Yoruba film: Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni gbajugbaja òṣèré, Nkechi Blessing ṣẹ Toyin Abraham tó fi ní kó jèbùrẹ́?

Oríṣun àwòrán, Iyabo Ojo/Nkechi/Toyin/Omotola
Oriṣiriṣi awọn nnkan lo ṣẹlẹ laarin ọsẹ yii lagbo oṣere tiata Yoruba.
Bi awọn kan ṣe n fi ẹmi imoore han si ololufẹ wọn, lawọn miran n fi ẹdun wọn han fun ijọba, ti awọn miran pẹlu si ṣe ẹyẹ ikẹyin fun arugbo wọn to papoda.
Wo diẹ lara bo ṣe lọ laarin ọsẹ yii lagbo oṣere tiata Yoruba.
Omotola Jalade
Gbajugbaja osere Nollywood, Ọmọtola Jalade-Ekeinde ti dupẹ lọwọ ọkọ rẹ fun atilẹyin rẹ ni igba gbogbo.
Jalade lo fi eyi si oju opo ikansiraẹni Instagram rẹ laarin ọsẹ yii.
Omotola sọ pe oun ya aworan kan lasiko kan ti oun ko si fẹran bi ikun oun ṣe yọ sita ninu aworan naa, ṣugbọn ọkọ oun ni bo tilẹ jẹ pe ikun oun yọ tandi sita, oun ṣi rẹwa sibẹ.
Ninu ọrọ to kọ soju opo Instagram rẹ, o ni "ọrọ idupe ni mo fẹ fi eyii ṣe! Ọpẹ patakai lọwọ ọkọ mi to maa n ti mi lẹyin ni gbogbo igba."
Lẹyin naa lo sọ pe oun ni ifẹ arakunrin naa gidigidi.
Iyabo Ojo
Ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2020 yii ni Iyabo Ojo padanu iya rẹ, o si sin oku iya naa lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọnanla kan naa.

Oríṣun àwòrán, Kizit Photography
Pupọ ninu awọn akẹgbẹ rẹ ninu iṣe tiata Yoruba lo peju-pesẹ sibi ti ayẹyẹ isinkun naa ti waye, lai yọ awọn ibatan rẹ silẹ pẹlu.
Ninu fidio to fi lede loju opo Instagram rẹ lo ti ṣafihan bi awọn ẹbi, ọrẹ, atawọn gbajumọ lawujọ ṣe tii lẹyin lati ṣe ayẹyẹ ikẹyin fun iya naa to di oloogbe.
Lara awọn to peju sibi ayẹyẹ isninku naa ni Dayo Amusa, Toyin Abraham atawọn gbajugbaja oṣere tiata Yoruba miran.
Toyin Abraham ati Nkechi Blessing
Ọjọ kẹta, ọsu Kejila yii ni Nkechi Blessing fi ọrọ kan lede loju opo Instagram rẹ, nibi to ti n tọrọ aforoji lọwọ Toyin Abraham.
- Àwòrán àwọn afurasí tí a fi léde kìí ṣe òfegè, ṣùgbọn a dọ́gbọ́n síi - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Ọ̀dọ́bìnrin, ẹ ṣọ́ra! Ìbàlòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin kìí ṣe ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ kọ́ ni ìbálòpọ̀ - Genevieve Nnaji
- Wo ọ̀rọ̀ tí Asiwaju Bola Tinubu fi síta lórí ìṣòro ètò àbò Nàìjíríà
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
Ninu ọrọ ọhun ni Nkechi ti sọ pe "ọrọ ti mo fẹ kọ gun pupọ ṣugbọn mo kan fẹ sare sọ fun yin loju koju pe mummy mi ẹdakun ẹ jeburẹ."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Pupọ ninu awọn ololufẹ awọn oṣere memeji lo ti n fi erongba wọn lede lori ọrọ naa.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun ti Nkechi ṣe dara pupọ, lawọn mii n bere pe ki gan ni ẹṣẹ ti Nkechi ṣe Toyin to fi n sọ pe ki Toyin jeburẹ.
Dejo Tunfulu
Dejo Tunfulu ti ke si ijọba apapọ lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn oṣere tiata ni Naijiria ki nnkan le ṣenu ire fun wọn.

Oríṣun àwòrán, @creamsnigeria
Dejo lo sọ bẹ lasiko to ba BBC Yoruba lalejo ninu ifọwerọ kan to waye laarin ọsẹ yii.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O ni lara awọnm iranlọwọ ti ijọba le ṣe fun ẹka tiata ni ko ba wọn gbogun ti awọn to maa n ṣe ayederu fọran sita.
Bakan naa lo tun ke si awọn ololufẹ rẹ lati maa wo awọn fiimu to ba gbe jade, paapaa lojo opo YouTube rẹ ki awọn owo diẹdiẹ le maa wọle fun un.
- Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Pfizer kéde ló fa ọ̀wọ́ngógó epo ní Naijiria - Ìjọba àpapọ̀
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara
- Ṣe lóòtọ́ ní ọmọ Nàíjíríà mílíọ́nù 25 yóò má ló ìná Solar látí Dec 1, 2020?
- Ọkùnrin kan, Kabiru dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó jí súùtì àti àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọkùnrin nílé ìtàjà ní Abuja
- Nigeria police brutality probe: Ohun tí akọròyìn BBC rí rèé lásìkò ikọlù níbi ìwọ́de Lekki













