Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá mú ọkùnrin ẹni ọdún 55 tó gé ẹ̀yà ara èèyàn nílẹ̀ ìsìnkú ṣọ́ọ̀ṣì l'Ogun

Oríṣun àwòrán, The Punch
Awọn ọlọpaa nipinlẹ Ogun ti mu ọkunrin ẹni ọdun marundinlọgọta kan, Yesiru Salisu, ti wọn ba ẹya ara eeyan lọwọ rẹ ni Ijebu-Igbo.
Iroyin sọ pe wọn ba agbari eeyan mẹrin, ọwọ meji, ati àgbọn mẹta lọwọ ri.
Afurasi naa, ni wọn sọ pe ilẹ isinku Kristiẹni kan to wa ni adugbo Oke-Eri, nilu Ijebu-Igbo, lo ti ge awọn ẹya ara naa lọjọ Aje, pẹlu iranlọwọ ẹnikan, Lekan Bakare, to ti salọ bayii.
- Bàbá akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti pásítọ̀ fi ṣ'oògùn owó ń bèèrè fún ìdájọ́ òdodo
- Ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwadìí lórí ikú olùṣirò owo táwọn agbénipa pa ní Ikorodu
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí ọkùnrin tó gé akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ wẹ́lẹ́ wẹ́lẹ́ fún òògùn owó ní Ikorodu
- Ṣé òtítọ́ ni pé nǹkan oṣù obìnrin le ba òògùn ìbílẹ̀ jẹ́?
Gẹgẹ bi iwe iroyin abẹle, The Punch, ṣe sọ, ọwọ tẹ Salisu, lẹyin ti awọn araalu fi ẹjọ sun ni agọ ọlọpaa to wa ni Ago-Iwoye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi, sọ pe ẹni to lọ fi ẹjọ sun ni oun ri ọkunrin kan to gbe apo dani, ti oun fura si pe ẹru ẹlẹru lo wa ninu rẹ.
Ati pe nigba ti wọn beere ọrọ lọwọ rẹ, o ju apo naa silẹ, o si sa wọ inu igbo lọ.
- Ewé ṣunko! Babaláwo rèé pẹ̀lú afurasí adigunjalè mẹ́rin láhàmọ́ọ́ ọlọ́pàá
- Báwo ni ọkùnrin tí ọlọ́pàá bá òkú rẹ̀ nínú àgbá ní Oyingbo ṣe kú?
- Ọkùnrin kan pa ara rẹ̀ sínú ọgbà àjọ TRACE tó n mójútọ ìrìnnà ọkọ̀ nípìnlẹ̀ Ogun
- Omotara pàdánù isẹ́ olówó ńlá nítorí ó fi ọtí ẹlẹ́rìndòdò sódà lá ọmọ alágbe lójú
Eyi lo mu ki awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọ si ibẹ, ti wọn si ba awọn ẹya ara eeyan to ti gbẹ ninu apo naa.
"Lẹyin naa ni wọn yẹ inu igbo ti afurasi naa sa wọ daadaa, nibi ti ọwọ ti tẹ ẹ.
"O si jẹwọ pe ilẹ isinku to wa ni Oke-Eri nilu Ijebu-Igbo, ni oun ati ẹnikan ti ge awọn ẹya ara naa."
Nibayii, iwadii ti n lọ lori ọrọ naa.
- Ilé aṣòfin orílẹ̀-èdè UK n gbèrò fífí ìyà jẹ àwọn adarí Naijiria tó lọ́wọ́ nínú rògbòdìyàn ENDSARS
- Jemila dáná sún ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin tó bá nílé
- Èyí ni ohun tí Ọọ̀ni sọ nípa Àrẹ̀mọ rẹ àti ètùtù tó ń ṣe lọ́wọ́
- Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọlọ́kadà àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Ibadan
- Adájọ́ ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọmọ Rasheed Maina, Faisal, tó sá mọ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́

















