National Grid: Ìgbà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìtàkùn ìpínná ní Nàìjíríà ti dákú lọ́dún 2020

E ipinnaba kan

Oríṣun àwòrán, Twitter/tcn

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọrọ idakureku itakun ina ọba pinpin lorilẹede Naijiria ti n kọ ọpọ awọn ọmọ Naijiria atawọn alẹnulọrọ lẹka naa lominu.

Laarin ọdun 2013 si asiko yii o ti le ni ọgọrun igba ti itakun ina pinpin lorilẹede Naijiria daku patapata.

Ni ọdun to kọja, iyẹn 2019 nikan, igba mọkanla ọtọọtọ ni itakun ina pinpin lorilẹede Naijiria daku ti gbogbo orilẹede Naijiria si wa laisi ina ọba.

Oṣu kẹrin, ọdun 2020

Ni osun kẹrin ọdun 2020, itakun ina pinpin lorilẹede Naijiria daku patapata lẹyin tawọn eeyan to lẹnulọrọ lẹka naa ni awọn ohun elo fun ina pinpin lẹka naa nilo ayipada lati lee ba igba mu.

Osun karun ọdun 2020

Ni oṣu karun ọdun 2020, itakun ina pinpin lorilẹede Naijiria daku patapata ki wọn to ri i gbe dide si ẹgbẹrun mẹta o din ọgọrun (2900 megawatts).

Ni igba naa, ileeṣẹ to n pin ina ọba lorilẹede Naijiria, TCN ṣalaye pe nnkan bii ẹgbẹrun kan o le ọtalelẹgbẹta o din meji mẹgawaati (1658 megawatts) ni wọn padanu ninu agbami akojọpọ ina mọnamọna to wa fun lilo ni Naijiria nigba naa.

Awọn onwoye ṣalaye nigba naa pe wahala ati ifẹhonuhan awọn oṣiṣẹ ẹka naa lo fa didaku ti ina manamana naa daku.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ keji oṣu kẹfa ọdun 2020, 02/06/2020

Ni ọjọ keji oṣu kẹfa ọdun 2020, itakun ina pinpin lorilẹede Naijiria lati ilu Oṣogbo tun daku patapata to si sọ orilẹede Naijiria sinu okunkun.

Ọjọ kọkandinlọgbọn Oṣu kọkanla, ọdun 2020

Lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ni awọn ileeṣẹ to n pin ina ọba lorilẹede Naijiria ti fi ọrọ ilanilọyẹ sita lati fi to awọn araalu leti.

Ileeṣẹ to n ri si pinpin ina ọba jakejado Naijiria, TCN rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria fun itakun ina to ja kaakiri orilẹede Naijiria lọjọ Aiku eyi to sọ gbogbo ọmọ Naijiria sinu okunkun birimu.

Titi di akoko ti a fi n ko iroyin yii jọ, awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria ko tii ri ina gba pada.

Ẹ̀yin Oníbàárà wa ọ̀wọ́n, ẹ má mikàn, a ti ń dá gbogbo iná yín padà - TCN

ina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, ọpọ ero gba pe ko tọ si awọn EKEDC lati sọrọ lori ina bayii

Okunkun birimu birimu ṣu bolẹ kaakiri awọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria eyi si ti mu ki awọn Naijiria figbe bọ ẹnu pe irọ ni awọn ileeṣẹ apina ọba n pa.

Ileeṣẹ to n ri si pinpin ina ọba jakejado Naijiria, TCN ti rawọ ẹbẹ sawọn ọmọ Naijiria fun itakun ina to ja kaakiri orilẹede Naijiria lọjọ Aiku eyi to sọ gbogbo ọmọ Naijiria sinu okunkun birimu.

Lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kọkanla ni awọn ileeṣẹ to n pin ina ọba lorilẹede Naijiria ti fi ọrọ ilanilọyẹ sita lati fi to awọn araalu leti.

"Ni nnkan bii agogo mọkanla kọja iṣẹju marundinlọgbọn ni itakun ina orilẹede Naijiria daku lọ gbọrangandan ti gbogbo orilẹede Naijiria si bọ sinu hilahilo ko sina". Ileeṣẹ TCN lo fi atẹjade naa sita.

Ẹka ti Ikeja ni ipinlẹ eko jẹ ko di mimọ fawọn araalu loju opo Twitter pe ina ti ko si waye latari irinṣẹ awọn to dẹnukọlẹ.

"Amọ inu wa dun lati fi too yin leti pe ina ti de pada ni agbegbe Maryland ati Ilupeju ti yoo si de pada diẹdiẹ sawọn apa ibi to ku.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Ina Oba

Oríṣun àwòrán, TCNNigeria

Amọṣa, ninu atẹjade kan to fi sita, alukoro ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Ndidi Mbah ni awọn ti sa ipa lati da ina pada sawọn agbegbe kan lorilẹede Naijiria, ṣugbọn ẹkọ ko tii ṣoju mimu lawọn agbegbe bii Calabar, Ugwuaji, Makurdi, Jos, Gombe, Yola ati Maiduguri.

Loju ẹsẹ naa lawọn eeyan ti han wọn ti wọn si n fesi nipa didarukọ adugbo wọn lọkọọkan pe ọrọ aisina kii ṣe ọrọ oni tabi ana ti wọn si n fesi pe titi di asiko ti Ikeja Electric n fi ọrọ wọn sita, ko tii si ina ladugbo awọn.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Àkọlé fídíò, Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú ló ṣe rọ́nà wọlé sí mi lára
Prepaid Meter

Oríṣun àwòrán, @EKEDP

Igbe tawọn mii fi bọ ẹnu ni wipe laipẹ yii ni wọn ṣẹṣẹ fi kun iye owo ina ti awọn eeyan yoo ma san pẹlu ireti pe eleyii yoo mu ọrọ ṣegeṣege kuro ninu ina ọba paapaa pẹlu bo ṣe jẹ pe iye too ba fi kaadi "prepaid" rẹ ra naa ni waa ba nibẹ amọ wọn ni ọgbọn ki ijọba apapọ le ri owo ya lọwọ Banki agbaye eyi to pọn dandan ni wọn ṣe ṣe eyi.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3