun ni papakọ ofurufu nibi ti ikọ ologun Amẹrika to le ni ẹgbẹrun marun wa, lati se atilẹyin fun igbesẹ naa.

Aarẹ Joe Biden ti kede ipinnu rẹ lati ko ikọ ologun kuro ni orilẹede naa, pẹlu awijare pe oun ko ni idi kan pato ti ikọ ogun Amẹrika yoo fi wa ni orilẹede to tun fẹ bẹrẹ ogun abẹle miran.

Ki lo sẹlẹ ni Jalalabad?

Iroyin ni laarọ ọjọ Aiku ni ikọ Taliban gba akoso ilu naa, tii se olu ilu ẹkun Nangarhar lai yin ọta ibn kan soso.

"Ko si ija kankan to n waye lọwọ nilu Jalalabad nitori gomina ti jọwọ ilu naa fun ikọ Taliban." Ara orilẹede Afganistan kan lo sọ fun ileesẹ iroyin Reuters bẹẹ.

"Gbigba awọn ikọ Taliban laaye nikan ni ọna kan soso lati doola ẹmi awọn araalu."

Akojọpọ awọn agbegbe to ti bọ sọwọ ikọ ọlọtẹ Taliban
Àkọlé àwòrán, Akojọpọ awọn agbegbe to ti bọ sọwọ ikọ ọlọtẹ Taliban

Akọroyin kan, Tariq Ghazniwal fi awọn aworan kan to n se afihan gomina to n gbe ijọba le ikọ Taliban lọwọ soju opo Twitter .

Bi ikọ Taliban si se agba akoso Jalalabad yii tumọ pe wọn ti gba akoso awọn oju popo to so orilẹede naa mọ ilẹ Pakistan.

Ki lo n sẹlẹ ni Kabul?

Akọroyin iwe iroyin Wall Street Yaroslav Trofimov to wa ni Kabul sọ fun BBC lagbaye pe awọn n gbọ ti iro ibọn n dun lakọlakọ.

O ni awọn eeyan n gba owo lẹnu ẹrọ ATM nigba ti agbegbe tawọn ileesẹ asoju awọn orilẹẹde miran wa ti da paroparo, bẹẹ ni wn ti gba aaye tan ninu awọn baalu to n kurop lorilẹede naa.

Lara ete ti ikọ Taliban n da ni lati ri pe wọn ko da awọn ọmọ ogun rẹ to wa laarin ilu mọ.

Ikọ Taliban ko fi ọkọ ijagun ransẹ ko to gba ilu Kabul, wn wa nilu naa ni...wọn setan lati bẹrẹ ija. Ohun to sẹlẹ naa ree ni awọn ilu miran bii Herat nibi ti ija ti sadede bẹrẹ laarin ilu." Trofimov salaye.

Wamu-wamu ni awọn ọlọpaa Afghanistan duro, ti wọn si n da awọn ọkọ duro fun ayẹwo

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Wamu-wamu ni awọn ọlọpaa Afghanistan duro, ti wọn si n da awọn ọkọ duro fun ayẹwo

O le ni ida mẹrin miliọnu eeyan tiija naa ti sọ ti alainilelori mọ, ti ọpọ si n se atipo ni olu ilu naa.

Awọn eeyan to sa kuro lawọn agbegbe ti ikọ Taliban ti gba akoso rẹ ni awọn agbebọn naa n beoere pe ki awn fi awọn ọmọge ati obinrin silẹ, ki wn le di aya fun awọn jagunjagun awọn.

Muzhda, obinrin ẹni ọdun marundinlogoji, to sa kuro nilu Parwan lọ si Kabul pẹlu arabinrin rẹ meji ni oun yoo ya pa ara oun ni, dipo ki ikọ Taliban fi tipa fẹ oun.

"Tọsan toru ni mo fi n sunkun," O sọ fun ileesẹ iroyin AFP

Awọn obinrin to wa lawọn agbegbe ti ikọ Taliban ti gba akoso wọn ni wọn ti n fi tipa mu awn lati lo ibori fi boju ati ara - ti awọn agbebọn naa si n na awọn araalu to ba rufin.