Yoruba Nation: Abdulsalam Abubakar sọ ìdí tí kò fi ṣeéṣe láti pín Nàíjíríà sí wẹ́wẹ́

Awọn eeyan to n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba ati Biafra gbe asia ikọọkan wọn lọwọ

Asaaju ijọba ologun tẹlẹ, Ajagunfẹyinti Abubakar Abdulsalam ti sisọ loju rẹ pe ofo ọjọ keji ọja ni aayan awọn eeyan to fẹ ya kuro lara Naijiria.

Abubakar sisọ loju ọrọ yii nibi eto ifọrọjomitoro ọrọ kan ti wọn fi sọri Ibrahim Babangida ati ogun to fi silẹ, eyi waye ni Ọjọbọ.

Abubakar lasiko to n sọ ero tiẹ lori bawọn eeyan kan se n beere fun idasilẹ orilẹede Yoruba ati Biafra kuro lara Naijiria, wa salaye idi ti erongba naa ko fi le jọ laelae.

O ni egungun ti wọnu ẹran, ẹran naa si ti wọnu egungun, ti ọpọ Yoruba si ti ba Hausa se igbeyawo, bẹẹ naa ni Fulani ti ba ẹya Igbo da ana laimọ iye igba, eyi ti yoo mu ko nira lati yapa.

"Tẹ ba ti tiẹ fọ Naijiria si yẹlẹyẹlẹ bayii, ki lẹ fẹ se nitori ko si abule tabi ilu tẹ de, tẹ ni ba ẹya Hausa, Igbo, Itsekiri tabi Yoruba nibẹ.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba

Tẹ ba wa da duro, nibo lẹ fẹ fi ti igbeyawo laarin ẹya kan ekeji si, nitori naa yoo nira lati fọ orilẹede Naijiria si wẹwẹ.

Amọ gbogbo wa lo yẹ ka pawọpọ lati wa ojutu si iwa aidaa tawọn kan n hu, yoo si dara kawọn eeyan maa tete tu asiri awọn onisẹ ibi, ti ko jẹ ki eto aabo wa duro re."

Adari Naijiria tẹlẹ naa wa rọ awọn araalu lati gba alaafia laaye, ki wsn si fara mọ oniruuru ẹya ati ede to wa nilẹ yii, ki wọn si tun maa wa irẹpọ laarin ara wọn.

Amin iyasọtọ kan

Ọwọ tẹ Mohammed, afurasí fúlàní darandaran tó gbé ìbọn AK47 nípìnlẹ Ogun- Iléeṣẹ ọlọpàá

afurasi

Oríṣun àwòrán, Nigeria police Ogun state

Owo te Mohammed, afurasi darandaran kan to gbe ibon AK47 nipinle Ogun

Ileese olopaa nipinle Ogyun ti so okunrin kan to pe oruko ara re ni Mohammed si gbaga olopaa.

Won mu u lojo Isegun, ojo kewaa, osu kejo, odun 2021 ni ipinle Ogun ni guusu iwo oorun Naijiria.

Ileese olopaa ni won gba ifitonileti nipase DPO to wa ni ekun Imeko pe awon Fulani meji kan n tin kiri agbegbe CAC Igbo Oba ni Iwoye Ketu pelu ibon AK 47 lowo won.

Ni kete ti ifitonileti yii de ódó DPO naa lo ti da awọn ọlọpaa mii sita pẹlu awọn ọdẹ aṣogbo ati awọn fijilante.

Àkọlé fídíò, Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47

Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn ti n ṣo igbo Oba ni ọwọ tẹ awọn Fulani afurasi meji naa.

Bi wọn si ti kọkọ mu Muhammed pẹlu ibọn AK 47 to gbe dani nibi to farapamọ si naa ni wọn ti fọwọ ofin mu u.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni o jẹ afurasi lara awọn ajinigbe to n ṣọṣẹ ni agbegbe Ketu.

Ninu atẹjade ti DSP Abimbola Oyeyemi to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fọwọ si ni o ti ni pe Komiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti paṣẹ lori ọrọ naa.

Àkọlé fídíò, Tope Ajogbajesu: Mọ̀lẹ́bí kan ní orin ikú ọdún yìí fò mí ru ní Tope kọ láàrin ọ̀sẹ̀ tó kú

Abimbola ni Komiṣọnna Edward Awolowo Ajogun ti ni ki awọn otẹlẹmuyẹ agbofimro bẹrẹ iwadii ni kia.

O tun ni ki wọn tubọ wa igbo Oba naa lọ ki wọn le mu awọn to ku to jẹ oniṣẹ ibi nibẹ.