Sunday Igboho: Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí Igboho ké sáwọn Alfa, Pásítọ̀, oníṣẹ̀ṣe láti ké pe Ọlọ́run pẹ̀lú gba ààwẹ̀ àti àdúrà

Oríṣun àwòrán, sunday_Igboho/Instagram
Yoruba ni ẹni ti a ko ba le mu, Ọlọrun ọba ni a fi le lọwọ, ati pe ẹni mi ko sẹni, eeyan mi ko seniyan amọ ko ni jọ alaaro lasan.
Idi ree ti awọn eeyan ilu ajijagbara fun ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho fi bẹrẹ igbesẹ lati duro ti eeyan wọn ko le bọ lọwọ ipenija ati idojukọ to n ba finra lorilẹede Benin.
Awọn ọmọbibi ilu Igboho naa, ti wọn korajọpọ sabẹ aburada ẹgbẹ Ifelodun ọmọ Igboho, eyi ti Alhaji Imran Oloyoyo ko sodi, lo fidi isẹlẹ naa mulẹ.
- Wọ́n ti fi ẹ̀sùn míì kan Sunday Igboho ní ìlú Benin! - Agbẹ́jọ́rò Igboho
- Sunday Igboho kọ́ ló ń gbọ́ bùkàtà ẹ̀jọ́ rẹ̀, àwa àjìjàgbara ní - Banji Akitoye
- Wo ìgbà márùn-ún tí wọn saáyan láti mú Sunday Igboho
- "Á dá ohun àlùmọ́ọ́nì wa jọ láti gbèjà Sunday Igboho nílé ẹjọ́"
- "Ẹni tó bá gba 'Passport Benin Republic' láì ṣe ọmọ onílùú, yóò fi ẹ̀wọ̀n jura"
- Ooni Ife àtàwọn èèkàn Yorùbá ṣèpàdé ìdákọ́nkọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Sunday Igboho
- Sé lóòtọ́ ni wọ́n ti fi Sunday Igboho sílẹ̀ ní Cotonou?
Awọn eeyan ilu Igboho, to wa nijọba ibilẹ Oorelope nipinlẹ Oyo ti wa gunle eto aawẹ ati adura lati mu Sunday Igboho bọ ninu ọfin ofin to jin si nile ẹjọ.
Awọn eeyan ile Igboho lo n gunle ija inu ẹmi yii lati fi tako igbesẹ ijọba apapọ to fẹ di ajafẹtọ ẹni naa lapanyaka wọnu baalu wa sile lati ilu Cotonou.
Nigba to n salaye igbesẹ ẹmi ti wọn fẹ gbe, Oloyoyo ni irọ to jinna sootọ ni wọn pa mọ Sunday Igboho pe o fẹ doju ijọba Buhari bolẹ ni.
O ni wọn kan fẹ sọ aja Igboho ni orukọ buruku ni ki wọn le so mọ igi lati pa nitori ohun to se ko kọja igbesẹ to gbe lati ja fun ominira Yoruba nitori iwa aidaa ti wọn n hu si wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ara àwọn alátìlẹyìn Tinubu láti di ààrẹ kò yá, wọ́n nílò àyẹ̀wò ọpọlọ - Bode George
- Wo owó bodè tó san, tó bá gbé ọkọ̀ kọjá ní márosẹ̀ Nàíjíríà
- Iléeṣẹ ọlọpàá mú ọgá àgbà iléèkó nítorí pé o fipá bá akẹkọọ lò pọ
- Èyí ni ìgbà tó ṣeéṣe kí Twitter padà sẹ́nu iṣẹ́ ní Nàìjíríà
- Instagram gbé Èròjà tuntun jáde láti dẹ́kun ìdẹ́yẹsí, wo bí o ṣe lè lòó
- Ọwọ tẹ Mohammed, afurasí fúlàní darandaran tó gbé ìbọn AK47 nípìnlẹ Ogun- Iléeṣẹ ọlọpàá
- Ọba alayé kan àti gómìnà kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi, kí n tó fẹ́ Mr Lawal - Lizzy Anjorin
"Ni aye ti oju ti la yii, o n kọ mi lominu pe araalu ti ko ni olugbeja tabi ohun aabo kankan, ni wọn n naka aleebu si pe wọn fẹ doju ijọba bolẹ.
Bẹẹ ni lati igba tijọba ti kede pe oun n wa Sunday Igboho, ile ẹjọ kankan ko tii kede pe o jẹbi, nitori naa, alailẹsẹ lọrun si ni Igboho."
Alhaji Oloyoyo ni idi ree ti agbarijọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ Ifelodun Igboho fi ke sawọn asaaju ẹsin Kristiẹni ati Musulumi to fi mọ awọn ẹlẹsin ibilẹ.
O ni koko ohun ti wọn se ni lati gbe ohun soke, ke pe Ọlọrun ninu ẹbẹ aawẹ ati adura, ki ọmọ wọn le bọ lọwọ kinihun aye to gbe hanu.
Oloyoyo naa ni ireti si wa pe Ọlọrun ti da si ọrọ naa, to si ti pe adura wọn lori Sunday Igboho.




















