Buhari: Ìjọba mi ti ń lo ẹ̀rọ ìgbàlódé láti pèsè èrè ìjọba alágbádá àti fún àgbéga Nàíjíríà

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Muhammadu Buhari/Facebook

Bi ogun ẹni ba da ni loju, a fi gbari ni, ma si fi oko mi se aala, ọjọ kan ni eeyan maa n kọ ọ.

Eyi lo mu ki aarẹ Muhammadu maa leri leka, to si n tọ ilẹ la pe ijọba yoo gbajumọ eto aabo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari fọwọ idaniloju yii sọya nibi ayẹyẹ ikẹkọjade ile ẹkọ ologun to wa nilu Abuja, eyi to waye lọjọ Ẹti.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Buhari, ẹni ti minisita eto aabo, Bashir Magashi soju fun wa salaye awọn igbesẹ ti ijọba rẹ n gbe lati se agbekalẹ ileesẹ alaabo tuntun, ko si se atunse awọn eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ.

"Bi o tilẹ jẹ pe orilẹede wa n koju ipenija awọn agbebọn ati ikọ afẹjẹwẹ, ajinigbe, ija agbẹ ati darandaran pẹlu awọn agbesunmọmi.

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

Sibẹ, ọna agbara ni ijọba mi fi n kọju oro si wọn ko le pese aabo to peye fun ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria.

A ti mu ki alaafia jọba ni agbegbe Niger-Delta, ta si ti gba ọpọ ilẹ lọwọ awọn adunkookomọni to wa lẹkun ila oorun ariwa Naijiria.

A si ti n tẹsiwaju lati ri daju pe eto aabo to dara fidi mulẹ fun alaafia ati idagbasoke Naijiria, lai naani awọn ipenija yii, igbẹkẹle wa ninu ilẹ yii ko mi rara."

Aarẹ Buhari tun fi ọwọ idaniloju sọya pe ijọba oun n gunle awọn amulo imọ ẹrọ igbalode lati mu ki omitooto ere ijọba awa ara wa de ẹẹkẹ awọn ọmọ Naijiria ati fun idagbasoke orilẹede yii.

Amin iyasọtọ kan

Apostle Suleman lo ọlọ́pàá láti fi ìyà jẹ oníbàárà mi, ó fi sí àtìmọ́lé torí ọ̀rọ̀ tó sọ - Amòfin

Apostle Suleman ati Isreal Balogun

Ileesẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nilu Abuja ti fi sọrọ sọrọ ori ayelujara YouTube kan, Israel Balogun, sì ahamọ nitori ẹsun pe o ba Apostle Johnson Suleman lórúkọ jẹ, to si tun n dọdẹ rẹ lori ayelujara.

Iroyin sọ pe fun bi i wakati mẹrin ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fi fi ọrọ wa Ọgbẹni Balogun lẹ́nu wo lori awọn ẹsun naa.

Lẹyin naa ni awọn yoo gba beeli rẹ, pẹlu awọn ilana to lagbara, ko to o di pe wọn tun fi si atimọle.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ni ọjọ diẹ sẹyin ni Balogun fi fidio kan si ori ayelujara YouTube rẹ, nibi to ti bu ẹnu ẹtẹ lu fidio kan to safihan Apostle Suleman to sọ pe awọn áńgẹ́lì yoo fi owo si apo àsùnwọ̀n awọn ọmọ ijọ rẹ.

O sọ eyi lasiko ijọsin kan to waye ni ile ijọsin rẹ ni ilu Atlanta lorilẹ-ede America, ati ilu Auchi nipinlẹ Edo, lorilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Doctors‘ Strike: Àwọn dókítà tó ń woṣẹ́ níran ní UCH sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀dùn ọkàn wọn

Ti àwọn ọmọ ijọ kan naa si bẹrẹ si ni fi atejisẹ han ninu isin naa pe awọn ti ri owo ninu apo asunwon banki wọn, lati ọdọ áńgẹ́lì.

Ọgbẹni Balogun sọ pe ayederu isẹ iyanu ni Apostle Suleman ṣe.

Ọrọ to sọ yii fa ariyanjiyan lori ayelujara. Bi awọn kan ṣe gboriyin fun Balogun fun bo ṣe bu ẹnu ẹtẹ lu Suleman, ni awọn kan n sọ pe Balogun fẹ ẹ fi ọrọ naa wa okiki ni.

Agbẹjọro Isreal Balogun salaye bi ọrọ se jẹ:

Agbejọro fun Israel Balogun, Amofin Inibehe Effiong sọ fun BBC pe awọn ọlọpaa fi onibaara òun si atimọle, bo tilẹ jẹ jẹ pe funra rẹ lo lọ jẹ ipe ti wọn pe e.

O ni wọn kọ lati fi pasitọ naa silẹ, ti wọn si ni ko lọ ọ mu oniduro to jẹ oṣiṣẹ ijọba, to si tun gbọdọ setan lati fi iwe igbega to gba kẹhin lẹ́nu isẹ tabi lẹta idanimọ lati ibi to ti n sisẹ silẹ.

O ni lootọ ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki oniduro naa de agọ ọlọpaa, sugbọn gbogbo igbiyanju lati mu ki ẹlomiran to setan lati fi iwe ilé rẹ nilu Abuja silẹ, titi ti oniduro yoo fi de lonii, lo ja si òfo.

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

O ṣalaye pe saaju ni agbejọro Wolii Suleman kọ lẹta si onibaara oun pe ko tọrọ aforijin fun ọrọ to sọ, ti oun oun si fi esi ránṣẹ pe ko ni idi kankan lati tọrọ aforijin.

"A jẹ ko ye wọn pe ko si ohunkóhun ti onibaara mi yoo tọrọ aforijin fún, bẹẹni a si setan lati yanju rẹ nile ẹjọ.

"Sugbọn bi ọrọ ṣe ri bayii, o daju pe Suleman n lo ọlọpaa lati fi iya jẹ onibaara mi, eyi ti ile ẹjọ kò le fi aaye rẹ gba a. "

O ni awọn ẹsun ti wọn fi kan onibaara òun, Páṣítọ̀ Balogun ko boju mu rara.

Kin ni Apostle Johnson Suleman sọ lori ọrọ yii?

Ninu iroyin ti awọn ileesẹ iwe iroyin kan gbe jáde, wọn ni Apostle Suleman sọ pe oun ko mọ nipa iwe ẹsun naa.

Bakan naa ninu fidio kan ti Apostle naa fi sita, o ni oun ti sakiyesi pe awọn eeyan ma n bu oun lori YouTube lati fi wa ero si oju opo rẹ, ati lati pawo.

O ni oun si ti pinnu lati gba owo fun eebu ti wọn n bu oun.

Apostle naa sọ pe "lasiko yii, bibu àwọn pasitọ ni awọn sọrọ sọrọ ori ayelujara fi n pa owo. Mo si jẹ ọkan lara awọn ti wọn ma n bu."

"Mi o binu si wọn, nitori pe ẹgbẹrun eebu ko le di nkankan. Sugbọn nkan to n dun mi ni pe wọn yoo fi eebu bibu pawo ni ipari oṣu lọwọ YouTube.

" Nitori naa, a ni lati jọ dunadura pe wa a sanwo fun mi ti o ba bu mi.

"Ma a fi ọwọ si pe ko bu mi, to o ba sa ti fun mi ni owo, nitori pe ẹgbẹgbẹrun eebu ko le ja iranṣẹ Ọlọ́run tootọ bọ́.

Àkọlé fídíò, Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú