EndSARS, Daniel Chibuike Ikeaguchi: ọlọ́pàá yìbọn pa Sleek ní Port Harcourt niléẹjọ́ bá bú N50 mílíọ̀nù, owó gbà má bínú

SLEEK

Oríṣun àwòrán, SLEEK DC/FACEBOOK

Aadọta miliọnu naira ni Adajọ ni ki ileeṣẹ ọlọpaa o san fun ẹbi Sleek.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Rivers kan to fikalẹ silu PortHarcourt ti paṣẹ pe ki ileeṣẹ ọlọpaa, ọga ọlọpaa Naijiria, kọmiṣọnna ọlọpaa atawọn ọlọpaa meji miran o san owo gba maa binu naa.

Awọn ikọ yii ni yoo san aadọta miliọnu naira fun ẹbi oloogbe Daniel Chibuike Ikeaguchi ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Sleek'.

Ni ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan an, ọdun 2020 lawọn ọlọpaa ikọ agbogun tiwa ijinigbe, Anti-Kidnapping Unit, ileeṣẹ ọlọpaa pa Sleek.

Ni ilu Port Harcourt ni ipinlẹ rivers to jẹ ẹkun guusuguusu Naijiria ni eleyii to mu ki wọn pe illeeṣẹ ọlọpaa lẹjọ itapa si ẹtọ ọmọniyan.

Ni ijoko ile ẹjọ naa meji lawọn ọlọpaa ko ti yọju ti wọn ko si tun ranṣẹ ki wọn to farahan ni ijoko ile ẹjọ naa to kẹyin lọjọ kẹtalelogun, oṣu kọkanla, ọdun 2020 lati wa pẹjọ tako ẹsun ti olupẹjọ naa n fi kan wọn.

SLEEK

Oríṣun àwòrán, SLEEK DC/FACEBOOK

Onidajọ S.C. Amadi ninu idajọ rẹ ni bi ọlọpaa ṣe ṣeku pa Sleek tako iwe ofin orilẹ-ede Naijiria ati pe bi wọn ko tun ṣe fi ọlọpaa to yin in nibọn pa naa jẹjọ ko bofin mu rara.

Amọṣa dipo biliọnu kan naira tawọn ẹbi Ikeaguchi n bere fun fun, aadọta miliọnu naira ni Adajọ Amadi naa paṣẹ ki wọn san fun ẹbi ologbe naa lẹyẹ o ṣọka.

aworan isin idagbere fun oloogbe Sleek

Oríṣun àwòrán, SLEEK DC/FACEBOOK

Agbẹjọro fun ẹbi ologbe naa, Noble Njoku ṣe apejuwe idajọ naa gẹgẹ bi eyi to dara pupọ ti yoo si jẹ ifaleti fawọn ọlọpaa ti wọn n fi eeyan kọ ibọn yinyin.

Awọn obi Sleek, Dominic Ikeaguchi Oyekwu pẹlu ṣalaye pe idajọ naa yoo wo ọgbẹ wọn san de aaye kan bi o tilẹ jẹ pe ọmọ awọn ko le e pada saye mọ.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi