Chief Imam death: Ọlọ́pàá ní kò sí àpá lára òkú Ìmáàmù tó lè fihàn pé ajínigbé ló pa á

Sheikh Mushafau Bakare

Oríṣun àwòrán, Facebook/M.O. Bakare

Ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ko si ẹri to daju to fidi rẹ mulẹ pe awọn janduku tabi tabi awọn ajinigbe lo ṣekupa Imaamu awujọ Atiba ni Ijebu Ode, Sheikh Mushafau Bakare.

Inu mọto Imaamu naa si ni wọn ti ri oku rẹ ni ọsan Ọjọbọ.

Ni Ọjọru lawọn ẹbi Sheikh Bakare sọ fawọn ọlọpaa pe Imaamu naa ko pada wale lati igba to ti jade lọ.

Awọn ẹbi rẹ si ro pe o ṣeeṣe ko ti bọ sọwọ awọn ajinigbe pawo, ki wọn si ti ṣeku pa a.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amọ ni owurọ Ọjọbọ ni wọn ri oku Imaamu naa ninu ọkọ Toyota Highlander to ṣẹṣẹ ra lagbegbe Ikangba ni ijọba ibilẹ Odogbolu nipinlẹ Ogun.

Awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ ni agọ ọlọpaa ẹkun Obalende ni Ijebu-Ode, lo ri oku Sheikh Bakare ninu ọkọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Wikipedia: Ẹ̀nìkan sọ fún mi pé iṣẹ́ ìdọ̀tí ni màá ṣe ni mo ṣe ń ta ìwé

Ṣugbọn agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbola Oyeyemi, ṣalaye pe awọn ajinigbe kọ le gbe Imaamu yii.

Bakan naa ni DSP Oyeyemi sọ pe awọn agbebọn kọ lo pa Imaamu Atiba gẹgẹ bi ọpọ ṣe gbagbọ.

Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa ni ko si apa kankan lara rẹ eyi to le fidi rẹ mulẹ bo ya awọn agbebọn tabi ajinigbe lo ṣeku pa a.

''Imaamu yii kuro ni ile lati lọ si ode ṣugbọn ko pada wale, eyi lo jẹ kawọn ẹbi rẹ fi ọrọ to awọn ọlọpaa leti.

Awọn ọlọpaa agbegbe Ijebu-Ode lo ri oku rẹ ninu ọkọ lẹgbẹ ọna nibi to duro si.

Ohun ti a gbọ ni pe Sheikh Bakara ni arun ẹjẹ ruru, o ṣeeṣe ko jẹ pe igba ti arun yii n yọ ọ lẹnu, ti ko si ri oluranlọwọ lo gbẹmi mi nitori ko si apa kankan lara oku rẹ,'' DSP Oyeyemi lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, wọn ti sin oku Imaamu naa l'Ọjọbọ ni awujọ rẹ ni ilana ẹsin musulumi.