Hushpuppi: Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí Òkè Ọya bẹ̀bẹ̀ àtìlẹyìn fún Abba Kyari

Abba Kyari ati Hushpuppi

Oríṣun àwòrán, Daily Nigerian

Agbẹjọro mọkanlelọgbọn lati oke Ọya ti yọnda lati ṣoju ọga ọlọpaa, DCP Abba Kyari lai gbowo lori ẹsun jibiti ti ile iṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ilẹ Amẹrika fi kan an pẹlu Ramon Abass(Hushpuppi).

Ile iṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria ti ni ki igbakeji kọmiṣọnna ọlọpaa Kyari lọ rọkun nile na bi ajọ FBI ṣe n ṣe iwadii lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Sunusi Bappah Salisu to jẹ agbẹnusọ fawọn agbẹjọro naa ṣalaye pe awọn amofin mọkanlelọgbọn yii wa lati ipinlẹ mọkandinlogun to wa lapa ariwa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Salisu ni igbeṣẹ yii waye lẹyin ti ẹgbẹ Coalition of Northern Groups kepe awọn eeyan oke Ọya lati gbaruku ti Kyari.

''A pinnu lati gbija Kyari lọfẹẹ lati ri pe wọn ko fi ẹtọ Kyari dun un.

Àkọlé fídíò, Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Gbogbo ẹsun tawọn ọlọpaa FBI fi kan Kyari ni a o wo fini fini, ohun to mu ki ile ẹjọ sọ pe o gbimọ pọ pẹlu Hushpuppi lati lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara.

A o beere awọn ibeere to nii ṣe pẹlu ẹtọ Kyari to le di titẹ mọlẹ tori ẹsẹ ikẹfa ati ikeje iwe ofin ilẹ Afirika sọ pe gbogbo eeyan lo lẹtọọ si ominira.

Iwe ofin naa tun sọ ninu awọn yii pe gbogbo eeyan lo lẹtọọ si abo ati pe wọn tun lẹtọọ lati sọ ti ẹnu wọn.

Bakan naa ni ajọ iṣọkan agbaye, UN sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba fi ẹsun kan lo jẹ afurasi.

O digba ti ile ẹjọ ba fi idi rẹ mulẹ pe lootọọ lo jẹbi ẹsun ti wọn kan an lẹyin ti wọn ti fun oun naa laaye lati sọ ti ẹnu rẹ ni wọn le pe ni ọdaran.