Boko Haram attack: Gómìnà Zulum sọ̀rọ̀ lórí ohun tí Ààrẹ Buhari lè ṣe láti dẹ́kun ìpànìyàn Boko Haram ní Borno

Oríṣun àwòrán, @MBuhari
Aarẹ Muhammadu Buhari ti paṣẹ fun awọn ọmọ ogun lati doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram.
Bakab naa ni Aarẹ tun sọ pe ko si oun to ṣe koko lasiko yii ju aabo lori ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria lọ.
Buhari lo sọ ọrọ naa loju opo Twitter rẹ lalẹ ọjọ Aje, lẹyin ti awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram pa awọn eeyan mẹtalelogoji ni ipinlẹ Bornu.
Aarẹ ni "Ko si ohun kankan to ṣeṣe koko lasiko yii ju abo lori ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria."
"Mo si maa ri daju pe ileeṣẹ ologun atawọn ẹṣọ alabo miran yoo ni gbogbo irinṣẹ to yẹ ki wọn ni lati le gbogun ti iwa iṣẹrubalu."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Buhari tẹsiwaju pe "Bi a ṣe n ṣọfọ awọn ẹmi to sọnu lọwọ, a ti paṣẹ fun awọn ọmọ ogun lati lọ gbena woju awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ṣaaju ni Aarẹ Buhari ti kọkọ bu ẹnu atẹ ikọlu ti ẹgbẹ naa ṣe si awọn agbẹ ninu oko irẹsi kan, ni ilu Koshebe, nipinlẹ Borno, nibi ti wọn ti dumbu eeyan mẹtalogoji bi ẹni dumbu ẹran.
Iṣẹlẹ naa ti mu ki ọpọ ọmọ Naijiria ke si Aarẹ pe ko da gbogbo awọn ọga ologun Naijiria duro lẹnu iṣẹ.
Bakan naa lawọn eeyan kan n sọ pe, ti Aare Buhari ko ba le e wa ojutu si eto abo to mẹhẹ, ko kọwe fi ipo silẹ.
Aráàlú faraya torí èèyàn àádọ́fà tó dèrò ọ̀run ní Borno, Gómìnà Zulum ke gbajare

Oríṣun àwòrán, Borno state government
O kere tan eeyan aadọfa lawọn ikọ aṣekupani Boko Haram ti ran lọ sọrun ọsangaan ninu ikọlu kan to waye ni ipinlẹ Borno.
Ṣaaju la gbọ pe eeyan mẹtalelogoji lo ba iṣẹlẹ naa lọ amọ bayii ti ajọ isọkanb agbaye ti toju bọ ọrọ naa wọn ni eeyan aadọfa lo ba iṣẹlẹ naa lọ.
Ọrọ yi wa ninu atẹjade kan ti oludari eto iranwọ fawọn atipo ajọ naa ,Edward Kallon fi sita lọjọ Aiku.
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọba tó kọ ifá sílẹ̀ gbé Bíbélì àti Kùránì
- Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù
- Ilé ẹjọ́ ní kí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá san N50 mílíọ̀nù fún ẹbí 'Sleek' ní Port Harcourt
- Ìyàwó adarí òṣìṣẹ́ nípìnlẹ̀ Ondo tí wọ́n jígbé gba òmìnira lọ́wọ́ ajínigbé
Yatọ si awọn to ku yi, ọpọ lo farapa ninu ikọlu naa.
Loju opo ayelujara, niṣe lawọn eeyan n gbarata ti ọpọ si n di ẹbi ru ijọba aarẹ Buhari fun pe ko mojuto eto aabo bo ti ṣe yẹ.
Ninu ọr awọn eeyan , wọn ni ijọba ni la ti wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ awọn agbesunmmi yi to jẹ pe ojujumọ lo n peleke si.

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter
Gómìnà Zulum bẹ Zabarmari, ìletò tí Boko Haram ti pa àgbẹ̀ 43 wò, Ó ní òkú tí wọ́n pa ṣì ju bẹ́ẹ̀ lọ̀
Wọn ti sin awọn agbẹ onirẹsi mẹtalelogoji tawọn agbebọn Boko Haram kọlu lọjọ Ẹti ti wọn si du loko ti wọn ti n ṣiṣẹ ọgbin wọn.
Gomina ipinlẹ Borno, Ọjọgbọn Babangana Umara Zulum lo lewaju awọn olugbe ilu Zabarmari lowurọ ọjọ Aiku ti isinku naa waye lati sinku awọn agbẹ onirẹsi naa.

