Maina N2bn Fraud: Agbẹjọ́rò Maina yọ ọwọ́ nínú ìgbẹ́jọ́, Ó lóun kò ṣé mọ̀

Ofin

Oríṣun àwòrán, Google

Ojumọ kan ara kan ni o n ṣẹlẹ lori igbẹjọ Abdulrasheed Maina ti ijọba ni oun ati ọmọ rẹ sa mọ ile ẹjọ lọwọ lori sun lilu owo ijọba ni ponpo.

Lowurọ Ọjọru nileẹjọ giga ti wọn ti n gbẹjọ lAbuja la ti gbọ pe agbẹjọro Maina ti fariga pe oun ko ṣoju Maina mọ.

Adeola Adedipe lo n ṣoju ọkan lara awọn ti wn pe lẹjọ iyẹn ileeṣẹ Maina Common Input Property and Investment Ltd lori ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan Maina.

Agbẹjọro naa ni idi ti oun fi fiwe ranṣẹ ni pe Maina ko san owo fun oun nitorinaa oun ko ni le ṣoju rẹ nile ẹjọ mọ.

Bẹẹ naa lo tọrọ aforijin lọwọ adajọ Okon Abang lori pe oun ko yọju sile ẹjọ lati ọjọ yi ti wọn ti n sun ẹjọ siwaju leralera.

Ninu ọrọ rẹ, adajọ Abang ni Adedipe mọmọ lati ma ṣe yọju sile ẹjọ lọjọ iṣẹgunni.

O ni ko si iwe kankan ti adajọ ri gba lati ọdọ rẹ pe ki wọn yọnda oun ninu ẹjọ naa.

Ni igbẹjọ to waye lọjọ Iṣẹgun, Adajọ ti ṣaaju ni ki wọn mu ọmọ Maina Faisal ti o kọ lati yọju sile ẹjọ.

Bi nkan ti ṣe ri bayi, ko si ẹni to le sọ ibi ti Maina ati ọmọ rẹ salọ lati igba ti igbẹjọ wọn ti bẹrẹ.

Aworan Maina nile ẹjọ

Adájọ́ ti pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọmọ Rasheed Maina, Faisal, tó sá mọ́ ilé ẹjọ́ lọ́wọ́:

Ọrọ ti Senetọ Ndume la kọkọ gbọ nipa alaga igbimọ ti ijọba Naijiria gbe kalẹ lati ṣatunto eto owo ifẹyinti, Abdulrasheed Maina to sa mọ ile ẹjọ lọwọ.

Ni bayi, adajọ ile ẹjọ giga to gbe idajọ kalẹ pe ki wọn fi Senetọ Ndume si gbaga ni Kuje ti ni ki wọn wọgi le beeli ti wọn fun ọmọ Maina, Faisal ki wọn si mu u tori pe o sa mọ ile ẹjọ lọwọ.

Adajọ Okong Abang tun ni ki wọn bẹrẹ igbẹjọ lori ẹsun ikowo ijọba pamọ ti wọn fi kan pẹlu titi ti awọn agbofinro yoo fi mu pada wa sile ẹjọ.

Bakan naa ni adajọ sọ pe ki ẹni to se oniduro rẹ, asofin ile aṣojuṣofin apapọ to n soju Kaura-Namoda, Sani Umar Galadima yọju sile ẹjọ.

Adajọ ni o gbọdọ wa lati ṣalaye idi ti awọn ko fi ni gba owo ọgọta miliọnu Naira to fi ṣ'oniduro fun Faisal.

Aṣẹ ti Adajọ yi gbe kalẹ n waye lẹyin nkan bi ọjọ mẹta ti ile ẹjọ yi kan naa gbe aṣẹ iru rẹ kalẹ ki wọn mu Abdulrasheed Maina ti o sa mọ ile ẹjọ lọwọ.

Aworan Maina

Oríṣun àwòrán, MEDIAMAFIA

Maina to jẹ alaga igbimọ atunto ọrọ owo ifẹyinti ni Naijiria ni wọn fi ẹsun pe o lu biliọnu meji owo ijọba ni ponpo.

Lọjọ Aje yi ni adajọ ni ki wọn fi Sẹnẹtọ Ali Ndume to ṣe oniduro Maina naa si ọgba ẹwọn to wa ni Kuje titi ti yoo fi san owo oniduro aadọta miliọnu Naira.

Àkọlé fídíò, Akọ́mọlédè àti Àṣà lórí BBC Yorùbá: Kọ̀ síi nípa iṣẹ́ tí oúnjẹ ń ṣe lára níbí

Ẹwẹ lọjọ Iṣẹgun yi, igbẹjọ tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan Maina tawọn eeyan mẹta si wa jẹri lori ẹsun ti wọn fi kan an yi.

Agbẹjọro EFCC Mohammed Abubakar sọ lọjọ Iṣẹgun pe ati baba ati ọmọ ni ko ti yọju sile ẹjọ lati ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹfa ọdun 2020.

Faisal oniduro rẹ ati agbẹjọro rẹ ko yọju sile ẹjọ.

Ere ofin Naijiria

Abdulrasheed Maina: Wo àwọn nkan tó yẹ kó mọ̀ kí o tó ṣe onídùró fún ẹnikẹni

Ọjọ Aje ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja, paṣẹ ki wọn o fi Sẹnetọ Ali Ndume , lati ipinlẹ Borno si atimọle.

Eyi ko ṣẹyin bi ẹni to ṣe oniduro fun nile ẹjọ, Abdulrasheed Maina, ṣe salọ.

