Covid 19 update: Wo ǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ tí o bá fẹ́ lọ fún ìsinmi lẹ́yìn Covid 19

Isinmi

Oríṣun àwòrán, others

Ọpọlọpọ eniyan lo n kundun ati rinrinajo lọ si ilu miran tabi orilẹede miran lati lọ sinmi, lẹyin ọpọlọpọ oṣu ti wọn ti wa nile nitori arun Coronavirus.Bakan naa ni ijọba ti si papakọ ofurufu ni abẹle ati ni ilẹ okeere, eleyii ti o mu u rọrun fun awọn eniyan lati rin irinajo lati ibi kan si omiran.

Amọ, bi o ti ṣe koko to lati rin irinajo lasiko yii, bakan naa ni o ṣe koko lati kiyesi ilera ara wa lasiko arun Coronavirus yii, nitori ko i tii kuro nilẹ.

Ti awọn orilẹede bi Amerika, Ilẹ Gẹẹsi ati Faranse laarin awọn ọpọlọpọ miran si n ri arun naa to n peleke si lagbegbe wọn, bẹẹ si ni ko i tii tan ni orilẹede Naijiria.

Nitori naa ni a ṣe ṣe akọsilẹ awọn nkan mẹwaa ti a nilo lati fi le daabo bo ara wa lasiko arun Covid-19.

Àkọlé fídíò, Ǹjẹ́ oòrùn tàbí oru leè pa àrùn Coronavirus bí?

Wo ohun mẹwaa to yẹ ko mọ to ba fẹ lọ sinmi lasiko arun Covid-19

Ma rin irinajo ti ara rẹ ko ba da:

Orilẹede Amerika lo kọkọ kilọ fun awọn eniyan lati kiyesi ilera ara wọn ti wọn ba n rinrinajo.

Koda, wọn si gba awọn eniyan ti o ba n ṣe aarẹ lati joko sile wọn, nitori ẹni to ba lugbadi arun Coronavirus yoo se akoba fun awọn ti wọn ba jọ rinrinajo, o le jẹ ọmọde tabi agba.

Isinmi

Oríṣun àwòrán, others

Ka iroyin nipa ibi ti on rin irinajo lo:

Aarun Covid-19 ko i tii ni iwosan nitori naa ni ipinlẹ kọọkan ati orilẹede n gbe akọsilẹ jade lori ọna ati dẹkun ajakalẹ arun naa.

O ṣeeṣe ki ilu tabi orilẹede ti o fẹ lọ ti ti ibode wọn, eleyii ti o le da irinajo rẹ ru. Nitorinaa, ka iroyin nipa alakalẹ ibi ti oun lo lori arun Coronavirus.

Ko awọn ohun idabobo mọ ẹru rẹ:

Lasiko to ba n rin irinajo ri daju pe o mu awon eelo idaabobo ara ẹni lọwọ arun Coronavirus, bi ibomu lasiko to ba wa ni gbangba, oogun apakokoro ati ofin ijinasiraẹni ni iwọn mita meji.

Ṣewadii nipa ọkọ ati ile itura ti o fẹ de si:

O ṣe Pataki ki o ṣewadii ibi ti o ma a desi ati iru ọkọ ti o fẹ wọ ni asiko irinajo rẹ.

Bakan naa ni ki o se iwadii nipa awon ohun idabobo ara ẹni ti wọn gbekalẹ lasiko arun Coronavirus yii.

isinmi

Oríṣun àwòrán, others

Ọkọ oju omi ati awọn ibi ti o maa lọ si lasiko irinajo naa.

Ṣọra fun ile ounjẹ ati ibi ase ti ko ba bọwọ fun ofin idadobo ara ẹni:

Iwadii fihan wi pe o ṣe koko ki eniyan jẹun tabi gbafẹ ni awọn agbegbe to bọwọ fun ofin Coronavirus.

Gbogbo awọn ohun eelo ounjẹ ti wọn ba n lo to fi mọ ike ti awọn eniyan nlo.

Ṣe ofintoto awọn ile idaraya ati iṣeraloge

Iwadii fihan pe awọn ile idaraya ati isaraloge gbọdọ wa ni imọtọtọ nipa ti tẹle ofin ijinasiraẹni.

Bẹẹ si ni eniyan kọọkan lo gbọdọ ma a lo awọn ibi yii ni ọgbọn iṣẹju si ara wọn, ki wọn si fi ibẹ fun iṣẹju marundinlogun,ki ẹlomiran to lo.

Sọra lati ma a gbe ọwọ le nkan ni ita gbangba tabi ATM;

Àkọlé fídíò, Eégun àti orò, bí wọ́n ṣe jọ bí Ẹ̀ṣà Egúngún nílẹ̀ Yorùba rèé

O lewu lati ma a gbe ọwọ le ohun gbogbo ti o ba ri ni itagbangba nitori ẹni to ti lugbadi arun Coronavirus ti le lọ ibẹ,

Eleyii ti o le mu ki eniyan ko arun naa, to fi mọ kiosk, ile igbọnsẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O le lo ile ifowopamọsi ti ko ni jẹ ki o gbe ọwọ le ẹrọ naa.

Kiyesara ti o ba n rinrinajo ninu ọkọ baalu

isinmi

Oríṣun àwòrán, others

Awọn ti wọn ba n rin irinajo pẹlu ọkọ baalu gbọdọ kiyesi ara nitori ọpọlọpọ papako ni o ma n kun fọfọ, ti wọn kii si tẹle ofin ijinasiraẹni tabi lilo ibọmu.

Nitori naa lilo awọn ohun idaabobo araẹ̣ni bi iboju ṣ̣e koko, ati titẹle awọn ilakalẹ ti wọn gbe kalẹ.

Ṣọra fun awọn agbegbe ti ero ba pọ siBi o tile jẹpe ọpọlọpọ awọn eniyan lo ma n lo gbafẹ ni eti okun,

O pọn dandan lati yago fun ibi ti ọpọ ero ba wa, eleyii ti o mu ki arun Coronavirus tete ranlẹ si nitori awon to sunmọ ara wọn pẹkipẹki.

Àkọlé fídíò, AbdulQudus Bello ṣàlàyé bí òun ṣe dí aláàbọ̀ ara nítorí pọpọ́ọ̀fù àti ìbínú jàǹdùkù àdúgbò

Gba imọran lọwọ awọn onimọ nipa arinrinajo

Bi o tile jẹ pe ọpọlọpọ awọn arinrinajo lo fẹran lati ma a ṣe ohun gbogbo ti wọn nilo fun ara wọn.

O pọn dandan ki a bere amọran lọwọ awọn onimọ nipa irinajo nitori wọn ni imọ pupọ nipa ibi ti a n lo, ati iru ijamba tabi ewu to wa nibẹ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC:Wo ìrúfẹ́ ìgbeyàwó méje tó wà nílẹ̀ Yorùbá àti ojúṣe Alárinà