Nollywood: Àwọn ǹkan pàtàkì tó yẹ kí o mọ̀ nípa Clarion Chukwura

Nollywood: Àwọn ǹkan pàtàkì tó yẹ kí o mọ̀ nípa Clarion Chukwura

Oríṣun àwòrán, Clarion Chukwurah

Àgbà ọ̀jẹ̀ òṣèré tíátà lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn Clarion Folasade Chuwkurah sọ̀rọ̀ nípa bi ó ṣe bẹ̀rẹ̀ eré tíáta ni ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ lásìkò ìfọ̀rọ̀ wánilẹ́nuwó ni BBC, ló ni ìyá òun gan ló fá òun le àwọn eléré tíátà lọ́wọ́.

Chukwuka Abiola ní ọ̀pọ̀ àwọn tó fí ọ̀nà àlùmọ́kọ́rọ́yin wọ eré tíátà ló lọ ma ń ṣe àfíkun sí ara. Ọ́ ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré tíátà sába máa n hùwà àìtọ́ kí wọn ba lé rí àwọn ènìyàn ra ọkọ àti àwọn ǹkan mèremère aye yìí fún wọ́n.

Àkọlé fídíò, Ìgbátí ìgbámú àná látọwọ́ sọ́jà obìnrin ti bá arákùnrin náà dé iléèwòsàn

"Bótilẹ̀ jẹ́ pé ìpèníjà oníruuru ló maa ń wà nínú eré títa síbẹ̀, ẹbùn ló ṣe pàtàkà kí ẹnìyàn ni ẹbún"

"Àgbà òṣèré náà ní lásìkò tí òun fẹ́ ṣe eré ọmọ tó niṣe pẹ̀lú àsà Yoruba, ni ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́gbẹ́ òún díde pé, ọmọ Igbo ni òun nítori naa ipa náà kò ta sí òún, èyí náà tún wáyé lásìkò eré Efunṣetan Aniwura"

Bákan náà ni Clarion sàlàye pé, ó yẹ ki Nollywood fòpin si àwọn eré tó níṣe pèlú lílọ sí ilé bábá aláwo tàbí fífí ọmọlakejì rẹ̀ ṣe òògún owó.

Ó ní èyí máa n nípa lórí àwọn ará ilú gidigidi ni Nàìjíríà

Bákan áà ló tún sàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹ̀lẹ̀ lásìkò kan ti ẹnikan kú sí ilé iṣẹ́ Clarence Peters tó jẹ́ ọmọ Clarion Chukwura tó bi fún Shina Peters.

Ó fí kun pé iná NEPA ló sokùnfa ikú ọmọbinrin náà àti pé Clarence Peters tó ni ilé iṣk kò mọ ǹkankan nípa ikú ọmọbinrin náà

Nkan márùn tí nípa Clarion Chukwura

  • Ọmọ ọdún ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni Clarion Chukwura
  • Ọmọ Ilesha ati Abeokuta ni láti ìdílé ìyá, sùgbọ́n Delta ati Onisha ni Baba rẹ̀
  • Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni làsìkò tó bẹ̀rẹ̀ eré tíátà
  • Ọdun mẹrin ni ó fi wà l'Amẹrika sùgbọ́n ó ti pada si Nàìjíríà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, sùgbọ́n gbogbo àwọn eré àgbéléwò tuntun ti tó ti kópa yóò jáde.
  • Ó bá Shina Peters dọ́rẹ wan si bímọ kan fun ara wọn ti wan pe orukọ rẹ̀ ni Clearence Abiodun Peters
  • Yàtọ sí eré Sinima, Clarion ń ṣe eto iṣẹ́ ẹyinju àámú ni Nàìjíríà, Cameoon àti Tanzania bákan náà ni wọ́n n ta asọ
  • Saliu Babatunde Abiola (Baba Agba) ní ọkọ rẹ̀ tó jẹ́ Aburo MKO Abiola kìí ṣe Abiola gan ló fẹ́
  • Ajíhìnrere ni Clarion Chukwura, èyí ló sì mú kí ó ma ṣètò ìrànwọ́ fún obínrin ti wọ́n bá ń tọ́mọ́.
  • Wọn ti gba ami ẹyẹ láti ọ̀dọ ajọ ìṣọkan agbayé
  • Ọkùnrin mẹ́ta ni wọ́n ti fẹ́ rí