EndSARS: Iléeṣẹ́ tó ń ṣàkóso "Billboard" tó wà ní Lekki Toll Gate ṣàlàyé ìdí tó ṣe pa iná pátákó ìkéde nàá

Oríṣun àwòrán, Nelson Ekujumi
Ileeṣẹ to n ṣakoso patako ikede to wa ni iloro Lekki Toll Gate, Loatsad Promo-media Ltd, ti pari ẹri rẹ niwaju igbimọ oluwadi ti ijọba ipinlẹ Eko gbe dide lati risi ẹsun ifiyajẹni ti awọn araalu fi kan awọn ọlọpaa SARS.
Ṣaaju ni akọwe ileeṣẹ naa, Abimbola Eniola ti kọkọ yọju siwaju igbimọ naa lẹyin ti wọn ke si lati sọ ipa ti ileeṣẹ naa ko ninu rogbodiyan to waye ni iloro ọhun logunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020.
Nigba ti agbẹjọro awọn oluwọde EndSARS n fi ọrọ wa ọgbẹni Eniola lẹnu wo lori idi ti wọn fi pa ina patako ikede to wa ni Toll gate naa, lasiko ti iroyin sọ pe awọn ọmọ ologun da ibọn bo awọn oluwọde, akọwe ileeṣẹ ọhun ni patako naa ko wa fun titan imọlẹ si iloro naa, bikoṣe lati polowo ọja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àrìnfẹsẹ̀sí ní bí wọn ṣe pa àwọn arìnrìnajò láti ìpínlẹ̀ Ondo ní ìpakúpa ní Jos - Akeredolu
- Orí kó ọmọ ọdún mẹ́ta tí wọ́n gbé sọnù sínú gọ́ọ́tà ní Ondo yọ lọ́wọ́ ikú
- Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì pa èèyàn 304, èèyàn 1,800 tún farapa ní Haiti
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ń dáàbò bo ara yín lọ́nà ìbílẹ̀ - Elebuibon
- Mọ̀ síi nípa àwọn ohun tó lè mú kí èèyàn tètè ní irun funfun lórí láì tíì di arúgbó
- ₦50m ni mo pàdánù lórí sinimá tí mo ṣe kẹ́yìn tórí àwọn tó ń ṣe ayédèrú fíìmù - Olaiya Igwe
Eniola sọ ọrọ naa lasiko to n dahun si ibere lori ẹni to paṣẹ pe ki wọn pa ina iloro ọhun.
Ọkan lara awọn agbẹjọro oluwọde, Adesina Ogunlana bere ni pato pe "Ta ni ẹni to paṣẹ pe ki wọn pa ina patako ikede naa?"

Oríṣun àwòrán, nigerianbulletin
Nigba to n fesi, Eniola sọ pe ọga awọn lo kede lori ikanni WhatsApp ileeṣẹ naa pe ijọba Eko ti kede konile-o-gbele, ti yoo bẹrẹ ni aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa.
O ni eredi ree ti awọn fi pa ina patako ikede ọhun ni aago mẹta ọsan ki awọn oṣiṣẹ awọn le tete de ile wọn ko to di aago mẹrin irọlẹ ti ijọba kede.
Bakan naa ni ẹlẹri keji fun awọn oluwọde to ti kọkọ sọ pe eeyan mejila ni ẹmi wọn ṣonu ni Toll Gate naa, Serah Ibrahim, ko yọju siwaju igbimọ ọhun nitori ara rẹ ti ko ya.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni rogbodiyan bẹ silẹ lasiko ti awọn ọmọ ogun ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde EndSARS ni iloro ọhun, nibi ti awọn eeyan kan ti jade laye, ti awọn mii si farapa.
- Wo ohun tó ṣe kí àtọ̀ rẹ fi ní agbára láti di ọmọ
- Orí afárá ni mo sì ti ń wẹ̀ l'Ojuelegba, ilé àkọ́kù ni mò ń gbé tẹ́lẹ̀ - Whitemoney
- Ẹ̀yin agbébọn, ajínigbé àti ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀, ìjọba mi yóò fimú yín dárin - Buhari
- "Inú òjò ní mo sùn fún wákàtí 48 pẹ̀lú ebi ní àhámọ́ ajinigbé"
- Wo ìye owó tí lítà epo pẹtirólú kan yóò jẹ́ lẹ́yìn ìpàdé ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti ìjọba













