Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́wàá ká nítorí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ọlọ́jọ́ gbọọrọ àti òògùn owó

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ẹjọ ibilẹ Mapo nilu Ibadan, ti tu igbeyawo ọlọdun mẹwa kan, nitori ẹsun ibalopọ alainigbedeke, ati oogun owo.
Iyawo, Basirat Adeyoyin lo gbe ọkọ rẹ, Adeyoyin Niyi lọ sile ẹjọ, to si fi ẹsun kan an pe o fẹ fi oun ṣe oogun owo.
Ninu ọrọ to sọ nile ẹjọ, Basirat ni ara bẹrẹ si ni fun oun , nigba ti ọkọ oun (Niyi) ko ṣe idaro lẹyin ti oun padanu oyun, nitori pe ibalopọ ti awọn n ni ti pọju.
O ni "Ninu ọdun 2018, Niyi dele lọjọ kan, lo ba sọ fun mi pe wọn riran si oun pe oun gbọdọ ni ibalopọ fun ọjọ meje gbako, lai fi pa ọjọ kankan jẹ.
"Emi naa ba gba fun, lai jiyan pẹlu rẹ, ti mi o si ronu pe yoo lẹyin."
- Gbogbo ìgbésẹ̀ Aláàfin láti jí mi gbé ló já sí pàbó, n kò le panumọ́ - Olori Anu
- Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́sàn ká lẹ́yìn tí ọkọ fi ẹ̀sùn olè kan ìyàwó
- Ọkọ'yàwó jẹ àjẹranjú ìyà lẹ́yìn tí ìyàwò rẹ̀ yọjú síbi ìgbéyàwó òun àti obìnrin mìràn
- Iléẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún méjé ká nítorí àìnáání ara ẹni
- Imam tó fẹ́ ọkùnrin míì níyàwó forí kó ìjìyà òfin
- Marlian, òfégè ìgbéyàwó Buhari, Fatoyinbo àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá tó mi ìgboro tìtì ní 2019
Arabinrin Basirat ṣalaye pe oyun oṣu mẹta ti wa ninu oun ṣaaju asiko ibalopọ naa.
Ṣugbọn, oun padanu oyun naa ni ọjọ keji ti awọn bẹrẹ ibalopọ ọlọjọ meje.
"Fun'ra mi ni mo tọju ara mi nileewosan.
"Iyalẹnu si lo jẹ bi Niyi ṣe sọ fun mi pe ki a tẹsiwaju pẹlu ibalopọ naa, lai fi ti ẹjẹ to ṣi n jade lara mi ṣe."
Basirat sọ pe oun fi ọrọ naa lọ awọn obi ati ẹbi oun. Gbogbo apẹẹrẹ lo si fihan pe Niyi fẹ ẹ fi oun ṣe oogun owo ni.
Nitori iṣẹlẹ yii ni Basirat ṣe gbe Niyi lọ sile ẹjọ pe ki wọn o tu igbeyawo wọn ka.
- Ṣé lóòtọ́ ni olorì méjì míì tún ti kúrò láàfin Oyo?
- Ọ̀rẹ́ wa ni Lawrence jẹ́, àmọ́ ó gbẹ̀yìn dẹ́nu ìfẹ́ kọ abúrò wa - Joshua àti Damilola Bamiloye
- Ẹ jọwọ, ẹ ba mi bẹ ìyàwó mi kí ìgbéyàwó mi ma baà túká - 9ice
- Oluwo bu èpè lu àwọn tó dá a lẹ̀bi pé ìgbéyàwó rẹ̀ túká
- Iléẹjọ́ wọ́gilé ìgbeyàwó nílànà ẹ̀sìn Islam pé kò bófin mu
Ṣugbọn nigba to n sọrọ nile ẹjọ, Niyi ni lootọ ni oun beere fun ibalopọ ọlọjọ gbọọrọ.
Amọ ẹsun miran lo fi kan iyawo rẹ pe "iyawo oun buru ju nkan ti agbara oun ka lọ, ati pe kii ka nkan si".
O ni ki ile ẹjọ ko awọn ọmọ mejeeji ti awọn bi fun oun, ti wọn ba tiẹ fẹ tu igbeyawo ka, nitori pe Basirat ko le mojuto wọn.
O ṣalaye pe ọmọkunrin kan ni adugbo ti wọn n gbe ti fi ipa ba ọmọ rẹ akọbi lo ri, ti Basirat ko si sọ fun oun.
O ni isẹlẹ naa waye nitori pe iya wọn ma n pẹ ko to o kuro ni ibi to ti n ta ọja.
Ninu idajọ rẹ, Adajọ ile ẹjọ naa, Onidajọ Odunade Ademola sọ pe ile ẹjọ naa ko ni i ma woran, titi wahala yoo fi ṣẹlẹ ki oun to gbe igbesẹ to yẹ.
Lẹyin naa lo tu igbeyawo naa ka, ki alaafia le jọba.
Bakan naa lo ko awọn ọmọ mejeeji fun Basirat. Amọ o paṣẹ fun Niyi lati ma a fun wọn ni ẹgbẹrun mẹwa, loṣooṣu fun owo ounjẹ.
Yoo si tun ma a san owo ileewe wọn, ati bukaata to ku.



