Maina ni laga igbimọ to wa fun ọrọ owo ifẹhinti ni Naijiria.

Sẹnetọ Ndume gba lati ṣe oniduro Maina, lasiko ti ajọ EFCC, gbe lọ sile ẹjọ fun pe o ṣe mago-mago ọgọrun biliọnu Naira owo ajọ naa.

Ṣugbọn, Maina si ti kuna lati pada yọju sile ẹjọ lẹyin ti wọn gba oniduro rẹ.

Eyi lo mu BBC News Yoruba ba Amofin Sadiku Ibitayọ sọrọ lori awọn nkan to rọ mọ ṣiṣe oniduro fun ẹni to n j'ẹjọ.

Oriṣi oniduro meji lo wa:

Amofin ṣalaye pe oriṣi oniduro meji lo wa. Akọkọ ni eyi ti ileeṣẹ ọlọpa beere fun ati ti ile ẹjọ.

"Oniduro ti ileeṣẹ ọlọpaa maa n waye lasiko ti awọn ọlọpaa ko ti i pari iwadi wọn lati mu ki ẹni naa duro fun afurasi ọdaran.

Wọn yoo kan sọ pe ki ẹni naa buwọlu iwe tabi fi iwe idanimọ rẹ silẹ.

Awọn ọlọpaa yoo pada ranṣẹ pe e ti o ba jẹ dandan."

Ni ti ile ẹjọ, awọn ti ẹsun ti wọn fi kan wọn ba fi aaye silẹ pe wọn le maa gba ile wọn wa jẹjọ ni adajọ maa n gba oniduro fun.

Àkọlé fídíò, Oba Adedokun Abolarin ti Oke Ila: Ó ya ọ̀pọ̀ tó súnmọ́ mi lẹ́nu bí mo ṣe ń kọ́

Kini o gbọdọ mọ ki o to ṣe oniduro ẹnikẹni?

Amofin Sadiku sọ pe ẹnikẹni to ba fẹ ẹ ṣe oniduro fun ẹni to n jẹjọ gbọdọ mọ, ki o si ni oye irufẹ ẹsun ti wọn fi kan ẹni to fẹ ṣe oniduro fun.

O ni ewu ni ti oniduro ko ba mọ ẹsun ti wọn fi kan ẹni to n jẹjọ.

Ti ẹni naa ba sa lọ, ori oniduro ni gbogbo atunbọtan ẹjọ yoo da le lori.

O ṣalaye pe ẹni to fẹ ẹ ṣe oniduro gbọdọ mọ ẹni to n jẹjọ daadaa, titi de ile ati ẹbi rẹ.

O si gbọdọ ni aridaju pe yoo wa sile ẹjọ lọjọkọjọ ti ile ẹjọ ba sọ pe ko wa, ti ko ni salọ.

Yatọ si eyi, amofin ni ẹsun ti wọn ba fi kan ẹni naa ni yoo sọ iru oniduro ti adajọ yoo sọ pe ko mu wa.

Bakan naa, iwọ ni wa a san owo ti ile ẹjọ ba beere fun lasiko to fẹ ẹ gba oniduro ẹni to n jẹjọ, ti ẹni naa ba fi salọ.

Koda, ile ẹjọ yoo gbẹsẹ le dukia ti o ba fi sẹ oniduro fun ẹni to salọ.

Ndume tí d'èrò ẹ̀wọ̀n nítori pé o gba onídur Maina

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ndume tí d'èrò ẹ̀wọ̀n nítori pé ó gba onídùróó Maina tí wọ́n kò rí mọ́

Ilé ẹjọ́ kan nílùú Abuja ti ni kí wan ti Ali Ndume tó jẹ́ sẹnátọ̀ láti Bornu mọ́lé, nítori bi Abdulrasheed Maina to ṣe oníduró fun ṣe pòórá.

Ilé ẹja náà lọ́ja ajé lásìkò ìjòkó rẹ̀ nílé ẹjọ ni ki wọ́n ti Maina mọ́ ọgbà ẹ̀wọ́n níwọ̀n ìgbà ti ko rí mú jáde lásìkò tó yẹ kó wá jẹ́jọ́ ìwà àjẹbánu tó ṣe lásìkò tó wà nípò.

Sáájú ni Ndume ti ṣe oníduró fún Maina ti wan fi ẹ̀sun méjìlá kan, tó fi mọ́ kíkó owó Nàìjíríà pamọ́ ní ìlú òkèrè.

Ọ̀kan lára àlàalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi oníduro ti wọ́n fi àdéhùn sí ni pé, Ndumne yóò máà tẹ̀lé Maina wá si ilé ẹjọ́ ní gbogbo ìgbà ti wọn ba nílò rẹ̀.

Ẹ̀wẹ̀, àìmọye ìgbà ni Sẹnatọ Ndume ko ti ri Maina mu wá si ilé ẹjọ́.

Nínú ìdájọ́ Adájọ́ Okon Abang lo sàlàyé pé, títí di àsìkò tó yóò fi le ṣe àmúṣẹ òníduro rẹ̀, yóò sán mílíọ̀nù 500 si àpò ìjọba

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún fún ìjọba àpapọ̀ láṣẹ láti ta ilé rẹ̀ tó wà ni Asokoro lati rí mílíọ̀nù ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà kójọ.

Adajọ́ náà ni wọ́n yóò tú Ndume sílẹ̀ ni ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje, ní kété tí o bá ti ṣètò gbogbo, tó sì san owó tó yẹ ki ó sàn.