Nigeria Police: Àwòrán àwọn afurasí tí a fi léde kìí ṣe ayédèrú, a kàn dọọ́gbọ́n síi ni

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG
Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti sọ pe fọto awọn ọdaran to wa loju opo Twitter rẹ kii ṣe ayederu.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n sọ lori ayelujara pe ileeṣẹ ọlọpaa dọgbọn sí aworan awọn ọdaran kan to wa loju opo rẹ lọjọ kinni, oṣu kejila, ọdun 2020 yii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye loju opo Twitter rẹ pe, obinrin kan, Talatu Ibrahim ẹni ogoji ọdun lati ipinlẹ Zamfara ni wọn gba ibọn AK49 mẹsan an lọwọ rẹ, ati afurasi ọkunrin kan, Duleji Alhaji Abubakar to n ra ibọn lọwọ obinrin naa lo wa ninu aworan ọhun.
- Àwọn afurasí ṣá ìgbákejì kọmísọ́nà ọ̀gá ọlọ́pàá láàké dójú ikú
- Ọ̀dọ́bìnrin, ẹ ṣọ́ra! Ìbàlòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́kùnrin kìí ṣe ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ kọ́ ni ìbálòpọ̀ - Genevieve Nnaji
- Àwọn Ọba alayé ní Naijiria ṣàbẹ̀wò sí Ọba Eko, Gómìnà Eko àti Bola Tinubu lẹyin ìwọ́de EndSARS
- Ṣé ẹ rántí àkọ́lé àwọn ìwé àkàgbádùn yìí?
"Abubakar n lo awọn ibọn to ba ra lọwọ Talatu lati jale ati lati ji awọn eeyan gbe fun owo, ko si irọ kankan nibi ọrọ naa," ileeṣẹ lo sọ bẹẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣai fikun ọrọ rẹ pe ọtọọtọ loun ya fọto awọn mejeeji ki oun to lẹ wọn pọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bakanna nile iṣẹ ọlọpaa tun sọ pe aworan awọn ẹlẹwọn ti wọn sa kuro lọgba ẹwọn Oko niluu Benin lasiko iwọde EndSARS kii ṣe ayederu fọto.
- Wo ọ̀rọ̀ tí Asiwaju Bola Tinubu fi síta lórí ìṣòro ètò àbò Nàìjíríà
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Àyà mi já nígbà tí Ganduje rọ Sanusi lóyè Emir Kano tó fi Bayero síi, ṣùgbọ́n...- Ooni Ile Ife
- Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ nípà olùdíje mèjì tó lágbára nínú ìdìbò Ghana rèé
O ṣalaye pe ọkan lara wọn ti orukọ rẹ n jẹ Alhaji Musa Hudu ti inagijẹ rẹ n jẹ Mai Cellular ko sí lára àwon yoku nigba ti wọn ya fọto papọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni eyi lo jẹ ki ohun lẹ fọto rẹ pọ mọ ti awọn ẹlẹwọn yoku ki iroyin naa le ye awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba n ka a.
Ileeṣẹ ọlọpaa wa rọ awọn eeyan pe ki wọn kọ eti ikun si awọn to n sọ pe fọto ayederu lohun fi sí oju opo ayelujara ohun.













