Omotara: Mo kábamọ ìwà tí mo hù sí ọmọ alágbe tó ń tọrọ lọwọ mi nínú ọkọ

Gbajugbaja ori ayelujara nni ti iroyin tan ka pe o huwa aidaa nipa fifi ọti ẹlẹrindodo la ọmọ alagbe kan loju, Omotara ti ba BBC sọrọ pe oun ko ro o bi awọn eeyan ṣe ri ohun to ṣẹlẹ.
O ni boun ṣe kọkọ ri fidio naa tawọn si bẹrẹ si ni pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ loun ti mọ pe oun ti rugi oyin lọwọ awọn ọmọ Naijiria.
"Ohun to ṣẹlẹ gan ni pe mo wa ninu sunkẹrẹfakẹrẹ ọkọ loju popo pẹlu ọrẹ mi, ere lasan ni mo kan n fi ṣe tori mo maa n ṣere gan".
Motara ni ni ti awọn to n sọ pe oun n rẹrin, kii ṣe ọmọ naa loun n fi rẹrin bi ko ṣe iya kan to n taja to n wo oun "pe ki lo n ṣe anti yii".
O ni kete ti awọn ọkọ bẹrẹ si ni sun siwaju pada naa loun tẹsiwaju.
"Maa fun ẹ, mi o ni fun ẹ ni ere ti mo n ba ọmọ naa ṣe ti mo si n sọ fun awọn ọrẹ mi pe ki wan fun mi lowo ninu baagi mi".
Motara ni oun pada fun ọmọ naa lowo ṣugbọn iyẹn o si ninu fidio tori oun ko ni i lọkan lati fi ṣe aburu.
"Afi gbaa ti mo ri i lori Twitter". Oju opo "Whatssap Status" lasan ni Omotara ni oun fi si to si ni to ba wu oun, oun gan le fi si orii Twitter amọ kii ṣe pe oun fẹ fi ṣe nkan ibi kankan.
O ni iṣẹlẹ yii ti ba igboya ninu ara ẹni ti oun ni jẹ tori oun ko le sun, oun ko le jẹun pẹlu bi oun ṣe ni aisan ọgbẹ inu to nitori oun n woye bi ọmọ gan yoo ṣe ro o lọkan ara rẹ pe "lootọ anti yii fun mi lowo ṣugbọn ṣe owo wa ni gbogbo nkan ni".
Motara ṣalaye fun BBC pe lojojumọ, lọsọọsẹ ti oun n ro pe ọrọ naa yoo rọlẹ ṣugbọn kaka kewe agbọn dẹ, pipele lo n pele sii ti mo n gbọ kaakiri pe awọn kan nibi lọhun tun ti n sọrọ nipa rẹ.
"Ojojumọ ni mo n pada lọ si ibi ti mo ti ri ọmọ yẹn boya maa ri i. Bi mo ba ri i nibi nisinsinyii, maa kunlẹ maa bẹ ẹ".
O ni gbogbo ọjọ aye oun lohun yoo fi tun ohun toun ti bajẹ ṣe ti oun si fẹ ko mọ pe oun ko ni aburu lọkan rara ninu nkan ti oun ṣe.
"Ẹnikẹni to ba ba mi ri i ko ba mi sọ fun un pe mo tọrọ aforiji".
Ẹkọ ti Omotara ti kọ bayii
Motara ni laye oun, oun ti kọ ẹkọ pe kii ṣe gbogbo nkan ni yẹyẹ teeyan gbudọ maa fi rẹrin.
Bakan naa kii ṣe gbogbo ọrọ to kan aye rẹ lo yẹ koo maa pin kaakiri lori ayelujara.
Lafikun o ni ko dara keeyan maa foju kere ẹnikẹni laye koda ko ṣe ẹni to n nu bata ẹsẹ rẹ tori ko sẹni to mọ ọla.
