Oríṣun àwòrán, Borno Government House
- Omo Ghetto: Funke Akindele ṣàlàyé bí àwọn agbébọn ṣe kọlù wọn làsíkò tí wọ́n ń ya fíìmù
- Àwọn afurasí gbin ǹkan olóró abúgbàmù sí ṣọ́ọ̀ṣì bàbá Wike, ọwọ́ pálábá wọ́n ségi!
- Àwọn agbébọn tún pa Alùfáà ìjọ Baptist kan ní Ekiti
- Kí ló ṣekú pa Bolu, akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó fò ṣánlẹ̀ kù nílé ẹ̀kọ́ ni Ikorodu?

Oríṣun àwòrán, Borno State Government
Gomina Zulum ni ọrọ ti di adiyẹ ba lokun fawọn eeyan agbegbe naa nitori bi wọn joko sile ebi yoo pa wọn, bi wọn tun lọ siṣẹ loko bayii, awọn agbebọn Boko Haram lo tun n lọ ree pa wọn si oko iwa nkan jẹ.
O ni lootọ olugbe ilu Zabarmari ni ijọba ibilẹ Jere lawọn eeyan ti wsn pa naa, amọṣa ileto Koshebe ni ijọba ibilẹ Mafa ni wọn ti da ẹmi wọn legbodo.
Gomina Zulum ni lootọ oku eeyan mẹtalelogoji ni wọn sin lowurọ ọjọ Aiku, sibẹ ko tii si ẹni lee sọ ni pato iye awọn eeyan ti wọn pa.
O fi kun un pe ọkan lara awọn olugbe ilu naa ti ko fẹ da orukọ ara rẹ ṣalaye fun oun lasiko isinku naa pe awọn oku miran ṣi wa ni ibudo ikọlu naa ti awọn eeyan agbegbe naa ko tii loore ọfẹ lati gbe pada wale nitori awọn eeyan ṣi wa ti wọn ṣi n wa bayii nibẹ.
Ààrẹ Buhari: Ìwa wèrè ni àwọn Boko Haram tó dúmbú àgbẹ̀ 40 hù

Oríṣun àwòrán, AFP
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti bu ẹnu at lu bi awọn agbevọn kan ṣe pa agbẹ ogoji.
Aarẹ ṣapejuwe ohun ti wọn wọn ṣe yii ninu atẹjade ti agbẹnusọ aarẹ, Garba Shehu fi sita loju opo Twitter bii iwa ẹni to sinwin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
"Mo bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbesunmọmi ṣe pa awọn agbẹ wa to n ṣiṣẹ karakara lori oko irẹsi wọn ni ipinlẹ Borno.
Iṣẹlẹ dun gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lapapọ bẹẹ si ni ọkan mi wa lọdọ idile awọn agbẹ yii lasiko ti wọn kẹdun awọn eeyan wọn".
Aarẹ gbadura ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.
Iroyin naa to tẹwa lọwọ lalẹ ọjọ Abamẹta sọ pe awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram lo ṣeku pa awọn agbẹ ogoji to n ṣiṣẹ ni oko wọn lọjọ Abamẹta kan naa.
Lowurọ ọjọ Abamẹta ni iṣẹlẹ to fọwọ kan ni lẹmi yi waye ni agbegbe Kwashebe Zamarmari ijọba ibilẹ Jere gẹgẹ bi awọn aradugbo ṣe sọ fun BBC.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, agbegbe naa jẹ ibi kan ti awọn ikọ agbesunmọmi Boko Haram ati ikọ Islamic State West Africa Group kii ṣe alejo pẹlu ikọlu wọn.
Amọ ko tii si ẹgbẹ kankan bii alara to jade wa sọ pe awọn lawọn ṣe ikọlu naa.
Wọn ni lasiko tawọn agbẹ naa n ge irẹsi loko ni ikọlu yi waye.
Eeyan mẹfa mi lagbọ pe wọn farapa ninu ikọlu yi.
Iroyin kan sọ pe wọn so awọn agbẹ naa mọ igi ti wọn si fi ọbẹ ge wọn lọrun.
Titi di bi a ti ṣe n sọrọ yi, ileeṣẹ ologun Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa ko ti fesi si iṣẹlẹ yi.
Boko Haram ati ISWAP si n da bira lariwa orileede Naijiria toun ti pe awọn alaṣẹ ni awọn ti kapa wọn.
Loṣu to ṣẹṣẹ kọja yii ni ikọ Boko Haram pa agbẹ mejilelogun to n ṣiṣẹ loko wọn ninu iṣẹlẹ meji ọtọọtọ.
















