LUTH bed space: "Ìta gbangba ni àwọn aláìsàn kan ń sùn ní LUTH"

LUTH
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wo bí ilé ìwòsàn LUTH ṣe ń gba owó ibùsùn lọ́wọ́ àwọn aláìsàn, tí àwọn míràn sì ń sun ìta

Awọn eeyan kan ti fẹsun kan ile iwosan ijọba apapọ to wa ni ilu Eko, LUTH, pe o n gba owo lọwọ awọn ẹbi alaisan ko to fun wọn ni aaye lati sun nile iwosan naa tabi ki wọn sun ni ita gbangba.

Ẹsun yii lo n waye lẹyin ti fidio kan jade lori ayelujara, eyii to n ṣafihan bi awọn ẹbi awọn alaisan to wa nile iwosan ọhun ṣe n sun ita gbangba.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Nibẹ naa ni awọn obinrin kan ti wọn ṣẹṣẹ bi ọmọ naa n sun ita yii kan naa.

Ṣugbọn awọn alakoso LUTH ti fẹsi pe ko si ootọ ninu fidio naa, ati pe o jẹ iyalẹnu fun awọn pe awọn eeyan le gbe iru fidio bẹẹ jade nipa ile iwosan ọhun.

Adari igbimọ to n ṣakoso ile iwosan naa, Ọjọgbọn Wasiu Adeyemo sọ fun BBC pe, ofin wa nilẹ ni LUTH, eyii ti ko fi aaye gba ẹbi awọn alaisan lati sun pẹlu ẹbi wọn ninu ile iwosan ọhun.

O ni irufẹ alaisan bẹẹ yoo ni lati san afikun owo tabi ki mọlẹbi rẹ sun ni ita gbangba.

LUTH

Oríṣun àwòrán, @others

Kini BBC ri nile iwosan LUTH?

Nigba ti BBC ṣabẹwo sile iwosan ọhun, a foju ganni awọn obinrin to ṣẹṣẹ bi ọmọ tuntun ati ẹbi wọn ti ẉon sun ni ita gbangba.

Diẹ lara awọn eeyan naa ṣalaye fun BBC pe ita ni awọn sun mọju nitori wọn ko ni owo lati san fun ibusun nile iwosan ọhun.

LUTH

Iya kan to ni ọmọ tuntun lọwọ sọ fun akọroyin BBC pe: "wọn ko gba mi laaye lati sun pẹlu ọmọ mi,

idi niyẹn ti mo fi san owo fun wọn ki wọn le faaye gba mi lati sun si yara ti wọn pese pẹlu ọmọ mi.

Àkọlé fídíò, Adebola Ademilua: Àìrísẹ́ ṣè lẹ́yìn ìwé kíkà ló sọ mi dí ìyá onírú, mo dúpẹ́ tèmi

Ẹlomiran ti ko fẹ ki a fi oruko oun lede sọ pe awọn oṣiṣẹ LUTH ko gbogbo ibusun to wa ninu ile iwosan to yẹ ki wọn sun kuro.

O ni wọn si le wọn jade sita, ṣugbọn o ni wọn pe awọn pada lẹyin ti fidio ohun ti oju wọn n ri lu jade lori ayelujara.

Akọroyin BBC to kan si ile iwosan naa ni oun foju gan ni awọn iya ọlọmọ ati ẹbi wọn ti wọn n mura lati sun ni ita gbangba lati nnkan bi aago mẹjọ alẹ.

LUTH

Iwadii BBC fihan pe, ile iwosan naa ni awọn iyara ti awọn alaisan to ba lowo lọwọ le e wọ si pẹlu ẹbi wọn.

Lara awọn iwe ti akọroyin BBC foju kan ṣafihan pe awọn alaisan kan le san iye owo to to #300,000 si #750,000 naira ki awọn ati ẹbi wọn le ri aaye ni iyara ti wọn ya sọtọ, nibi ti wọn yoo ti gba itọju to peye.

Ọjọgbọn Wasiu Adeyemo ni iṣẹ awọn Dokita ati Nọọsi ni lati tọju alsisan, nitori naa oun ko ri idi ti awọn ẹbi alaisan yoo fi maa reti lati sun ti ẹni to n gba itọju.

Bi ẹ ko ba gbagbe, LUTH wa lara awọn ile iwosan to n ṣetọju awọn alarun Covid-19 ni ipinlẹ Eko.

Eeyan 900 ni wọn ṣayẹwo fun, ti wọn si ti tọju awọn 600 to fara kasa Covid-19 lọdun 2020 nikan ṣoṣo.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí