Èròjà tuntun tí Instagram gbé jáde láti dẹ́kun ìdẹ́yẹsí- wo bí o ṣe lè lòó

Aworan Instagram

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ojuopo ikansiraẹni Instagram ti kede awọn eroja ati irinṣẹ tuntun fun didẹkun ọrọ alufansa lori ikanni naa ati didaabo bo awọn to n loo lọwọ awọn adunkukulajamọni.

Awọn ohun elo "makan" naa yoo wa fun lilo kaakiri agbaye lati maa funrarẹ gbe awọn ọrọ ati atẹjade latọdọ awọn ti kii ṣe ololufẹ eeyan bẹẹ pamọ.

Instagram ṣalaye pe eroja tuntun naa yoo wa lati maa dena awọn to ba fẹ maa sọ ọrọ kotọ sawọn eekan lawujọ.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ Instagram n tọka si iṣẹlẹ idẹyẹsi to waye lẹyin ifẹsẹwọnsẹ aṣekagba idije Euro 2020 laarin ikọ agbabọọlu England ati Italy gẹgẹ bii ara ohun to sun wọn si igbesẹ tuntun yii.

Lẹyin ti England ja kulẹ ni ifẹsẹwọnsẹ nipasẹ pẹnariti, oju awọn agbabọọlu England to jẹ alawọ dudu ri to lọwọ awọn to dẹyẹsi wọn, paapaajulọ lori awọn ikanni ayelujara gbogbo.

Ki lo mu ki wọn gbe igbesẹ tuntun yii?

Bi idẹyẹsi lori ayelujara wọnyii ṣe pọ lo faa ti olotu ijọba ilẹ Gẹẹsi o ke si ileeṣẹ Instagram atawọn oju opo ikansiraẹni miran pe ki wọn tubọ jawe sobi wọn lori didena idẹyẹsi loju opo wọn.

Instagram wa n woye pe ero oawọn ni pe awọn eroja tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe kalẹ yii yoo lee daabo bo awọn eeyan lọwọ awọn ọrọ idẹyẹsi, ẹlẹyamẹya tabi idẹyẹsi yoowu.

Bawo ni awọn eroja yii yoo ṣe maa ṣiṣẹ?

Aworan Instagram

Oríṣun àwòrán, Instagram

Instagram ni dipo eyi ti awọn tọrọ ba kan yoo fi baa pa awọn atẹjade tabi ọrọ bẹẹ rẹ funra wọn to si jẹ pe pupọ igba ni wọn maa n pa ọrọ awọn ololufẹ wọn miran rẹ pẹlu nipasẹ bẹẹ, eroja tuntun yii ni yoo maa pa awọn to n dẹyẹsi ẹni bẹẹ lẹnu mọ.

Oju opo ikansiraẹni naa tun kede rẹ pe awọn yoo gbe eroja "Hidden words system" ti awọn ti kọkọ kede ṣaaju sita fun gbogbo eeyan lagbaye.

Ki lo ti wa ṣẹlẹ lẹyin ikede Instagram yii?

Eroja yii ti wọgile awọn ọrọ ati atẹjade to le ni ẹgbẹrun meji eleyi ti wọn fi doju idẹyẹsi kọ awọn agbabọọlu ilẹ Gẹẹsi lẹyin aṣekagba idije Euro 2020 to kọja.

Ilẹ Gẹẹsi lawọn eeyan to n dẹyẹsi ẹni nipa ti ẹya ti pọjulọ la gbaye.

Ida mọkandinlọgọrun awọn eeyan to ni awọn oju opo ti irufẹ ọrọ idẹyẹsi bẹẹ ti jade ni wọn ti wọgile.