Goriola Hassan: Ilé Aṣòfin Ogun ní kí Hassan wá dàhùn ẹ̀sùn tí ẹgbẹ́ ọmọbíbí ìlú rẹ̀ fi kàn-án lórí ọba tó jẹ

Oríṣun àwòrán, Content
Gbajumọ osere tiata tẹlẹ to ti wa di ọba bayii, Goriola Hassan lo ti n ni ede aiyede pẹlu ile asofin ipinlẹ Ogun nitori oye ọba to jẹ.
Ile asofin ipinlẹ Ogun si ti wa pasẹ pe oun yoo ni ki awọn ọlọpaa gbe Goriola si ahamọ ni, to ba tun fi pe ara rẹ ni ọba ilu Imobi, to wa nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ijebu nipinlẹ naa.
Ọjọ Isẹgun, ọjọ Kọkanla osu Kẹjọ ọdun 2021 ni ile asofin naa fi ikede yii sita, to si tun pasẹ pe ki Goriola yọju siwaju igbimọ ile to wa fun ọrọ oye jijẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo ọba kan nílẹ̀ Yorùbá, tí kò ṣe ètùtù tàbí náwó ànájù, kó tó jọba
- Akintoye àti èèyàn 1m míì ń lọ àpéjọ UN lórí ìyapa Nàíjíríà
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- PDP ni yóò mú ọmọ Nàíjíríà kúrò lóko ìyà tí wọn wà ní 2023 - Kola Ologbondiyan
- Wòlíì tó ní kí wọ́n sin òun láàyè torí agbára ìṣẹ́gun, gba ibẹ̀ sọdá sí ọ̀run
- Ọmọ ìyá méjì tó ń lọ ṣe ìdánwò NECO wà lára èèyàn márùn ún tí tírélà agbépo tẹ̀ pa n'Ibadan
Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Post ti salaye, ile wa ni ti ọba naa ba fi faake kọri lati yọju siwaju igbimọ ile naa titi di ọjọ Kẹtadinlogun osu Kẹjọ ọdun 2021, gboro yoo gbe.
Alaga igbimọ ile to wa fun ọrọ oye jijẹ naa, Asofin Bolanle Ajayi ni ile ti fi iwe kan ransẹ saaju lati pe Goriola Hassan pe ko yọju siwaju wọn amọ to kọ lai yọju.
O wa fun osere tiata tẹlẹ naa ni anfaani lati pada yọju siwaju igbimọ naa lọjọ isẹgun ọsẹ to n bọ, tii se ọjọ Kẹtadinlogun osu Kẹjọ, bibẹẹkọ, wọn yoo gbe janto.
Ajayi ni isọri awọn eeyan kan ti wọn pe ara wọn ni ẹgbẹ ọmọ bibi ilu Imobi lo kọwe ẹsun wa sile asofin nipa ọba naa, ti ile si fẹ fun ni anfaani lati wa sọ tẹnu rẹ.
O ni iwe ẹsun naa lo da lori bi Goriola Hassan se n pe ara rẹ ni ọba ilu Imobi-Ijebu.
Ile asofin ipinlẹ Ogun ti wa kesi Goriola lati jawọ ninu pipe ara rẹ ni ọba ilu Imobi-Ijebu.
Bakan naa ni wọn pasẹ fun Goriola lati yọju siwaju ile pẹlu awọn baalẹ mẹrindinlogoji to wa ni agbegbe rẹ.
Igbesẹ naa ni wọn sọ pe yoo fun awọn asofin ọhun ni anfaani lati wa ojutu titi laelae si aawọ ọba jijẹ to n ba agbegbe naa finra.
Ajayi wa kede pe ti Goriola Hassan ba fi kọ lai yọju, ile yoo pasẹ fun ileesẹ ọlọpaa lati lọ gbe gbogbo awọn ti wọn ni ko ysju naa, paapaa Hassan.

















