Ondo state indigenes killed in Jos: Báyìí ní awakọ̀ Maruwa ṣé dóòlà ẹ̀mí mí lọ́wọ́ àwọn tó dá arìnrìnajò 22 lọnà ní Jos

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arinrinajo kan ti ori ko yọ ti ṣalaye fun awọn oniroyin bi o ṣe moribọ ninu iṣẹlẹ ipaniyan awọn arinrinajo ni Jos.
Ni ọjọ Abamẹta lawon janduku kan kọlu awọn musulumi to n dari bọ lati Bauchi lọ si iha Guusu Naijiria Eniyan bi mẹtalelogun ni wọn pa ninu wọn eniyan naa to n bọ lati ibi eto ayẹyẹ odun tuntun Hijirah
Muhammad Ibrahim jẹ okan ninu awon to moribọ ninu isẹlẹ ibi naa ni ipinlẹ Plateau to si sọ fun BBC pe bi kii ba ṣe ọpẹlọpẹ oni kẹkẹ Maruwa kan boya oun naa ko ba ti di ara awọn oku bayii. "Nigba ti isẹlẹ naa ṣe, mo kọkọ ro pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ lasan ni, sugbọn ko pẹ ni mo bẹrẹ si ni ri ti wọn n ju okuta mọ mọto wa, mi o mọ bi mo ṣe gba oju ferese moto jade."" Igba ti mo ba ara mi nilẹ ni oni kẹkẹ maruwa naa n pe mi pe ki n sare wọn inu kẹkẹ oun, bẹẹ ni mo ko sinu ẹ nnkan to ko mi yọ niyẹ. " Ki o to di igba naa, oju ara mi ni mo fi ri bi wọn se n fi okuta fọ awọn eniyan lori"

Oríṣun àwòrán, others
Muhammed ni bi o tilẹ jẹ pe ori ko oun yọ pẹlu ifarapa diẹ sibẹ ọjọ satide jẹ malegbagbe ni aye oun. Ni bayii, ijọba ti fi ofin konileogbele ni ijọba ibilẹ mẹta Jos North, Jos South ati Bass, ọpọ lo wa ninu ile wọn nito iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ́ ti tẹ ogún afurasí lára àwọn tó pa àwọn arìnrìnajò láti ìpínlẹ̀ Ondo ní ìpakúpa ní Jos - Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá
Ileeṣẹ ọlọpaa ti mu afurasi ogún lara awọn to pa awọn arinrinajo mejilelogun nilu Jos, nipinlẹ Ogun.
Ọjọ Satide ni wọn pa awọn eniyan naa to jẹ arinrinajo lati ipinlẹ Ondo, lasiko ti wọn n pada sile lẹyin eto ẹsin Islam ni Bauchi.
Abule Rukuba ni ikọlu naa ti waye nigba ti awọn janduku ọhun yabo awọn ọkọ awọn arinrinajo naa.
Awọn to le ni ọgbọn lo tun fi ara pa laarin wọn.
Niṣe ni awọn onikupani ẹda naa yabo awọn ọkọ to gbe wọn, ti wọn si bẹrẹ si ni i ṣa wọn ni ada, lẹ okuta ati igi mọ wọn.
- Orí kó ọmọ ọdún mẹ́ta tí wọ́n gbé sọnù sínú gọ́ọ́tà ní Ondo yọ lọ́wọ́ ikú
- Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì pa èèyàn 304, èèyàn 1,800 tún farapa ní Haiti
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ń dáàbò bo ara yín lọ́nà ìbílẹ̀ - Elebuibon
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá tí ìjọba dá sẹ̀ríà fún
- Ẹ̀yin agbébọn, ajínigbé àti ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀, ìjọba mi yóò fimú yín dárin - Buhari
Ileeṣẹ ọlọpaa si ti di ẹbi iṣẹlẹ naa ru awọn ọdọ lati abule Iregwe, nibi ti ọpọ eeyan ti jẹ ẹlẹsin Kristiẹni.
Ninu atẹjade to fi sita, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Frank Mba sọ pe Ọga Agba ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Alkali ti paṣẹ pe ki wọn o ko awọn ọlọpaa kogberegbe lọ si ipinlẹ Plateau lati mojuto eto aabo nibẹ.
Yatọ si awọn afurasi ti ọwọ tẹ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe oun doola eeyan mẹtalelọgbọn miran .
Ijọba ipinlẹ Plateau kede konile-o-gbele

Ninu iroyin miran lati gbọ pe ijọba ipinlẹ Plateau ti kede aṣẹ konile-o-gbele ni ilu Jos ati agbegbe rẹ nitori iṣẹlẹ iṣekupani naa.
Wakati mẹrinlelogun ni aṣẹ naa yoo fi ma a mulẹ.
Ijọba ipinlẹ naa sọ pe eeyan mẹtalelogun lo ku. Awọn alaṣẹ sọ pe ikede naa ṣe koko lati le dena ki eto abo dẹnu kọle.
Iṣẹlẹ ipani yii lo ti i buru ju ni Jos lati ọdun diẹ sẹyin ti ija ẹlẹyamẹya ati ti ẹsin dinku nibẹ.
Àrìnfẹsẹ̀sí ní bí wọn ṣe pa àwọn arìnrìnajò láti ìpínlẹ̀ Ondo ní ìpakúpa ní Jos - Gomina Akeredolu

