Goriola Hassan: ‘Tattoo’ tó wà lára mi, kò dí ọba jíjẹ lọ́wọ́, ara oge ṣíṣe ni

Oba Goriola Hassan

Oríṣun àwòrán, Instagram/goriolahassan

Gẹgẹ bi aṣa ilẹ Yoruba, o ni awọn etutu kan ti ilu gbọdọ ṣe ati eyi ti ọmọ oye to ba fẹ jọba naa ni lati ṣe, ki o to le gori oye.

Amọ, o dabi ẹni pe gbogbo nkan lo ti yipada bayii bo ya nitori pe aye ti di aye ọlaju ni.

Oṣere tiata kan ree, Goriola Hassan to sọ pe, oun ko ṣe etutu kankan, ki oun to jẹ ọba ilẹ Uba Imobi nilẹ Ijẹbu nipinlẹ Ogun.

Ọgbẹni Hassan to ti jẹ Ọba ilẹ Uba Imobi bayii sọ pe, lootọọ ni pe wọn gbọdọ ṣe awọn eto, amọ ni toun, ko si ohun to jọ etutu rara.

Oba Goriola Hassan atawọn mii

Oríṣun àwòrán, Instagram/somolu

''Ko digba ti wọn ba to lo odidi eeyan ṣe irubọ, ki eeyan to le jọba, a o ni lati faye ni ẹnikeji lara,'' Oba ilẹ Uba lo sọ bẹẹ.

Bakan naa ni Kabiyesi Uba ṣalaye pe, oye ti oun jẹ ko na oun owo bii ti wulẹ ko mọ.

Awọ̀n ilu lo se inawo iwuye mi:

Oba ilẹ Uba ni ''idile ọba ni wọn bi mi si, ati idile mama ati baba mi ni wọn n maa n jọba.''

O nigba ti oun de lati orilẹede Amerika, lawọn araalu wa ba oun pe ki oun jẹ ọba ilẹ Uba.

''Mi o ni lati nawo kankan, awọn ilu gan an lo ṣe inawo ibẹ,'' Kabiyesi Uba lo ṣalaye bẹẹ.

Omogoriola Hassan

Oríṣun àwòrán, Omogoriola Hassan

Olori kan ti mo ni ti to mi:

Lori ọrọ awọn olori laafin, Oba ilẹ Uba ni oju kan lada ni lọrọ oun, o ni iyawo kan toun ni, ti tẹ oun lọrun.

''Mi o le nifẹ obinrin meji pọ lẹẹkan naa, nitori naa, o maa nira fun mi lati ni olori meji laafin,'' Oba Uba lo woye bẹẹ.

Bẹẹ ba si gbagbe, gbajumọ osere tẹlẹ naa lo fẹ ọkan lara awọn osere tiata lobinrin, Ayo Adesanya, ko to di pe aarin wọn daru.

Omogoriola Hassan

Oríṣun àwòrán, Omogoriola Hassan

Oge sise lasan ni Tattoo ara mi, ko di ọba jijẹ lọwọ:

Kabiyesi tun sọ fawọn akọroyin pe, ko si ohun tuntun labẹ ọrun mọ lori laali tawọn oloyinbo n pe ni ''tattoos'' to wa lara oun.

O ni lati ayebaye lawọn Yoruba ti maa n le laali sara fun oge ṣiṣe, ''laye ode oni ni wọn kan n pe ni ''tattoo.''

Lakotan, Kabiyesi Uba ni oun n gbero lati pe awọn gbajugbaja oṣere tiata wa si ilẹ Uba, lati le wa dokoowo ki awọn araalu si jẹ anfaani rẹ.