Oríṣun àwòrán, others
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kesi awọn eniyan rẹ lati ni suuru, nitori ikọlu to waye si awọn kan ti igbagbọ wa pe ọmọ ipinlẹ naa ni wọn, nili Jos ni ipinlẹ Plateau.
Ọjọ Abamẹta ni iroyin jade pe awọn eeyan kan kọlu awọn eniyan naa lasiko ti wọn n rinrinajo pada lati ipinlẹ Bauchi si Gusu Naijiria.
Iṣẹlẹ yii lo waye lẹyin ọjọ diẹ ti ija kan ti kọkọ waye laarin awọn agbẹ to jẹ ẹlẹsin Kristiẹni ati awọn darandaran to jẹ Musulumi ni agbegbe naa.
Iroyin sọ pe ko din ni ọgbọn eeyan ti awọn jaguda yii pa lara awọn arinrinajo naa, ti ọpọlọpọ wọn si tun fi ara pa.
Ninu atẹjade ti Akọwe Ikede rẹ, Richard Olatunde fi sita ni alẹ ọjọ Abamẹta, Gomina Akeredolu sọ pe iroyin ti Gomina ipinlẹ Plateau fi to oun leti fihan pe arinfẹsẹsi ni awọn arinrinajo naa rin, nitori wọn ko mọ nkankan nipa ija to ti kọkọ waye.
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ń dáàbò bo ara yín lọ́nà ìbílẹ̀ - Elebuibon
- Àwọn ajagungbalẹ̀ gba ilẹ̀ tó yẹ fún kíkọ́ iléèwé girama ní ìpínlẹ̀ Ogun
- Agbébọn pa ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá nígbàkan rí, Christopher Deja
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
- Alaafin Oyo, Oba Adeyemi yarí lórí isẹ̀lẹ̀ ìsekúpani tó wáyé ní Igangan
Awọn iwadii to ti waye lori ipaniyan yii fihan pe awọn ọkọ awọn arinrinajo naa gba agbegbe ti rogbodiyan ti waye sẹyin, ti awọn to kọlu wọn si ro pe alatako ni wọn jẹ, nitori bi wọn ṣe kọ.
Gomina Akeredolu ni oun gba awọn eniyan ipinlẹ Ondo ni iyanju lati má fa wahala nitori iṣẹlẹ naa, to si bẹ wọn pe ki wọn o ma sọ ọrọ naa di nkan ti ko jẹ.
"Mo ti ba arakunrin mi, gomina ipinlẹ Plateau sọrọ, o si ti fun mi ni idaniloju pe igbesẹ ti n waye lori iṣẹlẹ naa.Iwadii mi ati iroyin ti mo gbọ fihan pe lootọ ni wọn pa awọn eniyan kan, ti awọn to fi ara pa si ti n gba itọju nileewosan."
"O daju pe arinfẹsẹsi ni iṣẹlẹ naa, gẹgẹ bi akẹẹgbẹ mi ṣe sọ fun mi. Mo si fẹ ẹ fi da awọn eniyan wa to n gbe ni ipinlẹ Plateau loju pe ko si ẹni to fẹ ẹ doju kọ wọn ninu ija ẹsin tabi ti ẹlẹyamẹya."
Bakan naa lo tun ba ẹbi awọn eniyan to padanu ẹmi wọn kẹdun.
Kini ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Plateau sọ̀ lori iṣẹlẹ naa?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Plateau ti sọ pe eeyan mejilelogun ti kagbako iku tawọn ọpọ si farapa ninu ikọlu kan to waye ni Jos.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi,musulumi lawọn arinrinajo to ku yii ti wọn si n dari bọ lati ibi ajọdun ọdun Hijrah kan ti wọn lọ ṣe ni Bauchi
Bi awọn arinrinajo yi ṣe n gba inu Jos kọja ni awọn kan da wọn lọna ti wọn si pawọn ni ipakupa.
O ṣeese ki iye eeyan to ku ninu iṣẹlẹ yi ju iye ti ọlọpaa pe lọ ti a ba wo nkan ti awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn sọ.
Akọroyin kan to kan si ile iwosan lagbegbe iṣẹlẹ yi sọ fun BBC pe oun ka oku ọgbọn ti ọpọ si n gba itọju nibẹ
Gẹg bo ti ṣe wi, ọgbẹ ada lo wa lara pupọ awọn to farakasa iṣẹlẹ yi.
Ko tii si aridaju idi ti wọn fi doju ija kọ awọn arinrinajo musulumi wọn yi.
Iṣẹlẹ yi waye lẹyin ikọlu kan laipẹ yi laarin awọn Fulani darandaran ati awọn agbẹ ẹya Iregwe ti pupọ wọn jẹ Kristẹni.
Gomina Simon Lalong ti bẹnu atẹ lu ikọlu yi to si ni ijọba ko ni faramọ iwa aibọwọ fun ofin kankan nipinlẹ naa.
Ija ẹlẹyamẹya ti waye kẹyin ni nkan bi ọdun 2001 ni Plateau ko to di pe o wa lọlẹ lẹnu lọọlọ yi.
Iṣekupaniyan eleyi lo buru julọ lẹnu igba ti ipenija aabo bẹrẹ si ni peleke si jakejado Naijiria.















